Ìjọba Oyo kìlọ̀ lórí gbèdéke ọjọ́ méje tí NURTW fún Makinde pé kó fòpin sí PMS káwọn lè gba gáréèjì

Alaga NURTW Alhaji Abideen Olajide Ejiogbe wọ aṣọ alawọ ewe, Gomina Seyi Makinde wọ aṣọ buba olomi buluu pẹlu fila
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Oyo ti fesi si gbedeke ọlọjọ meje ti ẹgbẹ awakọ NURTW ẹka ti ipinlẹ Oyo fun Gomina Seyi Makinde lati fopin si ajọ PMS to n ṣakoso ibudokọ nipinlẹ naa kawọn le gba gareeji pada.

Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, sọ fun BBC News Yoruba wi pe ijọba Makinde ṣetan lati tẹle ofin.

Ọmọba Oyelade ni ijọba ipinlẹ Oyo ko lodi si igbesẹ ti ẹgbẹ NURTW ba fẹ gbe, niwọn igba ti igbesẹ naa ba ti ba ofin mu.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ijọba ipinlẹ Oyo ko lodi sofin ri, ko si ni lodi sofin lasiko yii bakan naa.

Lori gbedeke ti NURTW fun Gomina Makinde lati ko ajọ PMS nilẹ kawọn le gba gareeji pada, Kọmiṣọna fun eto iroyin sọ pe ''ijọba maa kawọ gbera, a o si fọwọ lẹran ni.

Ki wọn lọ wadii rẹ wo bo ba jẹ pe NURTW le fọwọ lalẹ ki wọn si da gbedeke ọjọ fun ijọba.

To ba tọna bẹẹ, ofin lo maa yanju rẹ, ti ko ba si tọna naa, ofin lo maa ṣe atọna rẹ.

Ṣugbọn o ṣe pataki ki alaafia jọba ni ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi a ṣe n ba a bọ.

Ijọba ipinlẹ Oyo yoo lodi si nnkan ti ẹnikẹni ba ṣe lati da ilu ru.''

Oti to gẹẹ! A ṣetan lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun - NURTW Oyo

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ẹgbẹ onimọto NURTW ẹka ti ipinlẹ Oyo fun Gomina Seyi Makinde ni gbedeke ọjọ meje lati fopin si ajọ PMS to n ṣakoso gareeji nipinlẹ Oyo, kawọn le pada sawọn gareeji.

Ẹgbẹ naa fun ijọba di ọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla lati ṣe bẹẹ.

Ẹgbẹ NURTW fidii ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Abideen Olajide tawọn eeyan mọ si Ejiogbe ati akọwe, Kọmureedi Lekan Alesinloye jọ buwọlu.

Wọn sọ ninu atẹjade naa wi pe ijọba Makinde ko bọwọ fun ofin tori o kọ lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun eyi ti wọn lo dawọn lare.

Awọn oloye ẹgbẹ naa sọ pe lọpọ igba lawọn ti rawọ ẹbẹ si ijọba lati da NURTW pada tori ẹgbẹ ti idasilẹ rẹ wa ni ibamu pẹlu iwe ofin Naijiria ni, ṣugbọn eti ikun ni ijọba kọ si ẹbẹ awọn.

Ẹgbẹ NURTW ni ijọba si n tẹsiwaju lati maa ṣakoso ajọ PMS, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ ti dawọn lare lori ọrọ naa.

Ẹgbẹ NURTW sọ pe awọn ti sọ fun ijọba apapọ, ileeṣẹ ọmogun Naijiria, ajọ DSS, Kọmiṣọna ọlọpaa ati ẹgbẹ oṣiṣẹ pe awọn ṣetan lati tẹle idajọ ileẹjọ.

Awọn oloye NURTW sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita wi pe ''a ṣetan lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, o ti to gẹẹ bayii.

Ijọba Makinde ti fiya jẹ wa, ko si ọkankan ninu idajọ ti a gba lati ẹyin wa ti ijọba ipinlẹ Oyo tẹle.''

Ẹgbẹ naa ni ọna aitọ ni Makinde fi fofin de ẹgbẹ NURTW, wọn ni eyi si ti fa ebi ati iku ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto naa.

Alhaji Jelili Oyere nikan si loun mọ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo - MC Oluomo

Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ awakọ NURTW ni Naijiria, Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya (MC Oluomo), ti kilọ fun alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo wi pe ko gbọdọ da wahala silẹ.

Alhaji Akinsanya ni oun ti gbiyanju lati kan si Ejiogbe ṣugbọn oun ko tii lanfaani lati ba a sọrọ.

Aarẹ ẹgbẹ NURTW sọ pe ijọba ti da Ejoigbe duro, ko si gbọdọ lo orukọ ẹgbẹ NURTW lati da omi alaafia ru nipinlẹ Oyo.

MC Oluomo sọ pe Alhaji Jelili Oyere nikan si loun mọ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo.

Alhaji Akinsanya ni alaafia ni ẹgbẹ NURTW maa n le pa nibi gbogbo.