Gómìnà Abba Yusuf tìpínlẹ̀ Kano tú ìgbeyàwó ká pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Zainab abúrò Rabiu Kwankwanso, 'àbí ọ̀rọ̀ òṣèlú ni?' ni ìbéèrè táwọ̀n èèyàn ń béèrè

Aworan Gomina Abba Yusuf
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọrọ kan ti gomina ipinlẹ Abba Kabir Yusuf sọ lọjọ Aje ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ nipa igbeyawo rẹ.

Lasiko to fi n ba awọn oṣiṣẹfẹyinti sọrọ nibi ipade kan ni ilu Kano lo ti sọrọ naa bi awada pe igbeyawo oun ati Zainab Musa Kwankwaso, to jẹ aburo baba isalẹ rẹ tẹlẹ, Rabiu Musa Kwankwaso ti fori sọ igi.

Ọrọ yii n jade sita lasiko ti ahesọ ọrọ ti n lu sita lati opin ọsẹ to kọja wi peZainab ti lọ sileẹjọ lati pe fun iwe ikọsilẹ ni ile ẹjọ Upper Area Court ni Gudu nilu Abuja lati rọ̀ ileẹjọ naa pe ko tu igbeyawo oun ati gomina naa ka.

Igbesẹ yii ti mu ọ̀pọlọpọ awuyewuye wa nitori pe ọpọ eeyan to n wo bi ajọṣepọ oṣelu laarin Gomina Abba Yusuf ati baba isalẹ rẹ, Rabiu Kwankwaso ti pari.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, idile Kwankwaso ati Yusuf ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ naa, amọ ọrọ ti Gomina Abba Yusuf sọ lọjọ Aje ṣebi ẹni fi idi rẹ mulẹ pe igbeyawo naa ti foriṣanpọn.

Ki ni Gomina Yusuf sọ gan?

Aworan Gomina Abba Yusuf

Gomina Yusuf ni 'awọn to mọ mọ bo ṣe n lọ' laisi ọpọ̀ alaye rara.

Ninu fidio naa, ni Gomina Abba Yusuf tun ti n sọ pe: "to ba jẹ iwe aṣẹ ijọba lo nilo, a ti fun un ki gbogbo wa le sinmi'. Eyi to mu ki ọpọ onwoye maa wo o pe iwe ikọsilẹ igbeyawo lo n fi ẹna sọ.

Ta ni Zainab Musa Kwankwaso?

Aworan Rabiu Musa Kwankwaso
Àkọlé àwòrán, Kwankwaso ni ẹgbọn Zainab, iyawo ti gomina Abba Yusuf kọ silẹ

Zainab Musa Kwankwaso jẹ gẹgẹbi ọmọ̀ fun Gomina tẹlẹ naa, Sẹnetọ Rabiu Kwankwaso.

Zainab fẹ gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf ni ọdun 2006, igbeyawo wọn si ti so eso ọmọ mẹfa.

Lootọ ko si ẹni to le sọ ni pato, ṣugbọn awọn onwoye kan n sọ pe o niiṣe pẹlu tirela to gba aarin Gomina Abba Yusuf ati Rabiu Kwankwaso to jẹ igbkeji oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu NDC fun ibo aarẹ to n bọ lọna ni Naijiria.