Wo bí hòmóònù ṣe ń mú àyípadà bá ìhùwàsí àwọn obìnrin ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀
Lọpọ igba ni ihuwasi awọn obinrin kii saba ye awọn eeyan paapaa awọn ọkunrin nitori bi awọn obinrin ṣe maa n huwa nigba mii.
Ọpọ awọn ọkunrin ni ko mọ pe homoonu ara obinrin lo maa n dari ihuwasi wọn lọpọ igba, koda awọn oibinrin mii gan ko mọ eyi.
Eyi lo jẹ ki a ṣe agbeyẹwo bi homoonu obinrin ṣe n ṣiṣẹ ati ipa ti wọn maa n ni lara.
Ọsẹ kan homoonu kan ni fun awọn obinrin.
Ọsọọsẹ ni homoonu obinrin maa n yipada, eyi lo fa a to jẹ pe o le ri ki obinrin to n yọ fẹfẹ ti inu rẹ n dun lọsẹ yii bẹrẹ si ni di gbọnkugbọnku ni ọsẹ mii lai si ohun kan pato kan to o ṣe fun.
Ọsẹ akọkọ ni igba ni ti obinrin ba n ṣe nnkan oṣu lọwọ, lasiko yii, niṣe ni homoonu maa n lọ silẹ, igba yii ni ẹyin to wa nile ọmọ obinrin ti atọ ọkunrin ko sọ dọmọ maa n walẹ bii ẹjẹ. Ọpọ obinrin kii ni agbara lasiko yii, yoo maa rẹ wọn wẹsiwẹsi, ti wọn sii saba fẹ ki ẹnikẹni sunmọ wọn. Lasiko ara kikan ni gbogbo igba.
Ọsẹ keji ni igba ti agbara wọn ba ti n bọ sipo pada, ẹjẹ ti pari asiko yii ni wọn yoo maa ṣe oniruuru ipalẹmọ fun ohun ti wọn ba fẹ ṣe lọjọ iwaju.
Ni ọsẹ kẹta ẹwẹ, agbara yẹn ti maa de, obinrin a maa n rẹwa yatọ. Irori rẹ a maa ga, wọn maa ni arogun ati arojinlẹ gidi lasiko yii. Ẹ jẹ ki n tun sọ aṣiri kan fun-un yin, igba yii ni ọpọ obinrin maa n fẹran lati ni ibaṣepọ, ti ara rẹ yoo si maa dide daadaa.
Ọsẹ to kẹyin ni eyi ti homoonu tun ti n lọ silẹ pada, ko ni fi bẹẹ si agbara mọ bii ti ọsẹ meji sẹyin, igba yii ni ara kikan yoo maa bẹrẹ diẹdiẹ, to jẹ pe gbogbo nnkan ti ẹ ba n ṣe yoo maa bọ sodi fun un. Asiko yii ni homoonu oestrogen n bẹrẹ si ni lọ silẹ pada.
Kii ṣe pe obinrin to n fẹyin si ẹ lọsẹ to kọja ṣadede bẹrẹ si ni kanra mọ ọ lọsẹ yii, homoonu rẹ ni ayipada n ba, bi Eledua si ṣe da a niyẹn, ẹsọ pẹlẹ dọwọ rẹ o lati mọ bo o ṣe maa ba a gbe o






