You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amotekun nawọ́ gán afurasí agbéṣùmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Ondo
Ileeṣẹ ẹṣọ aabo Amotekun tẹka ipinlẹ Ondo ti nawọ gan awọn afurasi agbeṣumọmi mẹrin ti igbagbọ wa pe wọn lọwọ ninu awọn iwa ọdaran to n waye kaakiri ipinlẹ naa lati bii oṣu mẹjọ sẹyin.
Ọga agba ileeṣẹ Amotekun ipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Akure.
Adeleye sọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko tawọn Amotekun ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo mii latari italolobo kan ti wọn gbọ.
O ni awọn afurasi ti ọwọ tẹ naa ni wọn lọwọ ninu idigunjale, ijinigbe ati biba awọn nnkan ilu jẹ to n waye kaakiri ipinlẹ naa.
O sọ pe ọwọ tẹ olori awọn afurasi ọdaran naa, ẹni to ni lati ipinlẹ mii ni won ti n dari rẹ, nigba ti wọn koju awọn ọdaran naa loju ikọlu to lagbara.
O fi kun pe ilana tawọn eeyan kan fi n pese ohun elo fawọn afurasi ọdaran naa ni awọn ti ge danu, tọwọ si tun tẹ awọn afurasi ọdaran mii lasikọ ikọlu naa.
Ọga Amotekun naa salaye pe awọn ti fa awọn afurasi naa le ileeṣẹ eto aabo ọtelẹmuyẹ, DSS lọwọ nitori bi ẹṣẹ ṣe lagbara to.
O sọ pe mẹrin ninu awọn afurasi agbeṣumọmi ti ọwọ tẹ naa ni won ti jẹwọ pe awọn lọwọ ninu awon iwa ọdaran to n da omi alaafia ipinlẹ naa ru lati bii oṣu mẹjọ sẹyin.
Adeyeye kọ lati sọrọ nipa bi awọn afurasi naa ṣe n ṣiṣẹ bo ṣẹ ni ṣiṣe bẹẹ le ni ipa lori iwadii ti ajọ DSS n ṣe lọwọ.
O tẹsiwaju pe igbesẹ yii n waye latari akitiyan ijọba lati da aabo to peye pada si ipinlẹ Ondo, to si fi da awọn araalu loju pe gbogbo awọn ibi tawọn afurasi naa fi n ṣe ibuba ninu igbo ni awọn ti wo danu.
O woye pe awọn ẹnubode to w ani ipinlẹ Ondo, ti wọn paala pẹlu ipinlẹ mẹta jẹ ipenija nla lori eto aabo.
O fi kun pe ajọṣepọ ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ Ologun, DSS, ajọ ẹṣọ ara ẹni laabo ilu, NSCDC ati Amotekun ti mu alekun ba bi awọn ẹṣọ aabo ṣe n wọnu igbo bayii lati lọ le awọn afurasi ọdaran kuro ninu igbo ipinlẹ Ondo.
Bakan naa lo fi kun pe igbesẹ ti bẹrẹ lati ri pe awọn ko kan maa nawọ gan afurasi lasan mọ, bi ko ṣe pe wọn n koju ijiya to tọ si wọn ti ọwọ ofin ba ti tẹ wọn.
Adeyeye ni awọn ṣe aridaju rẹ pe awọn afurasi ti iye to 142 ni awọn pari iwadii ni oṣu to kọja nikan, ti awọn si tig be ẹjọ wọn lọ sile ẹjọ fun ijiya to tọ.
O ni lara ẹsun tawọn to n koju igbẹjọ n koju bayii ni ijinigbe, dida ẹran jẹ oko lọna aitọ, awọn ẹsun mii to niṣẹ pẹlu wahala awọn darandaran ati awọn ẹlẹgbẹ okunkun.
O fi kun pe awọn afurasi mẹrinlelọgọta ni awọn tun n ṣe iwadii wọn lọwọ, ti wọn si maa koju igbẹjọ ni kete tio iwadii nipa won ba ti pari ati abajade iwadii wọn.