Ọ̀kan ṣoṣo tó kù nínú gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ ṣe nílé ayé rèé – Fatomilola

Agbaọjẹ oṣere Peter Fatomilola wọ wọ aṣọ funfun balau
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agbaọjẹ oṣere ori itage n ni, Peter Fatomilola, ti sọ pe okan ṣoṣo lo ku ninu gbogbo nnkan toun fẹ ṣe nile aye.

Baba Fatomilola sọrọ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin ori ayelujara Africanalist.

Ilumọọka oṣere naa sọ pe nnkan ẹyọkan yii ni oun le sọ pe Ọba Oke ko tii fontẹ lu.

Fatomilola ni ''emi ati iyawo mi agba ti dawọ le nnkan ọhun.

Mo fẹ lọ kọ ile kan nigba naa ni eyi ti mo si ti bẹrẹ, mo kọ ile naa de oke ti wọn n pe ni ''Lintel.''

Bi mo ṣe kọ ile naa de ipele ''lintel'' ni iyawo mi jade laye.''

Ọmọ ni Taiwo Hassan jẹ fun mi lagbo ere tiata

Baba Fatomilola fikun ọrọ rẹ wi pe oun ko gbọ pe gbajugbaja oṣere tiata to ṣalaisi Taiwo Hassan tawọn eeyan mọ si Ogogo n ṣe aisan rara.

Agbaọjẹ oṣere ori itage naa sọ pe nigba ti ọmọbinrin Ogogo, Kira ke gbajare lori ayelujara pe baba oun n ṣe aisan ni oun to mọ nipa ailera rẹ.

''Emi gẹgẹ bi ẹnikan, mi o le sọ pe mo gbọ pe Ogogo ni idojukọ to n la kọja.

Nigba ti ọmọ rẹ to sọrọ sita ni mo to mọ, ti nnkan ba n ṣe eeyan ti o ba n de mọ abẹ aṣọ to jẹ pe nigba tọwọ ba bọ sori tan ni gbogbo eeyan yoo to o gbọ, ewu wa nibẹ.

Ṣe ẹ mọ pe ẹni to mọ eyi ko mọ nnkan mii, ti mo ba gbọ pe nnkan bayii lo n ṣe e ti mi o ba mọ ogun rẹ, mo maa tọ awọn to mọ ọn lọ.

Ohun lawọn Yoruba fi maa n pa a lowe pe Ogidimọlaja Awo Ile Ife, Awo lo maa n gbe Awo ni igbọwọ.

Bi Awo ko ba gbe Awo ni igbọwọ, Awo a tẹ, Awo a ya,'' Fatomilola lo sọ bẹẹ.

A sa gbogbo ipá wa láti gba ẹ̀mí Ogogo là – Yayi

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinẹ Ogun, Sẹnetọ Olamilekan Adeola, ti inagijẹ rẹ n jẹ Yayi ti sọ pe oun ati idile oun duro ti oṣere tiata to di oloogbe, Taiwo 'Ogogo' Hassan lasiko to n ṣaisan ko to jade laye.

Yayi lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ lati ṣe idaro oloogbe naa lẹyin ti iroyin iku rẹ gbode.

Ninu atẹjade ọhun, ti oun ati iyawo rẹ, Temitope Adeola buwọlu, o ni iroyin iku Ogogo da omi tutu sọkan awọn, o si jẹ inbanujẹ nla fun wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, idilẹ rẹ duro ti Ogogo lasiko to dubulẹ aisan pẹlu ireti pe yoo pada gbadun ki aisan ọhun to ja si iku.

O juwe Ogogo gẹgẹ bii ibatan oun lati ilu Ilaro ati eeyan pataki ni gbogbo agbegbe iwọ oorun ipinlẹ Ogun.

Lẹyin naa lo tun ba iyawo Ogogo atawọn ọmọ rẹ kedun iku ọkọ ati baba wọn, to fi mọ gbogbo ọmọ bibi ilu Ilaro lapapọ.

O pari atẹjade naa pẹlu adura pe ki Eledua fori aiṣedede rẹ jin in ko si tẹ si afẹfẹ rere.

Ọjọ Aiku ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni Ogogo fi aye silẹ lẹyin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ finra.