Ààrùn Ebola tún gbòde, gbẹ̀mí èèyàn 65

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si ajakalẹ aarun ni ilẹ Africa ti kede pe wọn tun ti ṣawari ajakalẹ Ebola ni ilu Ituri, ẹkun ila oorun ni orilẹ ede Democratic Republic of Congo, DRC.
Ajọ Centres for Diseases Control and Prevention ni Africa, CDC sọ pe eeyan 246 ni wọn ti ṣawari rẹ pe o lugbadi aarun naa, ti wọn si ṣe akọọlẹ iku eeyan marundinlaadọrin (65) ni agbegbe Mongwalu ati Rwanpara.
Ninu atẹjade ti CDC fi lede lọjọ Ẹti ni wọn ti sọ pe awọn ti fẹ pe ipade pẹlu DR Congo, Uganda, South Sudan atawọn ajọ agbaye mii lati jiroro lori ọna ti wọn fi maa ṣe amojuto bi aisan naa ko ṣe ni tan kalẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Ni ọdun 1976 ni wọn kọkọ ṣawari Ebola ni DR Congo, ti igbagbọ si wa pe lara ẹyẹ adan ni wọn ti n tan.
Igba kẹtadinlogun ree ti aisan naa n jade ni orilẹ ede naa, to si maa n tan lati ara omi to si maa n fa ki eeyan maa pọ ẹjẹ ati ba awọn ẹya ara jẹ.
Lara awọn eeyan marundinlaaadọrin ti wọn padanu ẹmi wọn naa, wọn ti fidi rẹ mulẹ ni ile ayẹwo pe ebola lo pa wọn.
Arun wo gan ni Ebola ati pe bawo lo ṣe n tan kalẹ?
Gẹgẹ bii ohun ti ajọ WHO sọ,ara adan ni arun Ebola ti wa, arun naa si buru jọjọ latari bo ṣe maa n gbẹmi eeyan laipẹ ọjọ.
Ara ẹranko to ba ti ni arun naa bii inaki, adan ati ẹgbin lo ti maa n ran eeyan.
Ara adan ti wọn n pe 'fruit bat' ni arun naa ti kọkọ wọ abule kan lẹyin ti wọn fọwọ kan ẹjẹ, omi ati ara ẹran to ni arun naa ṣaaju.
Oriṣiriṣi ẹda Ebola meji lo wa, akọkọ ni Sudan ti ekeji rẹ si n jẹ Zaire.
Arun naa maa n tan lati ara ẹnikan si omiran lati ara igbọnsẹ, ẹje, eebi ati oru aru ara eni to ba ni.
Ti eeyan ba fi ara kan oku ẹni ti Ebola gbẹmi rẹ, o ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹẹ ko arun ọhun.
Awọn apẹrẹ arun Ebola
Ebola maa n mu ki ọna ọfun dun eeyan, o tun maa n ṣadede fun eeyan ni iba lairo tẹlẹ.
Ti arun naa ba ti wọ ara eeyan daadaa, irufẹ ẹni bẹe yoo maa bi, yoo si maa ṣe igbọnsẹ gburu, nigba mii ẹni to ba ni Ebola yoo maa yọ ẹjẹ jade lati idi.
Laarin ọjọ meji pere si ọsẹ mẹta ni arun Ebola fi maa n dagba lara eeyan, o si le mu awọn arun mii bii iba dani.
Omi ara awọn to ba ni arun naa ma n tete gbẹ, eyii to maa n yọri si iku wọn.
Ọdun 2014 ni arun naa milẹ titi julọ lagbaye ninu eyii ti ẹmi ẹgbẹrun mọkanla eeyan lọ si.
Bi o ṣe le dena arun Ebola
Awọn ọna wọnyii ni o fi le daabo bo ara rẹ lọwọ Ebola:
- Maa fọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba
- Lọra ni fifi ọwọ kan ẹni to ba ti ko arun naa tẹlẹ
- Maṣe fi ọwọ tabi ara kan oku, paapaa ẹni ti o ko mọ irufẹ iku to gbẹmi rẹ
- Ṣọra fun pipa, fifi ọwọ kan tabi jijẹ ẹran igbẹ
- Abẹrẹ ajẹsara wa nigba kan ri fun ẹda Zaire arun naa amọ ko tii si abẹrẹ ajẹsara kankan fun ẹda Sudan.
- Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe ẹni ti wọn ba tete ṣawari arun naa lara rẹ to si gba itọju to peye le ru u la.


























