Lẹ́yìn tí ajínigbé gba N50m owó ìtúsílẹ̀, wọn pa àgbà olóṣèlú lẹ́gbẹ́ ADC, fi òkú rẹ̀ ránṣẹ́

Abas Anas Adamu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ajinigbe ti wọn ji aṣofin tẹlẹ ri ni ile igbimọ aṣojuṣofin, to tun jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Abba Anas Adamu gbe, ti fi oku rẹ ranṣẹ lẹyin tawọn ẹbi rẹ san owo itusilẹ.

Nigba ti Anas ati oluṣelu mii lati ipinlẹ Jigawa, Ali Tukr Gantsa n lọ sibi apero ẹgbẹ oṣelu ADC ni ilu Abuja ni wọn sọwọ awọn ajinigbe naa.

Iroyin ni ọgọrun-un miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ, ki wọn to din owo naa ku si aadọta miliọnu naira.

Ẹbi Anas sọ pe lẹyin ti awọn san naa ni wọn tu Gantsa silẹ, to si jẹ pe oku Anas ni wọn fi ranṣẹ sawọn.

Igbesẹ yii ti sọ ẹgbẹ oṣelu ADC tẹka ipinlẹ Jigawa sinu ọfọ, ti ọpọ eeyan si n juwe oloṣelu to doloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ni iwa irẹlẹ, to ni ifarajin si sise iṣẹ sin ọmọniyan nigba aye rẹ.

Anas, ẹni to ni aisan ikọ ife, ati aisan ẹjẹ ruru, ni ko mu oogun rẹ dani ni gbogbo igba to wa pẹlu awọn ajinigbe naa

Ẹbi naa sọ pe ipinlẹ Kano ni Anas ati Gantsa ti n ṣe irinajo lọ si ilu Abuja ki wọn to ji wọn gbe lasiko ti wọn n lọ sibi ipade oṣelu kan.

"Ni ọjọru to kọja ni awọn ajinigbe ji wọn gbe nigba ti wọn n lọ si Abuja lati ipinlẹ Kano. Inu igbo kan to wa ni agbegbe Jere ni awọn ajinigbe naa gbe wọn si ti wọn si kọkọ beere fun igba miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ ki wọn to dinku aadọta miliọnu naira.

Iwadii fi han pe Anas, ẹni to ni aisan ikọ ife, ati aisan ẹjẹ ruru, ni ko mu oogun rẹ dani ni gbogbo igba to wa pẹlu awọn ajinigbe naa.

Wọn ni awọn ipenija to koju nigba to wa ni ahamọ awọn ajinigbe jẹ ohun to ṣakoba fun ilera rẹ to si jẹ pe gbogbo igbiyanju Gantsa lati ṣe iranlọwo fun-un ko ma ba a ku si ahamọ awọn ajinigbe naa ṣugbọn ti gbogbo igbiyanju rẹ ja sip abo.

Ẹbi Anas naa sọ pe awọn ajinigbe naa ko tete sọ fun awọn pe o ti ku, to si jẹ pe lẹyin igba diẹ ni wọn to sọ fun awọn.

Wọn ti gbe oku Anas lọ si ipinlẹ Kano fun eto isinku to peye ni ilana ẹsin Islam

Eeyan kan to sunmọ ẹbi Anas sọ pe ọmọ Anas ati ẹnikan ni wọn gbe owo itusilẹ lọ fawọn ajinigbe naa, to si jẹ pe lẹyin ti wọn gba owo tan ni wọn tu Gantsa silẹ, ti wọn si fi oku Anas han ọmọ rẹ.

Iroyin ni wọn ti gbe oku Anas lọ si ipinlẹ Kano fun eto isinku to peye ni ilana ẹsin Islam.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ẹgbẹ oṣelu ADC tẹka ipinlẹ Jigawa ko i tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii.

Ipenija aabo to n lọ ni Naijiria tun n peleke bi o tilẹ jẹ pe aarẹ Bola Tinubu ti kede igbesẹ pajawiri ni ẹka naa.

Ọpọ idile lo ti padanu ẹbi wọn sawọn ajinigbe to n gbe eeyan lati fi pa owo, ti ọpọ idile si ti ta dukia lati tu owo itusilẹ tawọn ajinigbe ba n beere fun jọ, to si jẹ pe awọn mii maa n padanu owo ati eeyan wọn sọwọ awọn ajinigbe naa.