Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ awakọ̀ Anthony Joshua tún ṣe lọ àti àwọn kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí olùpẹ́jọ́ gbé kalẹ̀

Latif Ayodele, Anthony Joshua àti Sina Ghami jokoo lori pepele, wọn n wo ọọkan

Oríṣun àwòrán, Anthony Joshua

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbẹjọ awakọ Anthony Joshua, Adeniyi Mobolaji Kayode to n jẹjọ lori iku awọn ọrẹ gbajumọ akànṣẹ́gbayì ọhun tun tẹsiwaju.

Wọn sọ fun ile ẹjọ nibi igbejọ to waye lọjọbọ, ọjọ Kẹta, osu Kẹsan-an pe Adeniyi n gbiyanju lati sare kọja lẹgbẹ ọkọ nla kan ko to lọ fori sọ ọkọ mii ti wọn gbe kalẹ.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan pe awakọ naa ko ni iwe ẹri pe o le wakọ to si fẹmi awọn eeyan naa wewu.

Wọn sọ fun ile ẹjọ pe niṣe ni Joshua atawọn ọrẹ rẹ ti sun lọ ninu ọko Lexus SUV ti wọn wa nigba ti wọn n lọ si ilu Sagamu ki ijamba naa to waye.

Ẹlomiran to tun n jẹjọ lori ijamba ọkọ naa ni Abubakar Adamu, ẹni to jẹ awakọ ọkọ ti ọkọ awọn Anthony Joshua fori sọ, to si n koju igbẹjọ pe o gbe ọkọ si ibi ti ko yẹ eyi to ṣe idiwọ fun lilọ bibọ ọkọ geere.

Insipẹkitọ Christopher Ajayi Taiwo ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto lilọ bibọ ọkọ sọ fun ile ẹjọ pe wọn ti ko awọn ọkọ to ni ijamba naa kuro nigba ti oun fi maa de ibi ijamba naa.

Wọn sọ fun ile ẹjọ pe awọn ọlọpaa ko i tii ri Anthony Joshua ba sọrọ lẹyin ijamba naa nitori wọn ko ni nọmba rẹ.

Kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí wọ́n fi kan awakọ̀ Anthony Joshua nílé ẹjọ́

Koko ẹsun mẹrin ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi kan awakọ Lexus SUV ti Anthony Joshua atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ meji wa ninu rẹ, eyi to ni ijamba lọna marosẹ ilu Eko si Ibadan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni awakọ naa, Adeniyi Kayode, kọkọ foju ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Sagamu nipinlẹ Ogun.

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan awakọ naa ni pe o wa ọkọ lọna to lewu eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan meji Sina Ghami àti Latif Ayodele ti wọn jẹ ọrẹ Anthony Joshua.

Eleyii ni igbimọ olupẹjọ sọ pe o tako abala 5(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Ẹsun keji ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode ni ẹsun aibikita ati wiwa ọkọ ni iwakuwa eyi to lodi sofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Wiwa ọkọ lai na-an ni nnkan to le ṣẹlẹ lẹsun kẹta ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode, ati pe wọn lo tun ṣakoba fawọn to wa ninu ọkọ naa ti wọn fi farapa.

Labẹ ẹsun yii kan naa ni wọn tun ti sọ pe awakọ naa ba dukia jẹ eyi to lodi si abala 7(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Ẹsun kẹrin ti wọn fi kan awakọ Anthony Joshua ni pe o n wa ọkọ lai ni iwe ẹri iwakọ to yanranti lọwọ, eyi to lodi abala 10(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ.

Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ fun awakọ naa ni beeli pẹlu miliọnu marun un naira (N5m) ati oniduro meji.

Ile ẹjọ ti sun igbẹjọ si ọjọ Kẹwaa, oṣu Kẹsan-an.

'Ó le fún mi gan, kí Ọlọ́run ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn mi'

Ohun ti Anthony Joshua kọkọ sọ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣokùnfà ikú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì, Latif Ayodele àti Sina Ghami ni pe iṣẹlẹ naa le fun oun gidi gan.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnì X rẹ̀, Anthony Joshua ní ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ náà lágbára fún òun gan ṣùgbọ́n òun mọ̀ pé ó lágbára fún òbí àwọn èèyàn náà gan julọ.

Ó ní òun kò mọ bí àwọn ọ̀rẹ́ òun náà ṣe pàtàkì sí òun sí àyàfi ìgbà tí wọ́n jáde láyé tán.

Ó sọ pé òun àti wọn máa ń rìn papọ̀, ṣeré, rẹ́rìnín láì mọ̀ pé Ọlọ́run fi òun sí àárín àwọn èèyàn tó lágbára gidi ni.

Anthony Joshua wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún ìfẹ́ àti ìtara tí wọ́n fi hàn òun lórí ikú àwọn ọ̀rẹ́ òun náà tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ wọn sí afẹ́fẹ́ rere.