Ìjọba Tinubu yíì kì í bá ẹgbẹ òṣìṣẹ́ sọ àsọyépọ̀- Joe Ajaero, Ààrẹ NLC

Oríṣun àwòrán, Joe Ajaero/FB/Nigerian Presidency
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ Naijiria; "Nigeria Labour Congress" (NLC), Joe Ajaero, ti fẹsun kan ijọba Aarẹ Bola Tinubu, pe wọn ki i ba ẹgbẹ naa sọ aṣoyepọ bo ṣe yẹ.
Ajaero to sọrọ yii lọjọ Abamẹta lori eto kan, Mic On Podcast, ṣapejuwe iṣakoso naa bii eyi to dẹ́yẹ si ẹgbẹ oṣiṣẹ.
"Ọpọ igbiyanju ni NLC ti ṣe lati ba ijọba apapọ sọrọ, amọ a ko gbọ abọ kankan"
Gẹgẹ bi Aarẹ NLC ṣe wi, o ni lọdun 2025, nigba ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n gbero lati yan iṣẹ lodi loṣu Kejila, ọpọ iyanju lawọn gba lati ba ijọba apapọ sọrọ ṣaaju.
Ajaero sọ pe NLC ko ri esi kankan gba lọdọ ijọba apapọ laaarin oṣu Karun-un si Ikejila ọdun 2025 naa.
"Lati bii ọdun meji sẹyin, ki I ṣe ijọba to n ba eeyan sọ asọye ni. Ijọba yii ki i sọ asọyepọ."
Ajaero lo sọ bẹẹ.
O ni nigba tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba too fi ẹhonu han nigboro aye ni wọn to maa n dahun.
Ajaero fi kun un pe ijọba ti ya kuro lara ajọ oṣiṣẹ.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa sọ pe awọn gomina kan dide si ọrọ naa lasiko ọhun, eyi to fa ipade kan to waye laaarin awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ atawọn gomina.
O ni amọ lati igba naa, ajọsọ awọn pẹlu ijọba ko ju perete lọ.
Latigba naa ni ijọba ti n ba eto wọn lọ lai wo ẹhonu awọn oṣiṣẹ mọ gẹgẹ bo ṣe sọ.
"Ṣe ẹ ri awọn ọrọ naa lati oṣu Kejila ọdun to kọja titi di asiko yii, o waa bẹẹ ni. Ijọba n ba okoowo tiẹ lọ ni. Gbogbo eeyan ni ọta wọn."
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹka ẹgbẹ oṣiṣẹ; Joint National Public Service Negotiating Council (JNPSNC) kede iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ mẹta.
Wọn lawọn yoo daṣẹ silẹ patapata bi ijọba apapọ ba kọ lati din owo epo bẹntiroolu ku si ẹẹdẹgbẹta naira (N500) fun jala kan.























