Ọwọ́ tẹ afurasí agbébọn márùn-ún lẹ́yìn ìkọlù silé iṣẹ́ ọmọ ogun ní Igbeti ní Oyo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Afurasi ti ko din ni maru-un lọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun ati awọn ẹṣọ alaabo bii ọlọpaa ti tẹ bayii, lẹyin ti awọn janduku agbebọn lọ ṣe ikọlu si ibudo awọn ọmọ ologun ilẹ Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Oyo.
Ibudo ileeṣẹ ologun ti wọn pe ni 'Operation Burst', eyi to wa ni agbegbe Igbeti, ijọba ibilẹ Olorunsogo ni awọn janduku naa lọ ṣe ikọlu si.
Awọn afurasi marun-un naa ni wọn mu lasiko ti wọn ri wọn ninu aṣọ ọmọ ologun ninu igbo Ọba to wa ni agbegbe ọhun.
Nigba to n ṣe abẹwo sibi iṣẹlẹ naa, igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Bayo Lawal ṣalaye pe ọmọ ologun ọgọfa lo ti wa ninu igbo lati lepa awọn to ṣe ikọlu naa lọ.
Lawal sẹlẹri fun awọn olugbe agbegbe ti ikọlu ọhun ti waye wi pe ki wọn fọkan balẹ, ki wọn ba si ṣe foya, nitori pe eto aabọ ni agbegbe naa yoo tubọ muna doko si i.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Awọn janduku agbebọn ti ko tii sẹni to mọ wọn titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ni wọn ṣe kọlu nla si ibudo awọn ọmọ ogun, ẹka ti 'Operation Burst' to wa ninu igbo Igbeti to lọ si siluu Igboho, ijọba ibilẹ Orelope, ipinlẹ Oyo.
Nnkan bi agogo marun-un aabọ si mẹfa idaji owurọ ọjọ Aiku to kọja, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni ikọlu naa waye.
Gẹgẹ bi alaye ti awọn ọmọ ikọ ologun Operation Burst naa ṣe, wọn ni awọn agbebọn naa de si ibudo wọn laarọ kutukutu, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn si awọn ọmọ ogun wọn.
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn janduku naa pọ, debi wi pe wọn ko le sọ iye ti wọn jẹ, ti gbogbo wọn si ko awọn nnkan ija oloro dani.
Siwaju sii ni wọn loo ṣe awọn laanu wi pe nigba ti awọn ẹṣọ alaabo miran ti awọn sare ranṣẹ pajawiri si yoo fi de bẹ, awọn janduku agbebọn naa ti juba ehoro, wọn ti salọ.
Ileeṣẹ ologun fi kun ọrọ rẹ pe erongba awọn janduku agbebọn naa ni lati gba iṣakoso ibudo ọhun, ki wọn si gba gbogbo irinṣẹ wọn lọ.
Wọn fi kun ọrọ wọn pe pẹlu bi awọn agbebọn naa ṣe dana sun apakan ibudo wọn, ati ọkọ ti wọn fi n ṣiṣẹ, sibẹ, ko sẹnikẹni ninu wọn to ba ikọlu naa lọ ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Níbo ni ọkọ̀ òfurufú ààbò ìpínlẹ̀ Oyo wa?
Ibeere ti ọpọ olugbe ipinlẹ Oyo n beere lẹyin iṣẹlẹ ikọlu yii waye ni pe kini pato iṣẹ ọkọ ofurufu ti yoo ran awọn ẹṣọ alaabo lọwọ wa, lakooko ti ikọlu naa waye.
Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Bayo Lawal ni ọkọ ofurufu ti ijọba ipinlẹ Oyo ṣẹṣẹ ra lati ran awọn ẹsọ alaabo lọwọ n ṣe iṣẹ ti wọn ra a fun un.
Lawal ni ṣaaju ikọlu yii ni ọkọ ofurufu naa ti n lọ yika awọn inu igbo agbegbe naa.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọkọ ofurufu naa ko fi gbogbo igba wa ninu afẹfẹ, ṣugbọn yoo wa ni arọwọto nigbakugba ti awọn oṣiṣẹ ologun ba ti nilo rẹ.
Bẹẹ lo sẹlẹri lati fi oju gbogbo awọn ti ọwọ ba tẹ lori ikọlu naa jofin.



























