You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn agbábọ́ọ̀lù méje tí yóò gbé ògo Afrika ga nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ agbáyé ọdún 2026
- Author, Rob Stevens
- Role, BBC Sport Africa
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Orilẹede Afrika mẹwaa ni yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026.
Morocco wọ inu iwe itan lọdun mẹrin sẹyin lẹyin to di ikọ ilẹ Afrika kini ti yoo wọ ipele 'semi-finals' ninu idije ọhun
Cape Verde yoo kopa ninu idije naa fun igba akọkọ nigba ti DR Congo yoo kopa ninu idije ọhun fun igba akọkọ lati ọdun 1974.
BBC mu awọn agbabọọlu lati Afrika meje to ṣeeṣe ki wọn fakọyọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun yii ni Amẹrika, Mexico ati Canada lati ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa titi di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2026 yii.
Antoine Semenyo (Ghana)
Ilu London ni wọn bi Semenyo si, bo tilẹ jẹ pe ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League pẹlu Manchester Citya amọ ipa to ko ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Chelsea ni idije FA Cup ran ikọ naa lọwo.
Ọpọ ọmọ Ghana lo ṣeeṣe ki wọn fi ireti wọn sinu Semenyo latari pe agbabọọlu Ghana mii to n gba bọọlu ni Premier fun Tottenham, Mohammed Kudus, ti ṣeṣe.
Bo tilẹ jẹ pe Ghana ko kopa ninu idije 2025 Africa Cup of Nations (Afcon), o ti gbaradi lati fakọyọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026.
Yan Diomande (Ivory Coast)
Ivory Coast n pada si idije ife ẹyẹ agbaye lọdun yii fun igba akọkọ lati ọdun 2014. Wọn si ni agbabọọlu to ta lẹnu ni German Bundesliga.
Ẹni ọdun mọkandinlogun naa jẹ goolu mejila fun RB Leipzig lati gbe ipo kẹta ni Champions League.
A tilẹ gbọ pe o ṣeeṣe ko tẹkọ leti lọ si Liverpool tabi Chelsea laipẹ.
Ronwen Williams (South Africa)
Lati ọdun 2010, South Africa tun ti pada si idije ife ẹyẹ agbaye lẹẹkan si lẹyin ti wọn ṣagbatẹru idije naa ni 2010.
Lara awọn agbabọọlu wọn to ta lẹnu ni aṣọle wọn Williams wa.
Williams gbajumọ lẹyin to mu ọpọlọpọ goolu ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Cape Verde ni 2023.
South Africa ni yoo kọkọ ṣi idije naa loju pẹlu Mexico ki wọn to tun waa ko pẹlu Czech Republic ati South Korea.
Roberto 'Pico' Lopes
Ọkunrin yii lo n gba apa ẹyin fun Cape Verde ti wọn gbe ipo kẹjọ nini idije Afcon 2023.
Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ti wọn bi ni Dublin gba bọọlu fun orilẹede rẹ fun igba akọkọ lọdun 2019.
Ninu ipin H ti wọn wa ni wọn yoo ti pade Spain ati Urugauy to fi mọ Saudi Arabi, iriri Lopes yoo si ṣe orilẹede rẹ lanfani ninu idije yii.
Brahim Diaz (Morocco)
Agbabọọlu Real Madrid yii fakọyọ fun Morocco ninu idije Afcon 2025 lẹyin to sọ goolu marun un sinu awọn ẹgbẹ alatako wọn.
Ninu ipin C ti wọn wa ni wọn yoo ti koju Brazil ki wọn to tun lọ pade Scotland ati Haiti.
Ismaila Sarr (Senegal)
Igba mọkanlelogun ọtọtọ ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn yii ti gba bọọlu to jọju fun Crystal Palace ni saa bọọlu yii.
Ikọ agbabọọlu Teranga Lions yoo koju France, orilẹede Erling Haaland, Norway ati Iraq ni ipin I.
Ni 2022 ti Senegal kọkọ kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye, Senegal ko paṣan kan si odo fun France.
Ọpọ eeyan lo ti n duro de nnkan ti Sarr yoo ṣe fun Senegal lọtẹ yii.
Omar Marmoush (Egypt)
Ọdun to kọja ni agbabọọlu yii kuro ni Eintracht Frankfurt to si darapọ mọ Man City.
Igba mẹjọ pere lo gba bọolu fun City ni saa bọọlu 2025-2026 amọ o wa lara awọn ti yoo lewaju fun Egypt ninu idije ife ẹyẹ agbaye yii.
Ninu idije Afcon 2025, igba meji ọtọtọ lo sọ bọọlu sinu awọn, yoo si tiraka lati ṣe ju bẹẹ lọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye yii.