You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà máa fi ojú àwọn olóṣèlú dánrin níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀ - Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni oun gbagbọ pe nini agbara gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu to wa ni ipo ijọba apapọ ko ni ni ipa kankan ninu eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Nigba to n sọrọ yii nibi ipade apero lori ẹka inaju to waye ni gbọngan International Conference Centre, ICC ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.
Seyi Makinde ni oun gbagbọ pe awọn ọmọ Naijiria maa dibo fun ẹni to ba wu wọn nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 lai fi ẹgbẹ oṣelu ṣe.
"Mo gbagbọ pe lasiko idibo to n bọ yii, agbara ijọba apapọ ko ni ṣiṣẹ kankan. O ti ṣiṣẹ ri nigba ni ipinlẹ Ekiti amọ mi o ro pe o maa ṣiṣẹ mọ bayii, awọn ọmọ Naijiria maa fi oju awọn oloṣelu ri mabo.
"Wọn maa ṣafihan rẹ pe awọn ko kan fẹ maa jokoo lasan lai da si ohun to n ṣẹlẹ mọ, ohun ti mo si n sọ dami loju."
Lori iṣejọba ipinlẹ Oyo leyin to ba kuro lori ipo, Makinde ni iṣejọba oun ti pese ilana to jẹ pe ẹni to b agba ipo lẹyin le tọ lati tẹsiwaju pẹlu awọn iṣẹ ti awọn n ba lọ.
Gomina naa ni bi o tilẹ jẹ pe oun maa sọ ẹni to wu oun lati fa kalẹ lati gba ipo gomina Oyo lẹyin oun, o ni awọn eeyan ipinlẹ Oyo lo maa dibo yan ẹni ti wọn ba fẹ ko di gomina Oyo.
O wa sekilọ fawọn eeyan lati ṣe pẹlẹ, ki wọn ma dibo fun ẹni ti ko ni ikapa lati ṣejọba nitori o maa ni ipa to lagbara ọlọjọ pipẹ lori ipinlẹ naa.
"Mo maa n sọ fawọn eeyan pe maa sọ ẹni to wu mi lati fa kelẹ amọ awọn eeyan lo maa dibo yan ẹni to wu wọn.
"Fun idi eyi, a gbọdọ ri pe a yan ẹni to maa ṣiṣẹ daadaa, nitori ni kete ti a ba ti yan ẹnikan, o di ọdun mẹrin mii ka to le yipada."
"Ẹni to ba le mu itẹsiwaju ba awọn ohun rere ti a ti gbe ṣe ni ipinlẹ Oyo ni maa ṣe atilẹyin fun nibi eto idibo to n bọ"
Oniruuru ọrọ lo ti n lọ labẹlẹ pe o ṣeeṣe ki Makinde ṣe atilẹyin fun Adekanbi, ẹni to ti figba kan ri jẹ kọmiṣanna fun eto isuna ni ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi eni to maa gba ipo lẹyin rẹ.
Bakan naa ni olori ile aṣofin ipinlẹ Oyo, Debo Ogundoyin sọ ninu ọsẹ yii pe awọn lọ ṣe ipade owurọ nile Adekanmbi, ẹni ti awọn fẹnuko le lori lati gbegba ibo gomina labẹ ẹgbẹ oselu Allied Peoples Movement, APM ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ.
Labẹ iṣejọba Abiola Ajimobi ni Adekanbi ti ṣe kọmiṣanna eto isuna labẹ iṣjọba All progressives Congress, APC.
Nigba to n fesi si awuyewuye naa, Makinde ni ẹnikẹni to ba ti oun ba ri pe o ni ikapa lati ṣejọba to si nifẹẹ ipinlẹ Oyo ni oun maa ṣe atilẹyin fun.
O ni ohun to jẹ afojusun oun ni bi ijọba to duro ire ṣe maa tẹsiwaju ni ipinlẹ Oyo nipasẹ pipese ilana iṣejọba to n ṣiṣẹ eyi ti ijọba mii to ba gbapo le maa ṣiṣẹ le lori lọ dipo gbigbe awọn ilana tuntun mii kalẹ.
Makinde fi kun pe ipinlẹ Oyo ti sun kuro ninu ṣiṣẹṣẹ maa ṣawari awọn ibi ti ọrọ wa bikoṣe pipese ilana ti awọn ọrọ naa fi maa jẹ amulo lojuna ati le pese awọn ohun idagbasoke ati ilọsiwaju fawọn araalu.