You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n bá òkú ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nínú yàrá l'Osun, ariwo sọ
Wọn ti ri oku ọdọbinrin kan ladugbo Jaleyemi niluu Osogbo nipinlẹ Osun.
Awọn ara adugbo naa sọ pe lati ọjọ aje ọjọ kẹrin Osu Karùn-ún ọdun yii ni awọn ti ri Kemisola gbẹyin.
Kemisola, ọmọ ọdun mọkanlelogun jẹ ọmọbibi ilu Igbajo ní ijọba ibilẹ Boluwaduro ni ipinlẹ ọsun.
Awọn aladugbo ati awọn olugbe papọ pẹlu oloogbe Kemisola ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn bi awọn ṣe ri oku rẹ ninu yara rẹ ni ana ọjọ Keje osu Karùn-ún ọdun yii.
Ẹnikan ti oun ati Kemisola jọ n gbe ninu ile kan naa sọ pe oloogbe naa jẹ oṣiṣẹ awọn to maa tun irun ori obinrin se.
O ni Kemisola tun jẹ akinkanju nidi iṣẹ rẹ daada, ṣugbọn lati bi osu kan sẹyin ni oloogbe naa ko ti fi gbogbo ara gbe ile mọ latari bi ko ṣe si ina mọnamọna ninu ile naa.
O sọ pe eleyi lo mu ko wa sile ni alẹ ọjọ Aje ti o si wọ inu yara rẹ lọ gẹgẹ bi o ṣe maa n ṣe ni gbogbo igba to ba ti ibi iṣẹ ojo rẹ de.
Ṣugbọn, nigba ti o di alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn gbọ orun-un kan, eyi tawọn ro pe boya eku lo ku sinu ile ni.
O ni nigba ti orun-un naa ti gba gbogbo inu ile, ni oun wa ibi ti eku ku si ninu ile naa. Saadede ni oun gbọ orun-un naa lati inu yara oloogbe Kemisola ti oun si fi ọwọ kan ilẹkun oloogbe naa.
Alabagbe oloogbe naa ni bi oun ṣe fi ọwọ kan ilẹkun naa ni ilẹkun naa si ti oun si pe orukọ oloogbe naa amọ ko da oun l'ohun.
O sọ pe eleyi lo mu ki oun yọju wo inu yara oloogbe naa, ṣuugbọn, fun iyalẹnu oku oloogbe Kemisola lohun ba ni ori bẹdi rẹ.
Bayii ni alabagbe oloogbe pariwo pe gbogbo ara inu ile ati aladugbo wa wo ohun ti oun ri.
Awọn eeyan ṣe apejuwe oloogbe Kemisola pe o jẹ onírẹlẹ, kii si ba eeyan ja lati ọjọ to ti de inu ile naa rara.
Ọbẹ ati nnkan kan to wa ninu ike kekere kan ni wọn ba lẹgbẹẹ oloogbe naa, ṣugbọn wọn ko mọ bo ya mọjele ni abi bẹẹ kọ.
Ṣugbọn awọn Ọlọpaa ti gbe oku rẹ ati gbogbo ohun to wa ninu yara oloogbe lọ.
A ko ti mọ iru iku to pa oloogbe Kemisola. Ọlọpaa.
Arakunrin Abiodun Ojelabi, agbẹnusọ fun awọn Ọlọpaa ipinlẹ ọsun ti sọrọ lori iṣẹlẹ iku oloogbe Kemisola.
O ni awọn ko ti mọ iru iku abi ọna ti iku naa gba pa oloogbe Kemisola.
Ileeṣẹ fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gbe oku ọdọmọde naa lo si ile igbokusi ti ilewosan Fasiti ti ipinlẹ ọsun lati ṣe ayẹwo iku ti oloogbe naa ku.
Ati wi pe, awọn duro de awọn ẹbi oloogbe Kemisola lati fi ọwọ siwe ki awọn le tẹsiwaju ninu ayẹwo ati iwadii iku to pa oloogbe naa.