Ìjìyà tó wà lábẹ́ òfin rèé fún ẹnikẹ́ni tó lọ́wọ́ sí 'dìbò kó o sebẹ̀'

Àkọlé fídíò, Ìjìyà tó wà lábẹ́ òfin rèé fún ẹnikẹ́ni tó lọ́wọ́ sí 'dìbò kó o sebẹ̀'
Ìjìyà tó wà lábẹ́ òfin rèé fún ẹnikẹ́ni tó lọ́wọ́ sí 'dìbò kó o sebẹ̀'
Ọkunrin kan mu beba lọwọ lẹgbẹẹ ọlọpaa to gbe ibọn dani to n rin lọ
Published

Oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC, Eniola Oladapo, ti ṣalaye ijiya to wa fun ẹnikẹni to ba fi ibo ṣe kata-kara lasiko eto idibo.

Oladapo sọ fun BBC News Yoruba pe '' ti eeyan ba ra ibo rẹ to fun ọ ni N5,000 tabi N10,000 lonii, ṣe owo yẹn maa to ọ jẹun fun ọdun mẹrin ti ẹniyẹn maa fi wa nipo?''

Aṣoju ajọ INEC ni ofin eto idibo Naijiria ti wọn n pe ni ''electoral act'' abala 22(a&b) sọ pe ọmọ Naijiria ko gbọdọ ra tabi ta ibo.

''Ẹni to ra ibo rẹ ti ra ọkan rẹ niyẹn, o si i ni lẹtọọ lati beere fun nnkan ti yoo maye dẹrun fun iwọ atawọn ọmọ rẹ.

Gbogbo owo ti ẹni to ba ra ibo rẹ ba na ni yoo kọkọ wa to ba ti de ipo tan.

Eyi tumọ si pe a ko gbọdọ ta ibo wa, ohun to yẹ ka ṣe ni pe ki a dibo fun ẹni to ba wu wa.

Ofin ko sọ pe kawọn ẹgbẹ oṣelu ma fawọn eeyan ni nnkan bo ya bi owo ọkọ.

Ṣugbọn nnkan ti ofin lodi si ni pe ki o gba owo lọwọ eeyan tori ki o le dibo fun ẹni naa,'' Oladapo ṣalaye.

Aṣoju INEC naa sọ pe awọn agbofinro ati ajọ EFCC lo maa n fọwọ ofin mawọn to ba tapa si ofin yii.

Ọgbẹni Oladapo wa rọ gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn ma ṣe lọwọ ninu ''dibo ko o sebẹ.''