Àlàyé rèé lórí bí fọ́nrán ohùn Tinubu tí wọ́n fi AI ṣe, ṣe dá wàhálà sí VDM lọ́rùn, tí wọn ṣí ló gbọdọ̀ fojú winá òfin

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Imọ ẹrọ igbalode AI ti wọn n lo lẹka iṣẹ kaakiri bayii tun ṣee

lo fun ọpọ nnkan miran ju iṣẹ aje lọ.

Bi AI ṣe wulo lati mu iṣẹ ya kankan, bẹẹ naa ni awọn to mọ lilo rẹ nidakeji tun maa n lo o lati ya fidio eeyan tabi lo ohùn ẹnu ẹni ti wọn ba fẹ fi ṣe jamba fun.

Irufẹ lilo bẹẹ lo di ohun ti ileeṣẹ Aarẹ ilẹ Naijiria ṣe n pe fun fifi ọwọ ọfin mu ajafẹtọọ ọmọniyan to gbajumọ pupọ, Martins Vincent Otse, tawọn eeyan mọ si Very Dark Man tabi VDM.

"VDM ni lati foju wina ofin fun bo ṣe pin fọnran ohun Aarẹ Tinubu to jẹ ayederu lori ayelujara."

Ileeṣẹ Aarẹ lo sọrọ bẹẹ lori fidio kan ti wọn fi AI ṣe ti ẹnikan si gbe si ori fidio VDM.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni Oludamọran pataki fun Aarẹ Tinubu lori ikede ati ọgbọn inu; Bayo Onanuga, darukọ oju opo X kan to gbe fidio naa jade.

Niṣe ni fidio naa n sọrọ bii ohun ẹnu Aarẹ Tinubu gẹlẹ, wọn si gbe e mọ fidio VDM.

Ṣaaju ni VDM ti gbe fidio kan jade loju opo Instgram rẹ, nibi to ti jokoo to si kọkọ ṣafihan fidio sọrọsọrọ bii tiẹ, King Mitchy.

Lẹyin fidio King Mitchy to ṣafihan, VDM gbe fidio Aarẹ Tinubu si i, nibi to ti ṣeleri pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ina mọnamọna lo daadaa, ati pe bi wọn ka ba ri ina lo ni saa oun akọkọ, ki wọn ma dibo foun lẹẹkeji mọ.

Ni ibẹrẹ fidio naa, VDM sọ pe:

"Ṣẹ ẹ ri fidio to kan ti mo fẹ fi han yii, nibẹ ni ma a ti mọ boya wọn se ọkan yin ni, ẹyin tẹ ẹ fẹ ṣatilẹyin fun Bola Tinubu."

Lẹyin naa lo si ṣafihan fidio Aarẹ Tinubu.

Fidio kan naa ti VDM fi han, di ohun ti wọn fi AI gbe ohun Tinubu le lori to n tako araalu

Ṣugbọn nipa lilo agbara AI fun idakeji nnkan ire ti imọ ẹrọ naa le ṣe, fidio VDM di ohun ti wọn sọ di ohun ẹnu Aarẹ Tinubu, o si n da bii pe Ajafẹtọọ naa lo gbe e jade.

Ohun ẹnu Tinubu ti wọn fi AI gbe jade naa sọ pe:

"Wọn fẹ ki n kuro nipo yii, iyẹn o ṣee ṣe.

"Ṣe ẹ fẹ gbọ, mo maa bori ibo yii, ko sohun to kan mi nipa ohun to n ṣẹlẹ.

" Ohun to yẹ koju awọn ọmọ Naijiria ri lo n ri yii, nitori nigba ti mo fẹ di aarẹ, wọn o fẹ mi loye, ṣugbọn lojiji bayii, wọn wa fẹ ki n ba wọn ṣẹgun eto aabo to mẹhẹ."

Fọnran naa ko tan sibẹ, o tun sọ pe Tinubu sọ fun Peter Obi pe ko ma dije, ṣugbọn Obi kọ jalẹ.

Fọnran ohun naa wa tẹsiwaju, nibi to ti ni Tinubu sọ pe oun yoo ri I pe ìyà ai si aabo jẹ wọn gidi ni Guusu-Ila Oorun Naijiria ju ti awọn apa ibomi-In lọ.

Fọnran ohun yii lo fa a ti Onanuga to n kede fun Aarẹ fi ni o yẹ ki VDM foju wina ofin pẹlu ayederu fidio Aarẹ Tinubu to pin.

"O yẹ ki VDM yii koju agbara ofin, pẹlu bo ṣe n pin ayederu fidio Aarẹ Tinubu kiri. Aṣilo ayelujara to foju han leyi."

Bẹẹ ni Onanuga wi.

Ẹ ṣewadi ibi ti fidio yẹn ti wa, mi o mọ nnkan kan nipa ẹ - VDM

Ẹni ti a tiran mọ ki I dakẹ, to ba dakẹ yoo jẹbi.

Bi ọrọ yii ṣe n lọ lọwọ ni VDM naa ti fesi pada, o ni kijọba wadii ẹni to gbe fidio AI papọ mọ ti oun.

Very Dark Man ninu atẹjade ti lọya rẹ, Deji Adeyanju atawọn agbejọro ẹgbẹ rẹ fi sita, koro oju si bi Onanuga ṣe n darukọ VDM mọ fidio naa.

Atẹjade naa sọ pe bi ileeṣẹ Aarẹ ba tiẹ wo oju opo VDM lasan, ti won ko si ri fidio naa nibẹ, o yẹ ko ye wọn pe ọdọ rẹ kọ lo ti wa niyẹn.

"O jọ ni loju, pe pẹlu gbogbo ọna to wa lati wadii ọrọ yii lati ileeṣẹ Aarẹ, ọrọ buruku ni wọn wa n sọ si onibaara wa lai wadii ododo bo ṣe yẹ."

Apa kan atẹjade naa lo sọ bẹẹ.

Ikọ agbẹjọro fun VDM naa sọ pe ohun ti ijọba apapọ n ṣe yii tubọ n fidi ẹ mulẹ, pe wọn fẹ pa ohun mọ agogo VDM lẹnu ni, nitori bo ṣe maa n tako ijọba lori aṣiṣe wọn.

Awọn amofin naa wa pe ẹka to yẹ gbogbo, lati wadii iṣẹlẹ yii delẹ, ki wọn si mọ ibi ti ohun ẹnu aarẹ naa ti wa.

"A pe gbogbo ẹka alaabo lati wadii ibi ti fọnran ohun yii ti wa, ki wọn si ri I daju pe wọn mu awọn to wa nidii rẹ, ki wọn fi wọn jofin bo ṣe yẹ."

Atẹjade naa lo pari bẹẹ

Ta a ni VDM?

A bi Martins Vincent Otse tawọn eeyan mọ si Very Dark Man lọjo kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 1994, niluu Kaduna.

Bo tilẹ jẹ pe ilu Agenebode, nipinlẹ Edo lawọn obi rẹ ti wa, ilu Kaduna ni Very Dark Man ti lo igba ewe rẹ.

Very Dark Man jẹ alẹnulọrọ lori itakun ayelura, ajafẹtọọ ọmọniyan ati ẹlẹyinju aanu.

Ọgbẹni Otse jẹ ẹnikan to maa n saba ṣe nkan to maa n jẹ kawọn sọrọ nipa rẹ loorekoore.

O si maa n sọ kudiẹ-kudiẹ ijọba.

Ewu to wa ninu lilo AI

Ni iru asiko yii ti Naijiria n koju isoro aabo, ti wọn n ji eeyan gbe kiri, iru fidio ati fonra ohun ti wọn ṣe fun Aarẹ yii le da rogbodiyan nla silẹ bi amojuto ko ba si.

Eyi ni ohun ti awọn to mọ lilo AI ṣe sọ pe ewu gidi wa fun lilo o lọna aidaa, paapaa, bi ko ṣe si ofin to de lilo rẹ lati ṣe aburu.

Ẹka to n ri si aabo nipa lilo AI (Centre for AI Safety) sọ pe o ni ẹka aburu rẹpẹtẹ ti wọn le lo AI fun.

Wọn ni wọn n lo AI fun irinṣẹ ogun, wọn le lo o lati fi gbe ohun ẹnu eeyan jade, ti yoo sọ ọrọ ti ẹni naa ko sọ funra rẹ amọ gẹlẹ bii pe onitọhun lo n sọrọ ni yoo jọ.

Ni Europe, wọn ti ṣe AI tiwọn pẹlu ofin to de lilo rẹ, ti ko fi ni I koba araalu.

Ni Naijiria, ofin to de Ai ko ti I fi bẹẹ fẹsẹ mulẹ, debi ti yoo da aabo bo eeyan ti wọn ko fi ni I le lo AI ṣe alupaida ohun ẹnu tabi fidio eeyan.