Àrá sán pa olọ́pàá lẹ́nu iṣẹ́

Ara to n san lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kayeefi nla ni iku ọlọpaa kan, Abdulkadir Garba, ṣi n jẹ fun awọn eeyan to gbọ pe àrá kan to san l'Ọjọru ran an lọ sọrun ojiji nigba to wa lẹnu iṣẹ lọwọ.

Maiduguri ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Borno ni Garba tawọn eeyan tun mọ si Buratai, ti pade iku ojiji nigba ti ara naa san.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno, ASP Nahum Daso, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ara san to si pa Buratai, oun nikan kọ ni ara to san naa kan.

O ni o tun kan ọga rẹ kan, ASP Wazani Adamu, ṣugbọn iyẹn ko ku ni tiẹ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Borno naa ṣe wi, o ni nigba ti ojo naa n rọ, awọn ọlọpaa mejeeji gbiyanju lati sa sibi kan, ṣugbọn ara naa san ki wọn too de ibi ti wọn fẹ sa si.

Atẹjade ti Daso fi kede iṣẹle naa ṣalaye pe:

"Ibukun ni ojo maa n saba mu wa, ṣugbọn ibanujẹ ni eyi mu wa.

"Atẹgun bẹrẹ si I fẹ, awọn ọlọpaa mejeeji gbiyanju lati wa ibi kan sa si ki ojo naa too bẹrẹ si I rọ.

" Ṣugbọn lojiji, ara nla kan san, o si ba awon ọlọpaa mejeeji to ṣi wa lẹnu iṣẹ naa."

Alukoro tẹsiwaju pe ASP Wazani Adamu ti ko ku, ri aanu gba ni, ṣugbọn Buratai ni ara naa sọlẹ le lori ju, ara rẹ bo, eyi to fa iku rẹ.

"Inspekitọ Abdulkadir Garba ko padanu ẹmi rẹ sọwọ jagidijagan tabi wahala, ṣugbọn ara to san lo mu un lọ.

"Ọlọpaa to gbajumọ to si n ṣiṣẹ rẹ daadaa ni, o si jẹ apẹẹrẹ itẹpamọṣẹ."

Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Borno sọ nipa akẹgbẹ rẹ to rọrun nipasẹ ara to san lojiji.