You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Teslim Ajimobi, àbúrò Abiola Ajimobi jáde láyé lọ́jọ́ tó pé ọdún mẹ́fà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kú
Ni Ọjọbọ, ọjọ Kẹfa osu kẹfa ọdun 2026 tii se ana ni o pe ọdun mẹfa ti gomina ana nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi jade laye, ti adura iranti si waye nile rẹ nilu Ibadan.
Amọ o se ni laanu pe bi ni alẹ ana, lẹyin ti wọn se ayẹyẹ iranti oloogbe Abiola Ajimobi tan ni aburo rẹ, Alhaji Teslim Adeboye Ajimobinaa dagbere faye.
Ilu London nilẹ United Kingdom ni oloogbe naa ti jade laye lai ti pe aadọrin ọdun, amọ a ko ti le sọ iru iku to pa oloogbe naa.
O si n ya ọpọ eeyan lẹnu pe Teslim naa ki aye pe o digbose ni ọjọ to pe ọdun mẹfa geerege ti ẹgbọn rẹ ku.
Teslim Adeboye Ajimobi ti jẹ alaga ijọba ibilẹ nigba kan ri nijọba ibilẹ ila oorun guusu ibadan, South East lun 2017
Alhaji Wasiu Ajimobi, ti oun naa jẹ aburo Abiola Ajimobi si ti fi idi isẹlẹ yii mulẹ fun BBC News Yoruba.
O ni alẹ ana Ọjọbọ ni isẹlẹ iku oloogbe naa waye nilu London, aarọ oni si ni wọn yoo kede iku rẹ fun gbogbo ẹbi.
Onisowo pataki ni Teslim Adeboye Ajimobi loke okun, to si tun jẹ gbajumọ oloselu nigba aye rẹ.
Teslim Adeboye Ajimobi ti jẹ alaga ijọba ibilẹ nigba kan ri nijọba ibilẹ ila oorun guusu ibadan, South East lun 2017.