Ṣe ìwàásù nínú ọkọ̀ kó o rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ he, ìjọba ṣàgbékalẹ̀ òfin tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki kirakita owurọ too bẹrẹ, ohun ariwo orin iyin ati ọpẹ lo maa n gba gbogbo garaaji bọọsu Neoplan to wa ni olu-ilu orileede Ghana tii ṣe Accra, pẹlu bi awọn ẹlesin Kristiẹni ṣe maa n pejọ lati waasu ihinrere ninu awọn bọọsi to n rin irin ajo kaakiri.
Pẹlu ilu ati ijo ni Boateng Bismark James fi maa n lewaju awọn mẹtala ti wọn n ṣiṣẹ ihinrere, okunrin mẹsan ati obinrin mẹrin lati gbadura fun awọn awakọ ati arinrin-ajo to n lọ kaakiri orileede Ghana.
Ghana jẹ orileede ti ẹlẹsin Kristiẹni pọ si, to si jẹ pe iwaasu ninu awọn bọọsi akero gbilẹ kaakiri.
Ninu awọn bọọsi to n rin irin-ajo lọ si ọna to jinna, ẹ maa ri awọn pasitọ ti wọn n waasu ihinrere.
Lọpọ igba, wọn maa n duro lẹyin awakọ, ti awọn miran si maa n rin lọ siwaju ati si ẹyin ninu bọọsi naa lati ṣiṣẹ ti wọn gba, bii kika Bibeli, sisọrọ Ọlọrun ati pipe awọn ẹlẹṣẹ lati ronu piwada.
Ko nii ṣe pẹlu bi irin ajo naa ṣe le jinna to, tabi iye wakati ti wọn lo lori irin ajo ọhun, wọn kii danu titi wọn yoo fi de ebute ibi ti wọn n lọ.
Nigba miran, awọn to ba nigbagbọ ninu awọn bọọsi, maa n fi owo ta awọn oniwaasu yii lọrẹ, lati fi ṣe iranwọ fun iṣẹ iranṣẹ wọn.
Ṣugbọn ofin tuntun ti ijọba orileede Ghana ṣẹṣẹ gbe kalẹ bayii, ko ni faaye gba iru awọn iwa wọnyi mọ.
Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ, wi pe o n waasu ninu awọn bọọsi akero, yoo lọ ṣe ẹwọn oṣu mẹjọ gbako, tabi ko san ojilelaadọta owo dọla, tabi ki iru ẹni bẹẹ fi ijiya mejeeji gbara.
Ofin tuntun ti ile igbimọ aṣofin naa gbe kalẹ ninu oṣu Karun-un, ti yoo si bẹrẹ sii fẹsẹ mulẹ lọsẹ diẹ si asiko yii, lo tako wiwaasu ati tita ọja ninu awọn bọọsi to ba n rin irin ajo.
Wọn ni iwa ti ko lẹtọọ ni mejeeji, ati pe kii fun awọn arinrin-ajo ni anfaani si aabo ati igbayegbadun wọn ninu ọkọ.
Boateng, oniwaasu ẹni ọdun mọkanlelọgọta nile ijọsin Gospel Light, lo ti n waasu ninu awọn ọkọ to n rin irin-ajo lati Neoplan lati ọdun 2023.
"Mo maa n waasu ninu awọn bọọsi nitori pe kii ṣe gbogbo eeyan lo ni oore ọfẹ lati lọ si ṣọọṣi lọjọ isinmi. Ọpọ awọn arinrin-ajo ni wọn nilo iwaasu wa igbala ọkan ti a n ṣe lati ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ. A tun maa n mu awọn alaisan larada ninu awọn bọọsi miran," O sọ fun BBC.
Boateng wọ aṣọ awọn pasitọ lasiko to wọ inu ọkan lara awọn bọọsi to n lọ si Kumasi, ilu keji to tobi julọ ni Ghana.
Oniwaasu naa ba BBC sọrọ ko to di pe bọọsi naa gbera, ko ma ba a lugbadi ofin tuntun.
Awọn arinrin-ajo kan tẹtisilẹ lati gbọ ọrọ iwaasu rẹ, awọn miran ko tiẹ wo ọdọ rẹ, pẹlu bi wọn ṣe n tẹ foonu wọn, ti awọn miran si tun n ba awọn kan sọrọ lori foonu.
"Inu awọn arinrin-ajo kan maa n dun si iwaasu mi. Awọn miran a tiẹ maa sọ pe awọn ko gbọ iru iwaasu mi ri ni ṣọọṣi awọn, ṣugbọn nitori awọn iwaasu mi, o n jẹ ki wọn mọ ohun ti Bibeli sọ," o sọ bẹẹ.
Ofin ati agbekalẹ tuntun yii ti pin erongba awọn eeyan si ọtọọtọ.
Awọn to n bu ẹnu atẹ lu iwa naa sọ pe iwa ti ko tọ ni, nitori pe o le ṣi awọn awakọ lọkan, ṣugbọn ti awọn miran n sọ pe iwaasu ihunrere jẹ ojuṣe Kristiẹni , ti wọn si gbọdọ daabo bo o labẹ ilana anfaani si ẹsin ṣiṣe.
Obinrin kan to fẹ ki a pe orukọ oun ni Chery Lokko sọ pe nnkan to tẹ oun lọrun ni lati maa rin irin-ajo ninu alaafia ati ifọkanbalẹ.
"Nko nifẹẹ si i, nitori pe ko dara. Awọn miran a maa ja itọ sii yin lara lai mọ, paapaa bi ẹ ba jokoo sitosi wọn, wọn si n ṣe ohun ti ko tọ nipasẹ ariwo ati itọ titu. Mo maa n fẹ alaafi mi nigba ti mo ba n rin irin-ajo."
Ninu fọnran kan to n kaakiri ori ayelujara laipẹ yii, arinrin-ajo kan ninu bọọsi kekere ni a ri to n ba oniwaasu kan fa waala lasiko to fẹẹ wọle.
"Bọ silẹ, mo sọ pe ki o bọ silẹ," o n pariwo mọ-ọn.
Ohun ti awọn kan maa n sọ ni pe iwaasu ihinrere ninu bọọsi akero maa n fun awọn ti kii lọ si ṣọọṣi gbọ ọrọ Ọlọrun.
Bernice Nartey, arinrin-ajo kan to n lọ si Kumasi, sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn gba awọn pasitọ laaye lati maa waasu, niwọn igba ti awọn arinrin-ajo ba ti fọwọ si i.
"Iwaasu nigba miran maa n jẹ ki awọn eeyan yiwa pada. Fun apẹẹrẹ, bi eeyan ba n koju iporuru ọkan, iwaasu pasitọ le fun un ni ireti ọtun," o sọ bẹẹ.
"Owo ti mo n ri nibi iwaasu ni mo fi n bọ ẹbi mi"
Boatenga sọ pe ofin naa ba oun lojiji, to si mi oun titi, ati pe niṣe lo yẹ ki wọn fun awọn ẹlẹsin laaye lati maa waasu wọn.
"O n kọ wa lominu, nitori pe ọpọ awọn pasitọ nibi ni wọn gbojule iwaasu lati maa fi bọ iyawo atawọn ọmọ wọn, nipasẹ owo ti awọn eeyan n fun wọn ninu ọkọ," o sọ ọ di mimọ.
"Ki ijọba gba wa laaye lati maa waasu ninu bọọsi, ka si maa sọkalẹ nigba ti a ba fẹẹ kuro ni Accra," o fi kun ọrọ rẹ.
Fun Boateng, o gba wi pe iwaasu kii ṣe ipe nikan, bi ko ṣe pe o tun jẹ ọna pataki to n jẹ ki wọn ri ọwọ mu lọ sẹnu nipasẹ owo ti wọn n pa.
"Mo ti le tọju awọn ọmọ mi ati eto ẹkọ wọn. Abigbẹyin mi ṣẹṣẹ pari ni fasiti ni, ati pe idaji owo ti mo fi ran an lọ, lo jẹ pe owo ti awọn eeyan n fun mi nibi ti mọ ti n waasu."
"Ofin tuntun naa ko tẹ ofin ẹsin ṣiṣe loju mọlẹ"
Ofin ilẹ Ghana fi anfaani iru ẹsin ti eeyan ba nifẹ si lati ṣe silẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ofin naa lo nii ṣe pẹlu eto aabo araalu.
Ọdun 2012 ni wọn kọkọ wọgile iwaasu ninu bọọsi ni Ghana, pẹlu pe awọn to ba lugbadi ofin naa yoo lo ọgbọn ọjọ ninu ẹwọn.
Ṣugbọn ṣa, wọn ko fi bẹẹ fi idi rẹ mulẹ, idi ree ti iwa naa fi n gbilẹ si, paapaa lawọn inu bọọsi, ofin naa ti wa ni ijiya ninu bayii labẹ ofin, iyẹn fun awọn to ba lugbadi rẹ.
Wiwaasu pẹlu ẹrọn gbohungbohun lẹ tun le ri lawọn garaaji ati ibudokọ ni Ghana, ṣugbọn ofin naa ko ba wọn wi.
Ajọ to n ri sọrọ ẹsin Kristiẹni nilẹ Ghana, Christian Council of Ghana kọ lati ba BBC sọrọ lori igbesẹ tuntun naa.
Ṣugbọn ṣa, pasitọ agba kan nile ijọsin International Central Gospel Church, Rev Enoch Paul Hayes, sọ pe oun ko lero wi pe ofin tuntun naa tẹ oju ofin ṣiṣẹ oniruuru ẹsin loju mọlẹ.
O rọ awọn pasitọ bii tiẹ lati ma ṣe lugbadi ofin yii, ati pe ki wọn wa ọna miran lati maa fi waasu ihinrere wọn.
"Ikanni ayelujara wa nibẹ gẹgẹ bi ọna miran, nibi ti eeyan ti le waasu fun ogunlọgọ awọn eeyan," o sọ bẹẹ.
Ṣugbọn fun Boateng ati awọn oniwaasu ninu bọọsi bii tiẹ, ofin tuntun naa gbegi dina ọna ti wọn n gba pa owo wọle sapo ara wọn.

























