Ọlọ́pàá ṣàwárí ibi táwọn ajínigbé káwọn Àgùnbánirọ̀ Oyo sí, ohun tó ń dáwọn lọ́wọ́ kọ́ rèé

Awọn ọlọpaa ninu igbo atawọn agunbanirọ to wọ aṣọ funfun ati sokoto khaki
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹkọ ti n fi ojuu mimu han fawọn ọlọpaa ipinlẹ Imo lori awọn agunbanirọ ogun (20) ti ajinigbe ji gbe l'Ọjọbọ to kọja pẹlu awọn ero ọkọ mi-in.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Audu Garba Bosso, ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti mọ ibuba awọn ajinigbe naa ninu igbo, nibi ti wọn ko awọn ti wọn ji gbe naa si nipinlẹ Imo.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni Bosso sọrọ idaniloju naa.

Kọkọrọ kan to ni o n ba eyin aja jẹ ni pe o ṣee ṣe kawọn awọn ajinigbe ọhun ti kẹ ado oloro to le bu gbamu sawọn ibi ti eeyan le gba de ọdọ wọn.

O ni òye foju han pe wọn ti kẹ ohun abugbamu IED to le fa iku sitosi.

"Ẹrọ 'drone' ti fi ibi ti wọn wa han wa ninu igbo''

Ileeṣẹ ọlọpaa ni "ẹrọ 'drone' ti fi ibi ti wọn wa han wa ninu igbo, a maa gbe katakata atawọn ọkọ akọtami lọ sibẹ lati doola awọn ti wọn ji gbe."

Ni itẹsiwaju alaye Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Audu Garba Bosso, o ni nigba tawọn ẹṣọ alaabo dọdẹ awọn ajinigbe naa ninu igbo ni wọn fi ẹrọ drone mọ ibi ti wọn wa.

"A maa pada sinu igbo nigbakigba, ana naa, a wa ninu igbo, a dọdẹ wọn debi kan, a si ri I pe wọn ti fi ado oloro yi ibuba naa."

"A n lọ sibẹ pẹlu awọn ọkọ̀ alagbara bii bulldozer atawọn akọtami, ka fi eyi wo ba a ṣe maa ri awọn to wa lọdọ wọn gba lai jẹ pe wọn farapa."

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tẹ o ba gbagbe, ayajọ ọjọ ominira Naijiria, ti orilẹede yii pe ọdun mẹrindinlaadọrin ni awọn ajinigbe gbe awọn agunbanrọ to n lọ sinru ilu naa pẹlu awọn ero ọkọ mi-in wọgbo lọ.

Ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni awọn agunbanirọ naa to gbera lati ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, n rin irinajo lọ si Abia ati Akwa Ibom, fun ipagọ.

Ọkọ meji ni wọn gbe, ojiji si ni awọn to ji wọn gbe da wọn lọna loju ọna Owerri-Onitsha, lagbegbe Umunoha, ipinlẹ Imo.

Wọn ko wọn wọgbo lọ, amọ awọn dẹrẹba ọkọ wọn raye sa, awọn ni wọn si fi to awọn agbofinro to wa nitosi leti.

Awọn obi tọrọ naa kan ti ko si idaamu lati Ọjọbọ ti iṣẹlẹ yii ti waye.

Awọn ajinigbe ọhun n beere aadọta miliọnu owo itusilẹ lori ẹni kọọkan awọn ti wọn ji gbe.

Apapọ owo ti wọn n beere naa jẹ N950m.

Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Imo ti kede pe awọn ti ri eeyan mẹwaa doola lara awọn ti wọn ji gbe naa.

Bo tilẹ jẹ pe Alukoro ọlọpaa ibẹ, Henry Okoye, ko le fidi ẹ mulẹ boya lara awọn agunbanirọ naa ni awọn to ni awọn gba silẹ n ṣe.

Igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ṣáájú àwọn agbófinró ní Imo láti wá àgùnbánirọ̀ 20 àtàwọn èrò mí-ìn tí ajínigbé gbé lọ

Lojuna ati ri awọn agunbanirọ ti iye wọn to ogun (20), atawọn ero ọkọ mi-in tawọn ajinigbe gbe lọ nipinlẹ Imo l'Ọjọbọ ọsẹ yii, Ọga agba ọlọpaa pata lorilẹede Naijiria, Olatunji Disu, ti paṣẹ fun Igbakeji rẹ to wa fun iru iṣẹ bayii, Shehu Nadada, lati lewaju nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada.

Ọga agba ọlọpaa pata paṣẹ naa ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Naijiria, CSP Anietie Iniedu, fi sita lọjọ keji oṣu Kẹwaa ọdun 2026.

Aṣẹ IGP Olatunji naa lo gbe DIG Shehu Nadada pẹlu awọn kọmiṣanna ọlọpaa meji mi-in de Imo, lati dari ọna ti wọn yoo fi ri awọn to wa ni ahamọ ajinigbe naa gba pada.

Gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa naa ṣe ṣalaye, ẹsẹkẹsẹ ti DIG Nadada ti balẹ sipinlẹ Imo lo ti de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Alukoro ọlọpaa Naijiria sọ pe bẹẹ naa ni iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati gba awọn to wa nigbekun ajinigbe naa kalẹ.

O ni DIG Nadada ti ṣagbeyẹwo ilana ti wọn fẹ fi wa awọn eeyan naa ri, ati bi wọn yoo ṣe pin awọn ti yoo ṣiṣẹ naa sibi to yẹ.

O ni eto ti n lọ lori awọn irinṣẹ ti wọn yoo lo pẹlu, ki idari too tun waye lori iṣẹ iwadii naa.

Awọn ti wọn jọ ṣe agbeyẹwo iṣẹlẹ yii bi atẹjade naa ṣe wi ni: Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo; Audu Garba Bosso ati Kọmiṣanna ọlọpaa ijọba apapọ to wa fun iṣẹ bawọnyi; Akpan Anifiok.