Ìdí tí JAMB fi sún àkókò tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ dé gbàgede ìdánwò CBT síwájú

Awọn akẹkọo to n ṣe idanwo JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n ri si idanwo igbaniwọle si fasiti ni Naijiria, JAMB, ti ṣe atunsẹ si asiko ti awọn akẹkọọ yoo de gbagede idanwo JAMB ti yoo waye lọdun 2027.

Labẹ atunṣe yii, aago meje abọ aarọ ni akekọọ gbọdọ de si gbagede CBT wọn dipo aago mẹfa abọ aarọ to yẹ ki wọn de ibẹ ṣaaju.

Wọn ni idanwo yoo bẹrẹ ni aago mẹjọ abọ aarọ si aago mẹwaa abọ aarọ.

Atunṣe tuntun yii ni wọn kede ninu atẹjade kan ti wọn fi lede niluu Abuja.

Ki ni eredi atunṣe yii?

Gẹgẹ bii JAMB ṣe sọ, ẹredi atunṣe naa ko ṣẹyin ewu to le de ba awọn akẹkọọ ti wọn ba rinrinajo lọ kọ idanwo naa ni afẹmọju.

Igbesẹ yii ni JAMB fẹnuko le lori lẹyin ijiroro kan ti wọn ṣe niluu Ikot Ekpene, ipinlẹ Akwa Ibom laarin ọjọ kẹfa si ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2026 yii.

Wọn ni igbeṣe naa ṣe pataki lẹyin ti araalu bẹrẹ si n kọminu lori ewu to wa ninu ki awọn akẹkọọ maa kuro nile wọn lati rinrinajo afẹmọju nitori idanwo ọhun.

JAMB ni sisun akoko to yẹ ki wọn de gbadege CBT naa siwaju yoo ṣe ọpọ akẹkọọ lanfani pupọ.

Bo tilẹ jẹ pe idanwo naa ṣi di ọdun to n bọ, JAMB sọ pe awọn ti bẹrẹ igbaradi ki gbogbo nnkan le lọ ni irọwọrọsẹ.

Iye igba ti ewu ti wu awọn akẹkọọ to n lọ ṣe idanwo JAMB

Yatọ si kikuro nile ni afẹmọju, irinajo lọ si agbegbe mii lati lọ kọ idanwo JAMB lewu pupọ fun awọn akẹkọọ ti pupọ wọn ko tii to ọmọ ọdun mejidinlogun.

Lara awọn ewu naa ni ijamba ọkọ, ijinigbe, idunkokomọni awọn ọlọpaa loju ọna to le mu ki wọn pẹ de gbagede idanwo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Fun apẹrẹ, lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 yii, awọn agbebọn kọlu ọkọ akero Benue Links to ko awọn ero, ninu eyii ti awọn to fẹ lọ ṣe idanwo JAMB wa ninu rẹ loju ọna Otukpo.

Awọn agbebọn naa da ọkọ ọhun duro wọn gba gbogbo ẹru ọwọ awọn ero ọkọ naa ki wọn to dari wọn sinu igbo.

Ileeṣẹ iroyin Premium Times jabọ pe eeyan mẹrinla ni wọn ji gbe ninu ọkọ ọhun.

Lọdun 2024, akẹkọbinrin kan to fẹ lọ kọ idanwo JAMB ko sọwọ awọn adigunlae 'once chance' niluu Eko.

A gbọ pe ṣe ni wọn ti akẹkọọ naa jade ninu ọkọ to ṣi n rin loju popo, amọ akẹkọbinrin ọhun rọju de gbagede idanwo rẹ ki aago mẹfa abọ aarọ to lu.