Bàbá Mohbad fẹ́ jogún ọmọ rẹ̀; mi ò lè fun ní ohun tó ń fẹ́ – Wumi Aloba

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Omowunmi Aloba, to jẹ iyawo gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ileroluwa 'Mohbad' Aloba, ti sọ pe baba ọkọ oun n fẹ jogun dukia ọmọ rẹ.

Wumi lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, kekere jojolo ni oun ati Mohbad ti mọ ara wọn, ifẹ wọn si jẹ ojulowo.

Amọ ija oun ati baba Mohbad bẹrẹ lẹyin ti oun bi ọmọ wọn Liam tan.

O ni ọrọ inu ile lasan ni ọrọ ọhun amọ lẹyinorẹyin, o pada di ohun to burẹkẹ ti ko si ni ṣe e pari mọ.

Wumi sọ pe ija naa ko bẹrẹ lẹyin iku Mohbad amọ o ti bẹrẹ ki ololufẹ oun ọhun to jade laye.

Opo oloogbe naa ni baba ọkọ oun n gbiyanju lati yan oun jẹ latari pe oun jẹ ọmọde amọ ti ko mọ pe ọwọ obinrin gan ni agbara wa.

O ni ọrọ naa ti le to bẹẹ ti oun ko gbagbọ pe wọn yoo le yanju rẹ mọ.

Baba Mohbad n fẹ ki esi DNA fi han pe Mohad kọ lo ni ọmọ oun

Nigba to n sọrọ lori gbas-gbos laarin oun ati baba Mohbad, Wumi sọ pe "Mi o le fun ni ohun to n fẹ.

"Ọrọ yii ti de ibi ti mi o gbabọ pe a le yanju rẹ mọ, nitori mi o ni le fun ni ohun to n fẹ.

"Ohun to n fẹ ko le ṣeeṣe lailai. Ohun to n fẹ ni pe ki ayẹwo DNA ọmọ wa fi han pe kii ṣe Mohbad lo ni ọmọ.

"Erongba rẹ ni lati jogun awọn owo to n wọle lati ori orin ọkọ mi."

Wumi sọ pe gẹgẹ bii olori ile, ti baba Mohbad ba tilẹ maa jogun ọmọ rẹ, o yẹ ki baba Mohbad ṣe e ni ilana to yẹ gẹgẹ bii aṣa Yoruba.

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko sọ pe oun ko ṣe ayẹwo DNA ti baba Mohbad n bere fun, o ṣeni laanu pe kaka ki ọkunrin naa ba oun sọrọ nipa rẹ, niṣe lo yan lati lọ maa sọrọ lori ayelujara, eyii ti ko bojumu.

Wumi ni baba Mohbad ko ba oun sọrọ nipa DNA yatọ si ọrọ to n sọ lori ayelujara, amọ ogun oloogbe naa gan lo jẹ ọkunrin ọhun logun.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni Mohbad jade laye.