Ó dèèwọ̀! Ẹgbẹ́ òṣèlú APC fòfin de àwọn olùdíje pé wọn ò gbọdọ̀ rin ìrìn àjò lọ skè òkun lásìkò ètò ìdìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ẹka tipinlẹ Eko ti fi ofin de gbogbo awọn oludije sipo oṣelu patapata lati ma rin irin ajo lọ soke okun.
APC jẹ ko di mimọ ni gbogbo asiko ipolongo, ati titi digba ti eto idibo yoo fi waye lọdun 2027 ni gbogbo wọn ko gbọdọ fi Naijiria silẹ.
Cornelius Ojelabi to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu naa lo sọrọ naa laipẹ yii lasiko to n ṣe ifilọlẹ igbimọ iṣakoso fun eto idibo PBAT/KOH nile ẹgbẹ naa to wa lagbegbe Ikeja.
Ojelabi rọ gbogbo awọn oludije naa lati fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ iṣakoso olupolongo naa, pẹlu afikun wi pe awọn igbimọ naa ni yoo maa ṣeto gbogbo ibaraẹnisọrọ pẹlu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lasiko ipolongo.
Nigba to n sọrọ, o sọ pe "Ko si oludije kankan ti a faaye gba lati rin irin ajo lọ soke okun titi digba ti eto idibo yoo fi waye."
Bakan naa lo tun paṣẹ fun ọmọ igbimọ iṣakoso olupolongo naa lati ṣiṣẹ laaarin ẹkun idibo ati ijọba ibilẹ wọn.
O ni wọn gbọdọ rii daju pe wọn mu awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ti yoo ṣatilẹyin fun wọn lasiko eto idibo to n bọ wọle sinu ẹgbẹ wọn.
Alaga naa ṣalaye pe eti rẹpẹtẹ ko nii waye nile ẹgbẹ oṣelu wọn, ati pe wọn ko fẹ ki ọpọ ọmọ ẹgbẹ sọ ile ẹgbẹ di ile.
O ni wọn yoo lo ile ẹgbẹ wọn fun oniruuru eto fun ojuṣe awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ ati awọn ti wọn yoo gbe iṣẹ ẹgbẹ le lọwọ.
"ile ẹgbẹ yoo wa fun awọn nnkan to ba ṣe pataki si ẹgbẹ, ati fun agbekalẹ ilana, to fi mọ itọnu," o sọ bẹẹ.



























