Lateef Adedimeji kéde orúkọ àwọn ìbẹ́ta rẹ àti ọjọ́ tí wẹ̀jẹwẹ̀mu ìdúpẹ́ yóò wáyé

Aworan Lateef Adedimeji pẹlu iyawo rẹ to gbe awn ọmọ wọn dani

Oríṣun àwòrán, Screensho

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ti Eleduwa fi ibẹta ta wọn lọrẹ lọsẹ to kọja, gbajumọ oṣere tọkọtaya, Lateef Adedimeji ati Mo Bimpe ti ṣe isọmọlorukọ awọn ẹtaoko wọn.

Gẹgẹbi ọrọ ati fidio to fi si oju opo ayelujara rẹ, Lateef Adedimeji ṣalaye pe awọn ti ṣe isọmọlorukọ fun awọ̀n ọmọ awọn ni ọjọ Ẹti.

Bakan naa lo ṣalaye pe, Rahman, Raheem ati Rakeeb lawọn sọ awọn ọmọ naa.

Lateef Adedimeji tun ṣalaye wi pe oṣu keje dun yii lawọn yoo ṣe wẹjẹwẹmu idupẹ gbigbe oyun ati bibi layọ. O ni wẹjẹwẹmu naa ni wọn yoo ṣe "fun gbogbo eeyan lati jẹri si didara Ọlọrun!" Amọṣa ko ṣalaye ọjọ gan ni pato ti yoo jẹ ninu oṣu keje.

Ẹ jọwọ̀ gbogbo aworan to n lọ kaakiri kii ṣe aworan awọn ọmọ wa – Lateef Adedimeji

Aworan Lateef Adedimeji ati iyawo rẹ ti wọn jọ gbe ọkan lara awọn ọmọ wọn.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Bakan naa ni eekan oṣere tiata naa tun ke gbajare sita pe oun rii pe awọn aworan awọn ọmọ to jojungbese kan ti n lọ kaakiri lori ayelujara, amọṣa awọn ọmọ to wa ninu awọn aworan naa kii ṣe awọn ibẹta oun o.

"Ni kete ti a ba ti ṣetan lati fi oju awọn ọmọ wa sita, ẹ gbagbọ pe oju opo ayelujara wa lẹ ti maa kọkọ rii."

O wa rọ awọn eeyan lati maṣe lo ẹda ayederu aworan igbalode AI to n lọ kaakiri lori ayelujara.