You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Eku ò ké bí eku mọ́ ní Ekiti, 'èmi ló kàn' láti dá nǹkan padà bọ̀ sípò – Oluwadare Abejide, Olùdíje ADC fún ìbò gómìnà
Ninu ifọrọ̀werọ BBC News Yoruba pẹlu Amofin Oluwadare Bejide to jẹ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu ADC, O ṣalaye pe aiṣedede ilana ati igbesẹ iṣejọba ni ipinlẹ Ekiti lo mu ki oun darapọ mọ igbesẹ lati dije fun ipo gomina ipinlẹ naa lati lee mu atunto ba igbayegbadun araalu nibẹ.
O ni o ṣeni laanu pe ni gbogbo ilẹ Yoruba, ipinlẹ Ekiti nikan 'ni ipinlẹ ti ko si ileeṣẹ ẹyọkan ṣoṣo' bayii bi o ti wulẹ o mọ.
"Bo ṣe n lọ yii, eku o ke bi eku mọ l'Ekiti, ẹyẹ o ke bi ẹyẹ, ọmọ eniyan o fọhun bi ọmọ eniyan; ilu le!"
Ibo ti ko to ibo ni wọn n yí – Amofin Bejide
Ninu ọrọ rẹ to sọ siwaju, Amofin Oluwadare Bejide ṣalaye pe lootọ awọn kudiẹkudiẹ maa n waye lati mu akude ba eto idibo sibẹ oun gbagbọ pe ko si ẹni ti yoo le tipasẹ eyi da oun ni agbo nu lasiko idibo sipo gomina to n bọ lọna ni ipinlẹ Ekiti.
O ni ibo ti ko to ibo ni wọn n yi ati wi pe nigba ti araalu ba ti di ibo wọn lọpọ yanturu, ko si bi awọn kọlọrọsin oloṣelu kankan yoo ṣe lanfani lati yii da sigbo.