Gómìnà Seyi Makinde kéde pé òun yóò dupò ààrẹ Naijiria ni 2027

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Seyi Abiodun Makinde, ti kede pe oun yoo dupo aarẹ orilẹede Naijiria ninu idibo apapọ ọdun 2027.

Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla oṣu Karun-un ọdun 2026 ni Makinde kede bẹẹ, nibi eto kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ati APM ti jọ sọwọpọ fi awọn oludije dupo oṣelu fun eto idibo ọdun 2027 han niluu Ibadan.

Ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples' Movement (APM) ni Seyi Makinde ni oun yoo ti dupo aarẹ Naijiria ni 2027.

Ẹgbẹ oṣelu mejeeji ti i ṣe PDP ati APM jọ kọwọ bọwe adehun asọye( Memorandum of Understanding) nibi eto naa.

Seyi Bamidele lo buwọ luwe naa lorukọ PDP, nigba ti Oladele Oyadeji buwọ lu u lorukọ ẹgbẹ APM.

Bakan naa ni Gomina Seyi Makinde ati Alaga aapapọ APM, Yusuf Dantalle, jọ kọwọ bọwe adehun naa lorukọ ẹgbẹ mejeeji.

Ẹkunrẹrẹ iroyin yii n bọ laipẹ.

Ṣé lóòótọ́ ni Gómìnà Seyi Makinde máa kéde èròńgbà láti dupò ààrẹ Nàìjíríà lónìí?

Gbogbo eto lo ti to pẹlu bii gomina Ipinlẹ Oyo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fe fi awọn oludije sipo gomina ati Igbakeji rẹ ati awọn ti yoo dije dupo ile aṣoju sofin ati ile igbimo asofin han ninu ẹgbẹ oṣelu APM fun eto idibo ọdun 2027.

‎Eto naa ti wọn sọri rẹ ni "UNITY MEGA RALLY" ni yoo waye ni gbagede Mapo nilu Ibadan ni ọjọbọ ọjọ Kẹrinla oṣu Karun-un ọdun yii..

‎Ṣaaju ni awọn iwe iroyin kan ti n gbe iroyin pe o ṣeeṣe ki gomina Seyi Makinde naa kede erongba rẹ lati dije sipo Aarẹ Orilẹ-ede yii, sugbọn ẹnikan to sunmọ gomina Makinde ti ko fẹ ki a darukọ oun ni ikede naa le ma waye.

O ni o ṣeeṣe ki Makinde kede eerongba rẹ naa titi ipari oṣu Karun-un amọ kii ṣe nibi ayẹyẹ ti yoo waye lonii.

‎Ti o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni awọn aṣofin to n ṣoju ipinlẹ Oyo ni ile igbimo aṣojuṣofin ilu Abuja kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ti wọn si lọ si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM.

‎Ọpọ ninu awọn aṣofin naa to fẹ dije dupo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ lo ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ ti wọn si ti lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APM.

Lara wọn ni,Shina Peller, Olufemi Ajadi, Akeem Olatunji, ti aṣoju ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile igbimo aṣofin ipinlẹ Oyo, Sanjo Ọnaolapo naa wa lara wọn.

Ibaṣepọ wo lo wa laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APM?

‎Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo Michael Ogunsina ni ẹjọ, wahala to de ba ẹgbẹ oṣelu PDP ko tii dópin eyi lo fa a ti ọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ṣe n lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mii bii APM ki wọn ba le raye dije dupo ninu eto idibo ọdun to n bọ.

‎Micheal ṣalaye pe ki awọn to n tẹle gomina Seyi Makinde ma baa ni ijakulẹ lo fa a ti ọpọ wọn fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM.

‎O ni "ẹgbẹ oṣelu wa ni ẹjọ to pọ nile ẹjọ, awọn ẹjọ yẹn ko i tii forisọ ibi to da, a a ti pari ẹjọ yẹn, ṣugbọn ka le fun awọn ara ipinlẹ Oyo ni anfaani lati dibo fun awọn ti wọn fẹ ninu awọn to n tẹle gomina Seyi Makinde lo fa a ti wọn fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM.

‎"Ibiti ẹjọ ile ẹjọ ba wo si ni yoo sọ boya awa naa yoo lọ si inu ẹgbẹ oṣelu APM patapata tabi boya a maa duro sinu ẹgbẹ oṣelu PDP, awọn eeyan Ipinlẹ Oyo maa sọ fun Seyi Makinde pe ibi o ba n lọ la nl ọ, tori rẹ la fi lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APM ki awọn to n tẹle gomina Seyi Makinde le raye du ipo oṣelu."

Ki lo ṣeeṣe ko ṣẹlẹ lẹyin ikede ọjọ Kerinla?

‎Awọn onwoye oṣelu nipinlẹ Oyo ti woye wi pe, igbese ti gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde n gbe yoo ṣe atọna fun awọn oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM.

‎Wọn tun woye wi pe, igbeṣẹ naa yoo fun Gomina Seyi Makinde ni okun ọtun lati bọ ajaga ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.

‎Ọpọ lo gbagbọ pe laipẹ yii awọn olutẹle gomina Makinde ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ ki wọn le dijọ dibo yan awọn ololufẹ gomina Seyi Makinde sipo oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu APM.