Ọkọ ojú omi tí wọ́n ti ṣàwárí ààrùn hantavirus balẹ̀ sí Spain, àyẹ̀wò bẹ̀rẹ̀ fáwọn èrò

Awọn eeyan ti wọn wọ aṣọ to bo gbogbo ara wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkọ oju omi igbafẹ eyi tawọn eeyan lugbadi aarun hantavirus ti wa ni orilẹ ede Spain bayii nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ko awọn eeyan inu rẹ silẹ ni agbegbe Tenerife lẹbaa Canary Islands.

Minisita feto ilera Spain, Mónica Gracía sọ pe bí wọn ṣe n ko awọn eeyan bọlẹ ninu ọkọ naa lo n lọ ni mẹsọmẹsọ amọ gbogbo awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi MS Hondius ni ko ṣoju pe ohunkohun n ṣe wọn.

Pẹlu ẹrọ ayaworan, niṣe ni a ria won eeyan naa ti wọn n kiri ninu ọkọ oju omi naa, wọn wọ ibomu bi wọn ṣe n ko awọn kan kuro ninu ọkọ.

Niṣe ni wọn pin awọn ero ọkọ ọhun si ọtọọtọ pẹlu orilẹ ede ti wọn ti maa ja wọn, ti wọn si maa fi ọkọ ayọkẹlẹ ko wọn lọ si papakọ ofurufu ti wọn ti maa wwọkọ ofurufu pada si orilẹ ede wọn.

Awọn ọmọ Spain mẹrinla to wa ninu ọkọ naa lo kọkọ maa bọlẹ, ko to kan awọn ti wọn n pada si Netherlands, Denmark, Greek ati Germany.

Lẹyin naa lo maa kan awọn ti wọn n pada si UK ati US, ti igbagbọ si wa pe onikaluku ti maa pada si orilẹ ede wọn to ba fi maa di ọjọ Aje.

Ni idaji ọjọ Aiku ni ọkọ oju omi Hondius balẹ si ebute Granadilla, leyin osu kan ti ero kan ku sinu ọkọ naa.

Niṣe ni ọpọ awọn oṣiṣẹ ilera ti wa ni sẹpẹ lati ṣe ayẹwo awọn ero naa lati ṣawari aarun hantavirus lara wọn.

Bakan naa ni awọn akọṣẹmọṣẹ ti wa ni ile iwosan Candelaria ni Tenerife lati ṣamojuto ẹnikẹni ti wọn ba fi le ṣawari pe o n ṣaisan.

Wọn tip ese yarak an eyi ti wọn ti ko ohun. Elo itọju si bẹ lati fi mojuto ẹnikẹni ti wọn ba ri pe o n ṣojojo.

Adari ile iwosan naa, Dokita Mar Martin sọ fun BBC pe awọn wa ni sẹpẹ ati pe ọpọ awọn ohun elo ni awọn ti pese fawọn oṣiṣẹ to maa ma mojuto awọn to ba rẹ.

O ni bi o tilẹ pe awọn ko ri aarun hantavirus ri, awọn mọ pe Kokoro aifojuri lo n faa to si jẹ nnkan ti awọn n tọju ni gbogbo igba niyẹn.

Adari ajọ iṣọkan agbaye, Tedros Adhanom Ghebreyesus to wa ni Tenerife lati ṣe amojuto bi wọn ṣe n ko awọn eeyan naa kuro ninu ọkọ sọ pe eto naa n lọ deedee, to s ikan saara sawọn oṣiṣẹ bi wọn ṣe tete n ṣe amojuto rẹ lati ri pe ko tan ju bo ṣe yẹ lọ.