Kí ló dé tí ẹnu ń kun Sarafadeen Alli, olùdíje sípò gómìnà l'Oyo, torí fọ́nrán ibi tó ti gbé akẹ́kọ̀ọ́-kùnrin kan sórí ẹsẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Screenshot Sharafadeen Abiodun ALLI/Facebook
Sharafadeen Alli, oludije sipo gomina gbe akẹkọọ ọkunrin kan si ẹsẹ, wọn si jokoo lori aga - Alli lo mu ẹrọ gbohungbohun dani, pẹlu fila alawọ aro lasiko to n sọrọ.
Latigba ti fọnran kan ti jade sita lori ayelujara nipa oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sharafadeen Abiodun Alli, ni awọn eeyan ti n sọ oniruuru ọrọ.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe iwa ti oludije sipo gomina naa hu ko tọ, bẹẹ lawọn kan tun n fi ẹsun oniruuru to nii ṣe pẹlu iwa ọmọluabi kan, ṣugbọn ti awọn miran n jẹ ko di mimọ pe ko s'ohun to buru nibẹ.
Ninu fọnran naa to n kaakiri ori ayelujara lati Ọjọru, ọsẹ yii, la ti ri Alli, ẹni to tun jẹ Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Oyo lọwọ nile igbimọ aṣofin, to gbe akẹkọọ ile-ẹkọ gbogboniṣe tiluu Ibadan lori ẹsẹ.
Nigba to n sọrọ lori idi to fi gbe akẹkọọ naa sori ẹsẹ rẹ, Alli sọ pe oun ko ri nnkan to buru nibẹ, nitori pe gẹgẹ bi ẹni to sunmọ araalu, toun si tun nifẹ si awọn akẹkọọ, lo jẹ koun ṣe bẹẹ.
Alli sọ pe oun ko ni erongba buburu lọkan, gẹgẹ bi awọn kan ṣe n fẹsun kan oun.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ ipolongo idibo Alli fi sita, agba oloṣelu naa sọ pe gbogbo ẹsun ti wọn fi n kan oun lo ni ọwọ oṣelu ninu.
O jẹ ko di mimọ pe nigba ti awọn akẹkọọ naa wa ba oun ni ọfiisi ipolongo oun to wa niluu Ibadan, ko si aaye mọ, nitori pe awọn agbaagba ti jokoo fun ipade, to si ni ko sibi ti awọn akẹkọọ ọhun fẹẹ jokoo si.
"Ileeṣẹ ipolongo oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Sharafadeen Alli ti bu ẹnu atẹ lu igbiyanju awọn iroyin ori ayelujara kan ti wọn n ṣi iroyin ohun to ṣẹlẹ kọ," ileeṣẹ ipolongo naa sọ bẹẹ.
"Sẹnetọ Alli mọ-ọn-mọ gbe akẹkọọ naa lori ẹsẹ ni, nigba ti ko si aaye mọ lati jokoo ninu ọfiisi lasiko naa.
"O ṣeni laaanu pe wọn ti lọ ọrọ oṣelu mọ ohun to ṣẹlẹ yii, ati pe ipo oṣelu ti gbe wa de ibi ti a wa yii, nibi ti ajọsọ laaarin baba ati ọmọ to wa fun iranlọwọ ti di ohun ti wọn n sọ buruku nipa rẹ."
"Kò sọ́rọ̀ níbẹ̀ rárá"
Siwaju sii lo sọ pe ko yẹ ki ọrọ oṣelu gbe wọn de ipo ti wọn wa yii, nibi ti awọn oloṣelu alatako yoo ti maa lo awọn eeyan wọn lati maa lo awọn oniroyin fi ṣiṣẹ titabuku ba oludije awọn.
Wọn sọ pe oludije awọn ko ni ohunkohun lati fi pamọ, tabi pe ko lẹbọlẹru, nitori pe ita gbangba lo ti n ba awọn to ba fẹẹ rii sọrọ, paapaa bi awọn akẹkọọ, olori agbegbe tabi araalu.
O pe awọn to n gbe iroyin naa kaakiri ori ayelujara nija lati fi okodoro sita, dipo ki wọn maa wa awawi kaakiri.
"Awọn to mọ Sẹnetọ Sharafadeen Alli ni oye nipa rẹ wi pe o ko awọn eeyan mọra. Ko si idi kan ni pato ti yoo fi maa ṣe iru nnkan ti wọn n fi ẹsun rẹ kan an," wọn jẹ ko di mimọ.
Wọn wa sọ pe eto ipolongo idibo ni Alli gbajumọ lasiko yii, paapaa nipa ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn ara ati olugbe ipinlẹ Oyo, ati pe ko si iru awuyewuye ti yoo daa duro tabi dii lọwọ.


























