'Ẹ má sọ ìrètí nù, díẹ̀ ló kù kí Nàìjíríà dé ibi gíga - Ààrẹ Tinubu

Aare Bola Tinubu, o wọṣọ alawọ aro o si de fila alawọ kan naa, o fi igo soju, o n wo ẹgbẹ. Ẹrọ gbohungbohun han nisalẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin (66) Ominira Naijiria ṣe ku ọjọ diẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti rọ araalu lati ma ṣe sọ ireti nu lori orilẹede yii, o ni diẹ naa lo ku ki Naijiria de ibi giga.

Abẹnugan ile igbimọ Aṣoju, Tajudeen Abass, to ṣoju fun Aarẹ Tinubu nibi irun Jimọ ti wọn ki l'Abuja lọjọ Eti, ni mọṣalaṣi ijọba apapọ, lati sami ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ominira Naijiria, lo sọrọ yii.

"Bi Naijiria ko tilẹ ti I si nibi to yẹ ko wa, sibẹ o ti wa lojuna ati de ibi giga"

Ni itẹsiwaju ọrọ Aarẹ Tinubu nibi irun Jimọ naa, o ṣalaye pe orilẹede Naijiria ti wa loju ọna ati de ibi giga rẹ, bi ko tilẹ ti I si nibi to yẹ ko wa lọwọlọwọ.

O rọ araalu lati ti atunto ti ijọba yii n ṣe lẹyin, ki Naijiria le de ilẹ ileri rẹ.

'Ọdun kẹrindinlaadọrin ti Naijiria pe yii fi han pe agba ti de, bo tiẹ jẹ pe ta a ba wo ba a sẹ n ba a bọ, nnkan ko ṣe daadaa.

"Ọlọkan-o-jọkan aburu lo koju Naijiria nigba kan ri, bẹẹ si ni orilẹede yii padanu awọn anfaani to pọ.

"Amọ a dupẹ lọwọ ọba Allah Alagbara to fun wa ni ẹmi ati alaafia lati ri ayajọ yii ninu itan lonii."

Bẹẹ ni Abass to gbẹnusọ fun Tinubu wi.

"Ẹyin araalu, ẹ fun Tinubu lanfaani lati tẹsiwaju ninu atunṣe rẹ"

Ni itẹsiwaju ọrọ Abẹnugan ile igbimọ aṣoju naa, o ni:

"Iṣẹ ti mo fẹ jẹ lorukọ Aarẹ fun orilẹede yii, ni pe kawọn eeyan ma sọ ireti nu.

Alaafia n pada bọ sorilẹede yii. Idagbasoke n pada bọ sorilẹede yii. Nnkan yoo pada daa ba a ṣe n ba Dẹmokresi lọ."

O fi kun un pe ki araalu ma ṣe wo aṣiṣe to ti wa kọja, tabi anfaani ti Naijiria ti sọnu, bi ko ṣe ki wọn maa wo atunṣe ti Tinubu n ṣe.

Abẹnugan ile igbimọ aṣoju naa wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati jẹ ki Tinubu pari iṣẹ to bẹrẹ.

O ni ki wọn fun un ni anfaani lẹẹkan si I, nitori awọn ọmọ Naijiria paapaa ti farajin pupọ, asiko si ti n to bọ lati jẹre ifarajin wọn gẹgẹ bo ṣe sọ.