Èèyàn mẹ́ta tí ẹ̀yà ara pè níjà bọ́ sọ́wọ́ NDLEA fún ẹ̀sùn òògùn olóró

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ninu igbiyanju wọn lati wawọ iwa gbigbe oogun oloro bolẹ lorilẹede yii, ajọ National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti nawọ gan eeyan mẹta ti ẹya ara pe nija fun ẹsun kan naa.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni NDLEA fi atẹjade ati aworan awọn afurasi naa lede.
Femi Babafemi ti i ṣe Adari ikede ni NDLEA, ṣalaye ninu atẹjade naa pe baba agba ẹni ọgọta ọdun (60), torukọ rẹ n jẹ Romanus Nwabara, wa lara awọn akanda ẹda ti ọwọ ba fun ẹsun naa.
Awọn ilu ọtọọtọ bii Kwara ati Anambra lo ni ọwọ ti ba awọn akanda ẹda naa lẹyin iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti NDLEA ṣe.
Alaye nipa awọn tọwọ ba yii
Gẹgẹ bi Babafemi ṣe kede, inu igbo kan ti wọn n pe ni Akpaka, niluu Onitsha, ipinlẹ Anambra ni NDLEA dọdẹ baba agbalagba torukọ rẹ n Romanus Nwabara lọ.
Wọn mu afurasi naa nibẹ pẹlu ẹgboogi oloro skunk ti iwọn rẹ jẹ aadọta le ni igba (250 grams).
Inu awọn ọra pelebẹ lo ni wọn di oogun naa si fun tita.
Afurasi keji ti NDLEA kede rẹ ni Amos Kenneth, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) tọwọ ba lagbegbe Ogbunike, nipinlẹ Anambra kan naa.
Ẹya ara pe oun naa nija, amọ wọn ba Tramadol ti iwọn rẹ to 160.3 grams lọwọ rẹ bi NDLEA ṣe sọ.
Ajọ naa sọ pe awọn tun ba oogun mi-in ti a mọ si Diazepam lọwọ rẹ, wọn ni koro ọgọrin (80 pills) lo wa lakata Amos to fi n ṣowo.
Wọn fi kun un pe oogun oloro kan naa ti I ṣe Exol-5, ti iwọn rẹ jẹ 38.23 grams tun wa lọwọ afurasi yii, pẹlu skunk ti giraamu rẹ jẹ 176.93.
Ni Kwara ni ọwọ ti tẹ afurasi kẹta ti ẹya ara pe nija
Awọn oṣiṣẹ NDLEA to n wọde loju ọna Bode Saadu ni wọn da ọkọ akero kan duro.
Ninu rẹ ni wọn ti ri egboogi skunk ti iwọn rẹ jẹ 6.3.
Ajọ yii ṣalaye pe inu apo ile ẹkọ kan ni egbogi ọhun wa.
Ero ọkọ naa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Usman Salisu, ti ẹya ara pe nija ni wọn lo ni in.
Yatọ si awọn akanda eeyan ti ọwọ NDLEA ba yii, ajọ naa sọ ọ di mimọ pe awọn tun koju awọn to n ṣowo oogun oloro ni Lekki, Ijora Badia nipinlẹ Eko, ni Nasarawa, Kogi atawọn ilu mi-in.
Alaga ajọ naa, Mohamed Buba Marwa, gboriyin fun awọn oṣiṣẹ rẹ, fun bi wọn ṣe n gbogun ti awọn to yan iṣẹ to lodi sofin ilẹ yii laayo.


























