Kímò méjì ló kù kí Atinuke gbà fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ tó fi kú, ń kò le sọ iye owó tí a kó jọ fún-un, ọjọ́ pẹ́ tó ti ń sàìsàn, a ti sín ní àná - Owolabi Ajasa

Oríṣun àwòrán, Atinuke Kareem/Screenshot Owolabi Ajasa/Facebook
Latigba ti iroyin iku gbajugbaja oṣere nni, Atinuke Kareem tun ti jade sita ni ọpọ awọn ololufẹ ere tiata nilẹ Naijiria, ti bẹrẹ sii kọminu lori ajalu iku to n ṣẹlẹ lagbolee oṣere lasiko yii.
Bo tilẹ jẹ pe oṣere mẹrin ni wọn ti jade laye laaarin oṣu meji si asiko yii, sibẹ, mẹta ninu wọn lo jẹ iku wọn wa lẹyin aisan jẹjẹrẹ to ba wọn finra.
Temitope Osoba, Taiwo Hassan Ogogo, Alabi Ogundepo ati Atinuke Kareem toun ṣẹṣẹ ku, ni awọn oṣere mẹrin ti iku ojiji ti gba aṣọ lọrun wọn laaarin ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ si ọjọ kinni, oṣu Kẹsan, ọdun 2026.
"Ó ti pẹ́ tí Atinuke ti wà lórí àìsàn yìí" - Owolabi Ajasa
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, gomina ẹgbẹ oṣere TAMPAN, ẹka tipinlẹ Ogun, Owolabi Ajasa sọ pe oṣerebinrin naa ti wa lori idubulẹ aisan yii tipẹ, to si n gba itọju.
Ajasa sọ pe nigba ti agbara ko fẹẹ gbe e mọ, lo jẹ ko ke gbajare sita fun iranlọwọ, to si lawọn ẹlẹyinju aanu dide lati da owo fun un.
Gomina naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan dide iranlọwọ fun un, sibẹ oun ko le sọ pato iye owo ti awọn eeyan da fun un, nitori pe apo aṣuwọn ile ifowopamọ oloogbe ni awọn fi silẹ, ti awọn eeyan n fi owo ranṣẹ si.
O jẹ ko di mimọ pe oloogbe nikan lo le sọ pato iye owo to wọle fun itọju aisan jẹjẹrẹ ọmu naa.
"O ti pẹ diẹ ti Atinuke Kareem ti wa lori aisan naa.
Awọn eeyan dide lati gbaruku tii, nigba to jade fun iranlọwọ.
Mi o le sọ iye owo ti awọn eeyan da fun un, nitori pe apo aṣuwọn oloogbe naa la fi sita fun awọn eeyan lati fi owo ranṣẹ sinu rẹ, fun itọju," Ajasa sọ bẹẹ fun BBC News Yoruba.
Bakan naa lo sọ pe abojuto ilera rẹ lasan ni ẹgbẹ TAMPAN bojuto, lati rii pe o wa ni ilera pipe.
"Ohun ti awa ṣe ni abojuto nipa bi nnkan ṣe n lọ, boya to ba nilo ohunkohun ati awọn nnkan miran, ka dide si i. N ko le sọ pato iye owo to wọle fun un.
"Òru mọ́júmọ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ló jáde láyé"
Gomina TAMPAN l'Ogun sọ pe oru ọjọ Aje mọjumọ ọjọ Iṣẹgun ni Kareem ki aye pe o digboṣe, nigba ti ọrọ yiwọ.
O sọ fun BBC pe ara rẹ ti n balẹ, ṣugbọn to jẹ pe niṣe ni ọrọ tun yiwọ lojiji, leyi to jẹ ki awọn mọlẹbi rẹ sare gbe e lọ sile iwosan fun itọju, ṣugbọn to dakẹ loju ọna.
"Gẹgẹ bi awọn ẹgbọn rẹ ṣe sọ fun wa, ijẹta mọju si ana ni ọrọ tun yiwọ, to fi di pe wọn sare gbe e lọ sile iwosan kan niluu Abeokuta fun itọju.
Igba ti wọn maa fi gbe e de ile iwosan, o ti dakẹ.
"Wọn ko ni ohun meji ti wọn tun fẹẹ ṣe ju ki wọn gbe e pada sile lọ," Ajasa fidi rẹ mulẹ.
"Ohun tó bá mí sọ gbẹ̀yìn"
Siwaju sii ni agba oṣere naa fidi rẹ mulẹ pe oun pẹlu Kareem sọrọ lọjọ Abamẹta, to si ṣalaye ipo ti ilera rẹ foun.
O ni oloogbe naa sọ foun pe ara oun ti n ya, ati pe itọju ti wọn n pe ni 'chemotherapy' meji pere lo ku foun lati ṣe, ko to di pe oun lọ ṣiṣẹ abẹ.
"Alẹ ọjọ Abamẹta lemi pẹlu ẹ ṣi sọrọ.
Mo beere ibi ti ọrọ ilera rẹ de duro, o si sọ fun mi pe ara oun ti n balẹ, ati pe 'chemotherapy' meji lo ku foun lati gba, wi pe lẹyin naa ni wọn yoo too ṣẹṣẹ ṣiṣẹ abẹ foun.
"Awọn ẹgbọn rẹ sọ pe aarin oru ni nnkan yẹn bẹrẹ, ti wọn fi gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ.
Nnkan bi agogo marun-un si mẹfa aarọ ni wọn too ṣẹṣẹ da a pada sile."
A ti sìnkú rẹ̀
Owolabi Ajasa tọpọ mọ si Ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe "Ko sọ ohunkohun fun mi ju pe ara oun ti n balẹ lọ."
Alaga wa jẹ ko ye wa pe awọn ti sinku rẹ loju ẹsẹ, ati pe bi gbogbo eto yooku yoo ṣe lọ, o dọwọ gbogbo mọlẹbi.
"A ti sinku oloogbe lọjọ Iṣẹgun ti iroyin naa jade sita, awọn mọlẹbi si ti ṣeleri lati maa fi bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ to wa leti."
Atinuke kó ipa ribiribi lẹ́gbẹ́ TAMPAN
Nigba to n kadi ọrọ rẹ nilẹ, Ajasa sọ pe obinrin naa ko ipa takuntakun ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN titi digba ti ọlọjọ fi de.
O ni ko si nnkan ti wọn beere lọwọ rẹ, ti ko nii dahun si, paapaajulọ, bo tun ṣe jẹ alaga ẹgbẹ naa ni ẹkun
"Eeyan daadaa ni oloogbe, oun ni alaga ijọba ibilẹ Guusu-Iwọ-Oorun Abeokuta nipinlẹ Ogun, o si n ṣe daadaa, bẹẹ naa lo n ṣe daadaa ninu ẹgbẹ.
"Gbogbo nnkan ti a ba beere lo n fi silẹ gẹgẹ bi alaga, to si tun jẹ alakikanju eeyan to ko ipa ribiribi ninu ẹgbẹ TAMPAM wa."

Oríṣun àwòrán, Atinuke Kareem/Instagram
Ọ̀fọ̀ tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àrùn jẹjẹrẹ tún pa gbajúmọ̀ òṣèré míràn, Atinuke Kareem
Iroyin ibanujẹ miran lo tun ti sọ lagboole awọn oṣere tiata nilẹ Naijiria bayii, pẹlu bi gbajumọ oṣerebinrin nni, Atinuke Kareem ṣe jade laye.
Ko si nnkan meji ti a gbọ pe o ṣokunfa iku Atinuke Kareem, to kọja aisan jẹjẹrẹ ti ọmu.
Gomina ẹgbẹ oṣere, ẹka ti TAMPAN nipinlẹ Ogun, owolabi Ajasa lo fidi iroyin yii mulẹ loju opo ayelujara rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.
Ajasa sọ pe ibanujẹ ni iku oṣerebinrin naa, Kareem jẹ fun wọn, pẹlu bi aisan jẹjẹrẹ ti ọmu ṣe da ẹmi rẹ legbodo.
Yatọ si Owolabi Ajasa to fidi rẹ mulẹ, aarẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Bolaji Amusan tọpọ awọn eeyan mọ si Mista Latin naa tun fidi rẹ mulẹ.
Iṣẹlẹ yii ni yoo jẹ eyi ti yoo iṣẹlẹ kẹta laaarin oṣu meji, ti aisan jẹjẹrẹ yoo maa ran awọn oṣere tiata lọ sọrun lai ro tẹlẹ.
Tope Osoba ni iroyin rẹ kọkọ gba igboro lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026; ko ju bi ọsẹ meji aabọ lọ, ti Taiwo Hassan Ogogo naa tun jade laye lori aisan jẹjẹrẹ yii.
"Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú ati adura wa, Atinuke jade laye, o si ti dahun ipe ikẹyin"
Nigba to n kede, Owolabi Ajasa sọ pe "A dupẹ lọwọ gbogbo eeyan ti wọn dide iranlọwọ nipa owo, adura ati amọran, pẹlu igbaruku ti si itọju ọkan lara wa, Atinuke Remilekun Kareem.
"Ifẹ yin ati akitiyan yin lasiko ipenija rẹ jẹ ohun pataki si wa ati mọlẹbi rẹ. A fi tọkantọkan dupẹ.
"O ṣeni laanu wi pe, pẹlu ibanujẹ wi pe gbogbo igbiyanju ati adura wa, Atinuke jade laye, o si ti dahun ipe ikẹyin," Ajasa sọ bẹẹ.
Bakan naa lo ni awọn ko le ba Ọlọrun wijọ lori oṣere naa, ati pe adura nikan ni awọn le gba wi pe ki Ọlọrun tẹ e si afẹfẹ rere, ko si fun awọn ẹbi oloogbe ni ọkan lati farada ipapoda ọhun.
"Àìsan jẹjẹrẹ ọmú ló pa á"
Nigba toun naa n kede, Bolaji Amusan sọ pe aisan jẹjẹrẹ lo ṣeku pa Atinuke Kareem, lẹyin ọpọlọpọ itọju.
"Aisan jẹjẹrẹ lo gba a kuro lọwọ wa, to si fi awọn itan ti a ko le gbagbe silẹ ninu ọkan wa. Sun re o. Atinuke Kareem.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni obinrin naa jade sori ayelujara lati bẹbẹ fun iranlọwọ owo ati itọju lori aisan jẹjẹrẹ ọmu to n ba a finra.
Kareem sọ ọ di mimọ pe oun na ọpọlọpọ, ti awọn mọlẹbi oun naa si tun ti na owo pẹlu lati fi tọju oun.
O ni agbara ti ko gbe e mọ, lo jẹ koun jade lati tọrọ fun iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu.
Bakan naa lo sọ pe ko wun oun lati fi aye silẹ bayii, paapaa nitori awọn ọmọ meji ti wọn ṣi kere, ati pe ko sẹni to le tọju wọn bi oun.



























