Agbésùnmọ̀mì tún pa àgbẹ̀ 15 sínú oko, mẹ́ta di àwátì

Oríṣun àwòrán, Others
Ko din ni eeyan mẹẹẹdogun (15) ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno ti kede bayii pe wọn padanu ẹmi wọn sọwọ ikọ afurasi Boko Haram l'Ọjọru ọsẹ yii, bẹẹ ni wọn ni awọn ṣi n wa awọn mẹta mi-in ti wọn di awati lẹyin ikọlu awọn agbesunmọmi naa.
Iṣẹlẹ yii waye nijọba ibilẹ Marte, ipinlẹ Borno, lasiko tawọn agbẹ naa wa ninu oko wọn lọwọ irọlẹ, lagbegbe Ala ati Musune.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Borno, Nahum Daso, fidi ipaniyan ati ijinigbe naa mulẹ fun ẹka iroyin Punch lọjọ Ẹti.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Gẹgẹ bi Daso ṣe wi:
"Bẹẹ ni, ikọlu kan waye ni Marte. Wọn pa eeyan mẹẹẹdogun bẹẹ ni a ko ti i ri awọn kan. A ti n ṣiṣẹ lorii ba ṣe maa mọ ibi ti wọn wa."
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Borno tẹsiwaju, pe ohun to ṣẹlẹ naa ko ti i foju han tan, o ni awọn nnkan kan ṣi farasin.
O ni kọmandi ọlọpaa yoo maa mu alaye kikun lori rẹ wa bi otitọ ba ṣe n foju han nipa ikọlu naa.
Amọ awọn eeyan agbegbe naa ti wọn ba ẹka iroyin Punch sọrọ, ṣalaye pe mejidinlogun ni awọn agbẹ ti agbebọn kọlu.
Wọn ni wọn pa mẹẹẹdogun, awọn si ri oku wọn nibi ti wọn pa wọn si, Ọjọbọ ti I ṣe ọjọ keji ni awọn si sinku wọn nilana ẹsin Islam.
Wọn fi kun un pe awọn ti wọn pa naa jẹ ọdọkunrin, awọn baale ile atawọn agbalagba ti wọn lọ sinu oko wọn lati bojuto o tabi ṣẹgi wale.
"Wọn bẹ ori awọn kan, a ko tilẹ le da wọn mọ"
Ẹnikan lara awọn eeyan agbegbe naa sọ pe awọn agbebọn ọhun dena de awọn agbẹ naa ni.
"Awọn agbesunmọmi lo dena de wọn nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ oojọ wọn.
"Wọn dè wọn, wọn fipa mu wọn dubulẹ, wọn si pa wọn."
Ara agbegbe naa ti ko darukọ rẹ tẹsiwaju, o ni wọn bẹ ori awọn kan lara awọn agbẹ naa, o si jẹ ko ṣoro lati da wọn mọ pe lagbaja ree.
Tẹ o ba gbagbe, iwa iṣekupa awọn agbẹ sinu oko yii n waye kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede yii, eyi to n mu ọpọ agbẹ ma le lọ soko, to si n mu ọwọngogo ounjẹ waye pẹlu.























