Irọ́ lo pa! Ìjọba àpapọ̀ kò fún wa lówó kankan lórí àtúnṣe pápákọ̀ òfurufú ìlú Ibadan - Makinde fún Wike lésì

Makinde wọ aṣọ olomi aro, o de fila, Wike wa lẹyin rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ni irọ to jina si ootọ ni pe ijọba apapọ fun ipinlẹ Oyo ni aadọta biliọnu naira lati fi ṣatunṣe papakọ ofurufu to wa ni ilu Ibadan gẹgẹ bi Minisita fọrọ ilu Abuja, Nyesom Wike ṣe sọ.

Makinde sọ eyi nigba to n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ ni ilu Katsina nibi to ti sọ ọ pe ijọba apapọ ko fun oun ni owo kankan lati ṣe atunṣe papakọ ofurufu Ladoke Akintola to w ani ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.

Gomina naa sọ pe oun n ṣe afọmọ ọrọ naa latari ohun ti Wike sọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan TVC nibi to ti sọ pe Aarẹ Bola Tinubu fun ipinlẹ Oyo ni aadọta biliọnu naira lati fi ṣe atunṣe papakọ ofurufu Ibadan.

Wike, nigba to n sọrọ nibi eto naa sọ pe ijọba apapọ labẹ idari Aarẹ Bola Tinubu ṣe iranwọ fun ijọba ipinlẹ Oyo pẹlu aadọta biliọnu naira lati fi tun papakọ ofurufu ilu Ibadan ṣe ki o le wa ni ibamu pẹlu ti igbalode.

Amọ Makinde ti wa jiyan ẹsun naa to si ni irọ to jina si ootọ ni.

"Aarẹ Naijiria ko fun mi ni aadọta biliọnu naira tabi ipinlẹ Oyo ni aadọta biliọnu naira lati mu atunṣe ba papakọ ofurufu Ibadan. Owo ipinlẹ Oyo nikan ni a fi n ṣe atunṣe papakọ ofurufu naa."

Nigba to n fidi ọrọ gomina naa mulẹ, agbẹnusọ Makinde, Dokita Sulaimon Olanrewaju ninu atẹjade kan juwe ohun ti Wike sọ bi ohun to le ṣi awọn eeyan lọkan.

Olanrewaju sọ pe ijọba apapọ ko buwọlu aadọta biliọnu naira fun ipinle Oyo lori atunṣe papakọ ofurufu.

O ni ohun ti Wike sọ naa lo jẹ ọrọ oṣelu lasan, ti awọn ko si ni jẹ ki eeyan kan maa pa irọ lori ohun ti ko ṣẹlẹ.

O fi kun pe Aarẹ Bola Tinubu kan buwọlu atunṣe papakọ ofurufu Ibadan lasan ni lori iwe ti Makinde kọ ranṣẹ si lati beere fun ibuwọlu lati tun papakọ ofurufu naa ṣe amọ ko fi owo kun-un.

O ni oun gbagbọ pe ohun ti Wike sọ ko wa lati igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ tabi ibuwọlu ijọba, to si jẹ pe Wike kan n sọ tirẹ ni.

"Wike kii ṣe agbenusọ ijọba apapọ, ohun to sọ ko fẹsẹ mulẹ nitori ko si ẹri fun-un. Ko yẹ ki ẹnikẹni gba ohun to sọ gbọ nitori o kan sọ ọ lati fi idi ootọ mulẹ.

Olanrewaju tẹmpẹlẹmọ pe gbogbo atunṣe to n waye lori papakọ ofurufu naa lo jẹ latọwọ ijọba ipinlẹ Oyo, to si jẹ owo ijọba ipinlẹ Oyo nikan ni wọn n na lelori.

O ni o yẹ ki Wike ti ṣe iwadii lori ohun to jẹ ootọ lori ọrọ naa ko to maa lọ sọ lori amohunmaworan, ko to maa ṣi awọn eeyan lọkan.