APC àti Makinde ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ láti dènà EFCC láti ṣe ìwádìí ìṣúná Oyo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives, APC ni ipinlẹ Oyo, ti bu ẹnu ate lu bi Gomina Seyi Makinde ṣe pe ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC lati ṣayẹwo awọn iwe owo to niiṣe pẹlu iṣejọba rẹ lati ọdun meje sẹyin yẹwo.
APC ni iwa itiniloju gbaa mni iṣejọba Makinde hu lori igbesẹ naa.
Ẹ o ranti pe ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Oyo ti gbe aṣẹ kalẹ wi pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC ko gbọdọ ṣe iwadii tabi tọpinpin eto iṣuna ijọba ipinlẹ Oyo labẹ iṣakoso Gomina Seyi Makinde.
Onidajọ Nkeonye Maha lo gbe idajọ naa kalẹ ninu ẹsun ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe lọ siwaju rẹ lọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 lati tako bi ajọ EFCC ṣe fẹẹ wa tudi eto iṣuna wọn wo.
EFCC lo gbe akanṣe iwadii dide lati ṣe agbeyẹwo awọn owo iṣẹ akanṣe ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe jade fun awọn agbaṣẹṣe laaarin ọdun 2021 si ọdun 2025.
Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ nipinlẹ Oyo, Olawale Sadare fi lede lọjọbọ bu ẹnu atẹ lu Makinde pe ko fẹ ki ajọ to n ri si iwa ajẹbanu naa ṣe ojuṣe rẹ eyi to fi aaye gba wọn lati ṣayẹwo eto isuna ipinlẹ fun igba kan.
Sadare ninu atẹjade naa ni Makinde ro boya ṣiṣe gomina jẹ anfaani fun eeyan lati sọ ọrọ ilu di tirẹ, ti ko mọ pe oun maa jabọ gbogbo bi oun ṣe na owo ati ọrọ ilu nigba to wa lori ipo.
O fẹsun kan niṣe ni Makinde n ṣejọba bi apaṣẹ wa a, ti ko si ẹni to le bi i lẹjọ lori gbogbo ohun to ba n ṣe.
APC ni ibeere to gba ẹnu ọpọ eeyan páapaa awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni pe ki lo de ti gomina yoo ṣe maa bẹru lati jabọ ohun to fi owo awọn araalu.
Wọn ni pe ohun to han daju gbangba ni pe Makinde kan le fara pamọ fun igba diẹ ni ko le sa mọ ijọba lọwọ nitori EFCC atawọn ajọ oluwadii mii maa ṣe iṣẹ wọn nigba ti akoko ba to ti wọn si maa ṣi furọ adiẹ sita.
Makinde ko bẹru EFCC tabi ajọ ijọba apapọ kankan - Ijọba Oyo fesi
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Oyo ti wa fesi si ẹsun APC yii ti wọn si ṣalaye pe idi ti ijọba fi lọ sile ẹjọ lati beere idi ti EFCC ṣe fẹ ṣewadii awọn akọọlẹ iwe owo kii ṣe lati da iwadii duro ti wọn si tẹmpẹlẹmọ pe Makinde ko ni ohunkohun lati fi pamọ.
Agbẹnusọ Makinde, Sulaimon Olanrewaju ninu atẹjade to fi lede sọ pe ijọba morile ile ẹjọ nitori EFCC kọ lati sọ ileeṣẹ tabi awọn agbaṣẹṣe ti wọn n ṣe iwadii wọn.
Olanrewaju ninu atẹjade naa sọ pe EFCC n beere fun gbogbo awọn iwe ti ijọba fi gbe iṣẹ jade laaarin ọdun 2021 si 2025 amọ ti wọn ko sọ ileeṣẹ ti wọn n ṣe iwadii ni pato.
O ni ohun ti ijọba fi lọ sile ẹjọ ni lati mọ boya bibeere fun gbogbo awọn akọọlẹ tọna labẹ ofin.
"Bibeere fun alaye lori agbara EFCC kii ṣe tori ojo tabi ibẹru, Gomina Makinde ati ijọba ipinlẹ Oyo ko bẹru EFCC tabi ajọ ijọba apapọ kankan."
O fi kun pe ijọba maa fi gbogbo akọọlẹ to ba tọna ṣọwọ ti wọn beere awọn ohun to ba ofin mu.
Olanrewaju ni Gomina Makinde ti ṣamulo ọrọ ipinlẹ Oyo daadaa to si ni awọn aṣeyọri rẹ han ni gbogbo ẹka to fi mọ ọna ṣiṣe, eto ilera, eto ẹkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bí iléẹjọ́ ṣe dá EFCC lọ́wọ́ kọ́ láti ṣe ìwádìí ìṣúná gómìnà Oyo, ẹgbẹ́ APM ní ẹ̀rù Makinde ló ń ba Tinubu

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Bola Tinubu
Ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Oyo ti gbe aṣẹ kalẹ wi pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC ko gbọdọ ṣe iwadii tabi tọpinpin eto iṣuna ijọba ipinlẹ Oyo labẹ iṣakoso Gomina Seyi Makinde.
Onidajọ Nkeonye Maha lo gbe idajọ naa kalẹ ninu ẹsun ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe lọ siwaju rẹ lọjọ keji, o]su Kẹfa, ọdun 2025 lati tako bi ajọ EFCC ṣe fẹẹ wa tudi eto iṣuna wọn wo.
EFCC lo gbe akanṣe iwadii dide lati ṣe agbeyẹwo awọn owo iṣẹ akanṣe ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe jade fun awọn agbaṣẹṣe laaarin ọdun 2021 si ọdun 2025.
Ile-ẹjọ naa sọ ọ di mimọ pe pe bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ni aṣẹ labẹ ofin lati ṣe iwadii iwa jibiti owo ati ajẹbanu, ṣugbọn to tun sọ pe iru agbara bẹẹ ko gbọdọ da lori awuyewuye tabi lilo o lọna ti ko yẹ.
Gẹgẹ bi adajọ naa ṣe sọ, o ni ajọ EFCC fẹẹ ṣe iwadii ofintoto lori owo ti wọn na fun awọn agbaṣẹṣe, bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ awọn agbaṣẹṣe tabi ileeṣẹ, tabi owo to jade, tabi ẹsun aṣemaṣe.
Ile-ẹjọ wa sọ pe ajọ naa gbọdọ bọwọ fun ẹtọ labẹ ofin lojuna lati ṣe eyikeyi iwadii tabi ofintoto.
Ijọba ipinlẹ Oyo lo sọ fun ile-ẹjọ wi pe ki ajọ EFC tọka si awọn agbaṣẹṣe tabi owo to jade ninu igbesẹ lati ṣe iwadii rẹ, ki awọn le pese gbogbo iwe ẹri to yẹ fun iwadii wọn.
Ṣugbọn ṣa, lẹyin ti wọn ko gbọ ohunkohun lati ọdọ ajọ naa, eyi lo mu ki ijọba ọhun gba ile-ẹjọ lọ, lati ṣe atupalẹ ofin lori iru igbesẹ bẹẹ.
Agbẹjọro ijọba, Amofin Abiodun Aikomo sọ fun ile-ẹjọ bi ajọ EFCC ṣe fẹẹ ṣe awọn iwadii to nii ṣe pẹlu ọpọlọ ọdun ko tọna rara, o jẹ bii idunkooko, ati pe ko si ẹsun kankan to tii lẹyin
Ṣugbọn ṣa, nigba ti agbẹjọr EFCC n sọrọ ni tiẹ, I.G. Ojibor sọ pe abala kejidinlogoji ninu iwe to awọn silẹ fun wọn ni agbara lati beere fun awọn iroyin nipa ẹnikẹni, alakoso yoowu, ileeṣẹ tabi ijọba ninu igbesẹ lati ṣe iwadii ofintoto.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidajọ Maha, o gbe iwe ajọ EFCC sẹgbẹ kan, to si paṣẹ pe, niwọn igba ti ajọ naa bi agbara lati beere ibeere nipa ohun to ba ru wọn loju, iru ibeere bẹẹ gbọdọ waye lọna to yẹ, lori awọn ẹsun to ṣee foju ri ati eyi to ṣee feti gbọ, to si tun lọ ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn ba fi sita labẹ iwe ofin idasilẹ ajọ EFCC.
Makinde yóò gba ìjọba lọ́wọ́ Tinubu lọ́dún 2026 – APM sọ̀rọ̀
Ju gbogbo rẹ lọ, ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) ti wa ṣalaye awọn idi pataki ti Gomina Seyi Makinde yoo ṣe fidi Aarẹ Bola Tinubu rẹmi ninu eto idibo aarẹ ti ọdun 2027.
APM sọ pe awọn ipa rere ti Makinde ti ko ninu iṣakoso rẹ bii akọsilẹ iṣakoso, atunto eto ọrọ ati bi idagbasoke ṣe n de ba ifẹ ti awọn eeyan n ni jakejado agbaye.
Ẹgbẹ naa sọ pe awọn akitiyan gomina lori atunṣe si eto ọrọ aje ati iṣẹ akanṣe manigbagbe ti gbe e si ipo ti awọn ọmọ Naijiria ri gẹgẹ bi ọna abayọ lati oke.
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lapapọ, Abubakar Yusuf fi sita, lasiko to n sọrọ lori ọrọ ti oludamọran pataki si aarẹ lori eto iroyin, Daniel Bwala, nipa bo ṣe bu ẹnu atẹ lu ipo oṣelu Makinde.
O sọ pe bi agbẹnuọ ileeṣẹ aarẹ ṣe n ṣe ikọlu si Makinde, fi han pe iporuru ọkan ti n ba ileeṣẹ aarẹ, lori bi gomina ṣe n gba iyi ati iyi ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2027.
Yusuf sọ pe kaka ki wọn maa gbeja iṣakoso aarẹ lori awọn ipa to ti ko, ileeṣẹ aarẹ wa bẹrẹ sii ṣe atako si awọn alatako nidi oṣelu.
"Igbesẹ lati gbe awọn alabaṣiṣẹpọ aarẹ dide lati maa bu ẹnu atẹ lu Gomina Makinde ṣafihan aini igboya ninu aṣeyọri iṣakoso aarẹ. Eto idibo 2027 yoo ṣafihan ẹni ti ko ṣe pataki rara ni tootọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.
Ẹgbẹ APM tun tọka si ifọrọwerọ ti Bwala ṣe pẹlu ileeṣẹ Al Jazeera ni ibẹrẹ ọdun yii, leyi to fi sọ pe awọn ọmọ Naijiria ti mọ ọna ti iṣakoso yii n gba sọrọ jade.
"Daniel Bwala maa too ko awọn ọrọ rẹ to fi tako Gomina Makinde jẹ," atẹjade ọhun ṣalaye.
"O yẹ ki Aarẹ Tinubu tete maa ṣaniyan bayii nitori pe Gomina Makinde n bọ lati ba a du ipo, pẹlu awọn ipa rere to ti ko lawujọ, to fi mọ bo ṣe tun ipo Oyo ṣe," Yusuf sọ bẹẹ.




























