Àwọn ọmọ Nàìjíríà 105 mí-ìn tún dé láti South Africa, wọ́n ní ọ̀pọ̀ ló ti kú s'ájò

Lọjọ Ẹti, ọjọ keji oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni ìṣí mi-in ti wọn jẹ ọmọ orilẹede Naijiria tun balẹ sorilẹede yii lati South Africa, nibi ti wọn ti n fin wọn lápe pe awọn ko fẹ ri ajeji kankan.
Marunlelọgọrun-un (105) ni awọn ìṣí tuntun to ṣẹṣẹ de yii, wọn gunlẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed, n'Ikeja tile-tile.
Tẹ o ba gbagbe, awọn ọmọ Naijiria kan naa pada si orilẹede yii lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan-an ọdun yii, 105 ni awọn naa niye.
Awọn to ṣẹṣẹ gunlẹ lọjọ Ẹti yii royin ohun oju wọn ri ni South Africa ti wọn rè fun BBC, bi ijọ Irapada "Redeemed Christain Chuch of God" (RCCG) ṣe kowo silẹ fun irinajo ipadawale wọn.
Lara $265,854 ti ijọ naa gbe kalẹ ni wọn fi ko awọn iṣi tuntun yii wale, lẹyin ti RCCG ti ṣagbatẹru bawọn kan ṣe wale ṣaaju.
"Wọn ti pa pupọ ninu wa, awọn South Africa gan-an mọ pe mọṣuari awọn ti kún"

Ọkan lara awọn ọmọ Naijria to ṣẹṣẹ de yii ni obinrin kan, Ijeoma Pauline Eze, ibudo okoowo Johannesburg lo gbe titi to si ti n ta ounjẹ fawọn eeyan nile itaja kan.
Ijeoma, ọmọ ipinlẹ Imo, ṣalaye fun BBC ni papakọ ofurufu Mutala l'Ekoo, pe ibi gbogbo lo gbona mọ awọn ajeji ni South Africa, paapaa awọn ọmọ Naijiria, latari bawọn oniluu naa ṣe n sọ pe kawọn ajeji maa lọ.
"Bawọn ọlọpaa ṣe n daamu wa lo jẹ ki n pada wale, gbogbo nnkan ni wọn ti bajẹ fun wa, aanu awọn eeyan wa maa n ṣe mi ni, nitori wọn n dunkooko mọ wọn gan-an. Boya o ṣẹ̀ tabi o ko ṣe nnkan kan, wọn maa wa ẹsun kan ka si ẹ lẹsẹ lati ni ọ lara.
"Ọpọlọpọ awọn eeyan wa lo ti ku, koda awọn South Africa gan-an n pariwo pe mọṣuari awọn ti kun."
Obinrin naa sọ pe ipadawale yii paapaa to lọpẹ, oun si gbagbọ pe Oluwa ti ko jẹ kawọn ku sajo, o ni ohun ti yoo fi aye awọn ṣe ni Naijiria ni.
"Ko kan wọn boya o jẹ ajeji to forukọ silẹ bii ọmọ South Africa, gbogbo wa ni wọn fẹ ka lọ"

John Emeka Onu tun ni ẹlomi-in lara awọn to ṣẹṣẹ de naa, oun royin fun BBC pe ọmọ South Africa loun labẹ ofin, amọ wọn ṣaa le oun dandan ni.
"1996 ni mo kọkọ lọ si South Africa, mo wale lati ṣegbeyawo ni 2014, iyawo mi si waa ba mi ni South Africa ni 2017, a ti bimọ mẹta sibẹ.
"Ọmọ South Africa ni mi, igbeyawo mi labẹ ofin gan ba ofin wọn mu, mo ni iwe idanimọ South African ati gbogbo iwe igbeluu to yẹ, amọ wọn ṣaa sọ pe dandan ka lọ ni.
"Idi niyẹn ti mo fi pada wale nigba ti RCCG ti pese owo irinna ọfẹ, afi ki n pada wale."
Onu to n ba awọn abanikọle ṣiṣẹ ni South Africa, sọ pe irọ lawọn eeyan naa n pe ajeji n gba iṣẹ awọn ṣe.
O ni irọ ni wọn n pa pe wọn n gba awọn lobinrin pẹlu, ete lati le gbogbo awọn lọ lasan ni.
Ẹ o ranti pe ọgbọnjọ oṣu Kẹfa ọdun yii ni South Africa kọkọ fun awọn ajeji lati filu awọn silẹ, ti ọpọ ilu bii Naijiria, Zimbabwe, Uganda, Ghana, Mozambique atawọn mi-in si ko awọn ọmọ ilu wọn wale.
Awọn ọmọ Naijria ti ku ninu rogbodiyan naa, bẹẹ ni awọn to de yii wale lẹyin ọjọ meji ti South Africa fun wọn da lati kuro.
Ọgbọnjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 ni ijọba ilu naa pe ni gbedeke.

























