EFCC kéde wíwá Sadiya Farouq, mínísítà tẹ́lẹ̀ fún ètò ìbojú-àánú wo aráàlú

Sadiya Umar Farouq, o n wo ẹgbẹ. O we gele alawọ aro, o lo igo sojuu rẹ, o si lo iborun si ọrun, o lo yẹti ati ẹgba ọrun pẹlu.

Oríṣun àwòrán, @Sadiya Umar Farouq

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), to n ri si ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku ti kede pe oun n wa Sadiya Farouq, minisita tẹlẹ fu eto iboju-aanu wo araalu.

Awọn ẹsun bii kiko owo ilu si apo ara ẹni, aṣilo ipo ati igbimọ pọ huwa ọdaran ni EFCC kede pe oun n wa Sadiya Farouq fun.

Ọjọ Satide, ọjọ kẹsan-an oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni EFCC fi ikede naa sita loju opo ayelujara wọn.

Pẹlu aworan minisita tẹlẹ naa ti EFCC fi sita ni wọn kede pe:

"A fi asiko yii kede fun araalu, pe a n wa Sadiya Umar Farouq, ti aworan rẹ wa loke yii fun awọn ẹsun bii iwa ọdaran, aṣilo ipo ati dida owo ilu si apo ara ẹni."

Bi ẹnikẹni ba ni ohun to le ran ajọ naa lọwọ lori ẹsun yii lati sọ, EFCC ni ki wọn kan si ọfiisi awọn to wa ni Ibadan, Uyo, Sokoto, Maiduguri, Benin, Makurdi, Kaduna, Ilorin, Enugu, Kano, Eko, Gombe, Port Harcourt tabi Abuja.

Wọn fi kun un pe wọn le pe ẹrọ ibanisọrọ yii pẹlu: 08093322644.

Tabi ki wọn kan si ajọ yii pẹlu lẹta ori afẹfẹ ti a mọ si email: info@efcc.gov.ng.

Wọn si le kan si agọ ọlọpaa to ba sunmọ wọn julọ pẹlu ni EFCC sọ.

Sadiya Farouq ati Bashir Alkali ni kootu fẹsun kan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oloogbe aarẹ Muhammadu Buhari lo yan Sadiya Umar Farouq sipo minisita to n ri si oju-aanu ọmọniyan ni 2019.

O di ipo naa mu titi di 2023.

Laaarin awon asiko naa ni awon ẹsun ajẹbanu kan ti dide si Sadiya, ṣugbọn ti obinrin naa sẹ pe oun ko kowo ilu sapo ara oun.

Eyi ti wọn fi kede rẹ bii ẹni ti EFCC n wa yii jẹyọ lẹyin ti kootu paṣẹ pe ki wọn lọ fi ofin gbe e pẹlu ọga ẹka ileeṣẹ rẹ, Bashir Alkali.

Adajọ Jude Onwuegbuzie, ti ile ẹjọ giga ilu Abuja, paṣẹ naa lẹyin ti Sadiya ko yọju fun igbẹjọ lori ẹsun jibiti ti iye rẹ to $1.3 million ati N746.6 million ti wọn fi kan oun ati Bashir.

Ẹsun ti EFCC fi kan Sadiya ati Bashir jẹ mọkanlelogun (21).

Lara ẹsun naa ni yiyẹ adehun, fifi jibiti gbe agbaṣe iṣẹ jade, aṣilo ipo ati kiko owo ilu gba ibomi-in.

Gẹgẹ bi EFCC ṣe fẹsun kan wọn, wọn ko owo Naijiria ti iye rẹ jẹ $1,300,000 ati N746,574,303 gba ọna aitọ.

Wọn ni wọn ko $1.3 million to yẹ ki ileeṣẹ kan da pada si minisiri naa sapo ara wọn.

Agbẹjọrọ fun EFCC ṣalaye pe oṣu Kejila ọdun 2025 ni igbẹjọ yii bẹrẹ, ṣugbọn awon olujẹjọ mejeeji ko yọju ri

Ta a ni Sadiya Umar Farouq?

Sadiya Umar Farouq.

Oríṣun àwòrán, @Sadiya Umar Farouq

Ijọba lbilẹ Zurmi, ni ipinlẹ Zamfara ni wọn ti bi Sadiya Umar Farouq.

O lọ si ile iwe Ijọba apapọ ti o jẹ kiki obinrin ni ilu Gusau, ni Ipinlẹ Zamfara naa.

Ile Iwe Fasiti Ahmadu Bello, ni Zaria, ni ipinlẹ Kaduna lo ti kẹkọọ gboye ninu Eto Idokowo ni ọdun 1998.

Sadiya tun ṣe ipele keji [Masters Degree] lori eto ilẹ okeere.

O gba oye ipele keji yii ni ọdun 2008, ati ipele keji miran lori Idokowo [MBA] ni ọdun 2011, ni ile ẹkọ Fasiti Ahmadu Bello, Zaria.

Obinrin yii ti ṣiṣẹ ni ọpọlọpọ ile iṣẹ ri, o ṣe ọga agba fun igbokegbodo ni Pinnacle Travels and Tours, laarin ọdun 2001 si ọdun 2003, ko too darapọ mọ ajọ ti o n risi eto ọrọ ile igbimọ.

Sadiya Farouq ti fi igba kan jẹ Akapo ẹgbẹ oṣelu APC laarin oṣu kefa, ọdun 2013 si oṣu kẹfa, ọdun 2014.

O tun ṣe Akapo ẹgbẹ oṣelu CPC to jẹ ọkan lara ẹgbẹ to parapọ ni ọdun 2013 di APC.

Sadiya ni wọn yan gẹgẹ bi Kọmiṣanna ijọba apapọ lori ọrọ awọn atipo, ati awọn ti ko rile gbe, ni oṣu Kẹsan an ọdun 2016.

Ori ipo yii lo wa di oṣu Kẹjọ ọdun 2019, ki o to di minisita fun abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede yii.

Sadiya ni obinrin naa ti ẹnu kùn ni 2019, pe Oloogbe aarẹ Buhari fẹẹ fi ṣe iyawo keji lẹyin Aisha

Tẹ o ba gbagbe, Sadiya ni obinrin naa ti ẹnu kùn ni 2019, pe aarẹ Buhari fẹẹ fi ṣe iyawo keji lẹyin Aisha to wa nile bii obinrin akọkọ nigba naa.

Ṣugbọn iroyin naa pada ja si ahesọ.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti ijọba yoo fẹsun ajẹbanu kan Sadiya Farouq, ajọ ICPC naa ti fi ẹsun ajẹbanu kan an ri .

Owo to to N2.67 biliọnù ni ICPC, ti Bolaji Owasanoye jẹ alaga fun nigba naa fẹsun rẹ kan Farouq ni 2020.

Owo naa ni wọn lo wa fun òúnjẹ àwọn akẹkọọ lati fi bọ wọn.