Gbajúmọ̀ òṣèré jáde láyé lẹ́ni ogójì ọdún

Oríṣun àwòrán, Alex Ekubo/Facebook
Gbajugbaja oṣere tiata ọmọ Naijria kan, Alex Ekubo, ti jade laye lẹni ogoji ọdun (40).
Ojiji ni iroyin iku naa gbode nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kejila, oṣu Karun-un ọdun 2026.
Bi iroyin iku naa ṣe n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi, ti wọn ko fẹ tete gbagbọ pe arẹwa ọkunrin naa ti jade laye, ni awọn oṣere lede oyinbo, ede Yoruba ati ede Igbo bẹrẹ si I kẹdun iku naa loju opo wọn.
Eyi lo mu ọpọ eeyan gba pe loootọ ni Alex Ekubo, ọdọmọde elere tiata naa ti di ara ọrun.
Lara awọn oṣere to fidi iku naa mulẹ loju opo ayelujara wọn ni Funke Akindele, Bolanle Ninalowo ati Godwin Nnadiekwe.
Ki lo pa Alex Ekubo?
Bo tilẹ jẹ pe ko ti I sẹni to fidi iku pato to pa gbajumọ oṣere naa mulẹ, iroyin to gbode ju ni pe Jẹjẹrẹ inu Kindinrin lo mu Alex Ekubo lọ.
Bakan naa ni awọn ẹka iroyin kan ṣalaye pe aisan ranpẹ lo ṣe oloogbe naa ko too jade laye.
Ṣugbọn akọsilẹ fi han pe o ti n pẹ ọdun meji lọ ti Oloogbe Alex ti gbe ohunkojun jade loju opo ayelujara rẹ gbẹyin.
Eyi ni ọpọ si fi n sọ pe awon asiko ti ara rẹ ko ya ni oṣere naa ko raye lati gbe ohun tuntun si oju opo naa.
Aarin kan ninu ọdun 2025 to kọja si ni a gbọ pe aarẹ ti wọn lo ṣe Oloogbe Ekubo lagbara si i.
Ẹnikan ti ko darukọ rẹ lara awọn to sunmọ oṣere naa, ṣalaye pe ọjọ Aje ni wọn tun sare gbe Alex lọ sileewosan, lẹyin ti aarẹ naa le si i.
O ni afẹfẹ Oxygen ni oṣere naa fi n mi ko too dagbere faye lọjọ Iṣẹgun.
Ta a ni Alex Ekubo?

Oríṣun àwòrán, AlexEkubo/ Facebook
Alexx Ekubo (Alexx Ekubo-Okwaraeke), oṣere tiata ni wọn bi lọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 1986.
Portharcourt, nipinlẹ Rivers ni wọn ti bi I, amọ ọmọ ilu Arochukwu, nipinlẹ Abia ni.
Ẹkọ nipa imọ ofin ni Alex kọ ni Yunifasiti ilu Calabar, o si tun gba Diploma ninu imọ nipa iṣẹ iroyin nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Calabar kan naa.
Ere oniṣe kan ti wọn pe ni Weekend Getaway lo fi Oloogbe Alex han .
O ti gba ọpọ ami ẹyẹ titi to fi mọ oṣere to dangajia julọ nibi ka ṣe amugbalẹgbẹẹ, eyi waye ni 2013.



























