You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lateef Adedimeji kéde orúkọ àwọn ìbẹ́ta rẹ àti ọjọ́ tí wẹ̀jẹwẹ̀mu ìdúpẹ́ yóò wáyé
Lẹyin ti Eleduwa fi ibẹta ta wọn lọrẹ lọsẹ to kọja, gbajumọ oṣere tọkọtaya, Lateef Adedimeji ati Mo Bimpe ti ṣe isọmọlorukọ awọn ẹtaoko wọn.
Gẹgẹbi ọrọ ati fidio to fi si oju opo ayelujara rẹ, Lateef Adedimeji ṣalaye pe awọn ti ṣe isọmọlorukọ fun awọ̀n ọmọ awọn ni ọjọ Ẹti.
Bakan naa lo ṣalaye pe, Rahman, Raheem ati Rakeeb lawọn sọ awọn ọmọ naa.
Lateef Adedimeji tun ṣalaye wi pe oṣu keje dun yii lawọn yoo ṣe wẹjẹwẹmu idupẹ gbigbe oyun ati bibi layọ. O ni wẹjẹwẹmu naa ni wọn yoo ṣe "fun gbogbo eeyan lati jẹri si didara Ọlọrun!" Amọṣa ko ṣalaye ọjọ gan ni pato ti yoo jẹ ninu oṣu keje.
- 'Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó,' Lateef Adedimeji sọ̀rọ̀ lórí ọmọkùnrin mẹ́ta tí Elédùà fi ta ẹbí rẹ̀ lọ́rẹ
- Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dele Odule tó fi lọ béèrè iye tí wọ́n ń ta pósí fún ara rẹ̀? Ìdí abájọ rèé
- Ohun tó dùn mi jùlọ láyé lọ̀rọ̀ tí ìyàwó mi sọ pé méjì nínú ọmọ márùn ún tí mo ṣe súná wọn kìí ṣe tèmi - Òṣèré tíátà, Tioruju
Ẹ jọwọ̀ gbogbo aworan to n lọ kaakiri kii ṣe aworan awọn ọmọ wa – Lateef Adedimeji
Bakan naa ni eekan oṣere tiata naa tun ke gbajare sita pe oun rii pe awọn aworan awọn ọmọ to jojungbese kan ti n lọ kaakiri lori ayelujara, amọṣa awọn ọmọ to wa ninu awọn aworan naa kii ṣe awọn ibẹta oun o.
"Ni kete ti a ba ti ṣetan lati fi oju awọn ọmọ wa sita, ẹ gbagbọ pe oju opo ayelujara wa lẹ ti maa kọkọ rii."
O wa rọ awọn eeyan lati maṣe lo ẹda ayederu aworan igbalode AI to n lọ kaakiri lori ayelujara.