Makinde ní ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo kọjá ọ̀rọ̀ Kọ́kọ́rọ́ Alátẹ, Oriyomi náà dá a padà

Seyi Makinde wọ buba olomi bukuu pẹlu fila, Oriyomi Hamzat wọ ẹwu yẹlo, o fọwọ lẹran

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X/Oriyomi Hamzat/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fakaaja to n lọ laarin Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ati Oriyomi Hamzat to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord tun ti bọna mii yọ, lẹyin tawọn mejeeji tun tahun sira wọn.

Makinde lo kọkọ sọ pe didupo gomina ipinlẹ Oyo kii ṣe ọrọ awada, o si kọja ọrọ Kọkọrọ Alatẹ, iyẹn eto kan ti Oriyomi maa n ṣe lori redio Agidigbo FM n'Ibadan.

Nigba to n bawọn eeyan sọrọ lasiko ipolongo ibo, Makinde ni ''ẹ jẹ ki n sọ fun yin pe ko si ẹni to ṣe e fọwọ rọ danu ninu igbimọ ijọba mi.

Akọṣẹmọṣẹ onimọ ẹro ni emi ti mo jẹ gomina ipinblẹ Oyo, agbẹjọro to ti dupo agbẹjọro agba ipinlẹ Oyo ri mu ni igbakeji mi.

Ọjọgbọn nipa imọ ọrọ aje ni akọwe ijọba ipinlẹ Oyo i ṣe, bakan naa ni adari awọn oṣiṣẹ l''Oyo ti gboye Ọmọwe lẹnu ẹkọ.

Iru awọn eeyan to n ṣe ijọba ipinlẹ Oyo pẹlu mi niyii, to ba dẹ wa wu yin ki ẹ lọ dibo fun ẹni to sọ pe agbẹjọro loun amọ ti ko de ile ẹjọ ri.

Awa o kan maa sọrọ tori pe a fẹ ṣe oṣelu, ẹnikan loun a ṣe ileeṣẹ ijọba Kokoro Alatẹ.

Ọrọ iṣejọba kii ṣe nnkan awada rara tori pe o ni ṣe pẹlu igbesi aye awọn eeyan wa.

Ibi kii ṣe ibi a ti le maa pa awọn eeyan lẹrin-in, ọrọ oṣelu ni ṣe pẹlu irori lati gbe awọn igbesẹ to lọọrin.

Nigba to n fesi, Oriyomi naa sọ fawọn eeyan wi pe iṣẹ akọroyin ni iṣẹ toun n ṣe tawọn eeyan si mọ oun mọ.

Oriyomi ni ileeṣẹ redio toun ti n ṣiṣẹ wa lara nnkan tawọn oloṣelu maa n lo.

Oludasilẹ Agidigbo FM sọ pe ọrọ ti n dun Makinde lo jẹ ko maa sọrọ bayẹn.

O fikun ọrọ rẹ pe oun ṣetan lati tu aṣiri Makinde fun gbogbo aye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Má forúkọ mi ṣe ìpolongo ìbò mọ́, Makinde dá a padà fún Oriyomi

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina Seyi Makinde ìpínlẹ̀ Oyo ti kìlọ fún oludije sipo gomina f'ẹgbẹ òṣèlú Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, wí pé ko ye fi orúkọ oun ṣe ìpolongo ibo mọ.

Ṣaaju ni Oriyomi sọ pe oun loun mu Makinde wọ agbo oselu.

Amọ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo to sọrọ níbí eto kan niluu Ibadan sọ pe ki Oriyomi atawon mii ti wọn n l'orukọ oun fún oselu jawọ nbẹ tori oun ko dupo gomina ipinlẹ Oyo mọ.

Makinde wa rọ àwọn eeyan to n dupo òṣèlú wí pé ki wọn gbaju mọ nnkan ti wọn ba fẹ ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Oyo, dipo bi wọn ṣe n bu oun kaakiri.

''Mo ri awọn eeyan kan ti wọn n sọ kaakiri pe awọn fẹ jẹ gomina ipinlẹ Oyo.

Mo tun ri ọkan to ni oun loun mu mi wọ inu oṣelu, amọ, emi o dije fun ipo gomina mọ o.

Awọn eeyan ipinlẹ Oyo ti fun mi lanfaani lati sin wọn, mo fẹ ki awọn naa lọ sọ fun araalu nnkan ti wọn ba fẹ ṣe yatọ; ẹ ye bu Makinde mọ.

Ẹ le maa bu Bimbo atawọn ọmọlẹyin rẹ, koda ẹ le maa bu ara yin; ṣugbọn emi o dupo gomina mọ.

Ki lo de ti Makinde ko ṣe awọn nnkan kan? Ṣe nnkan ti ẹ fẹ maa fi ṣe ipolongo ibo niyẹn?

Mo fẹ ki ẹ mọ wi pe emi ti ṣe temi o,'' Makinde lo ṣalaye bẹẹ.