You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tó dùn mi jùlọ láyé lọ̀rọ̀ tí ìyàwó mi sọ pé méjì nínú ọmọ márùn ún tí mo ṣe súná wọn kìí ṣe tèmi - Òṣèré tíátà, Tioruju
Ori ayelujara n yeruku lala lẹyin ti agbaọjẹ oṣere tiata, Taofeek Salami ti ọpọ mọ si Tioruju Mondusi, sọ pe nnkan to dun oun julọ laye lọrọ ti iyawo oun sọ foun pe meji ninu ọmọ marun un ti oun ṣe suna wọn ni kii ṣe toun.
Nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu African A List, Tioruju ṣalaye bi o ti pada sile lati ibi to ti lọ ṣe ere ori itage, ti ko si ba iyawo rẹ ti oyun ọmọ karun un wọn wa ninu rẹ.
Ọkan lara awọn ọmọ rẹ to wa nile sọ fun un pe iya oun ti kuro nile fun bi ọjọ mẹta.
Lẹyin naa ni o sọ pe oun lọ fi ẹjọ iyawo oun sun nile awọn obi rẹ.
Amọ, nigba to de ibẹ lo ri fọto iyawo rẹ pẹlu ọkunrin mii lara ogiri.
Tioruju ni oun gbeja koju iyawo oun nibẹ, o si jẹwọ wi pe oun kọ lo ni oyun to wa ninu rẹ.
Ọrọ yii lo fa ija laarin awọn mejeeji, lẹyin naa si ni gbajumọ oṣere naa sọ pe ọkunrin kan toun ti ri ni ṣọọbu iyawo oun ri lasiko kan lo tọwọ bọwe iṣẹ abẹ ti obinrin naa fi bimọ.
O ni oun ko tiẹ ro pe ọkunrin naa ni ajọṣepọ pẹlu iyawo oun rara.
''Iyawo mi sọ fun ile ẹjọ wi pe akọbi mi, ẹkeji ati ẹkẹrin nikan lọmọ toun bi fun mi''
''Lẹyin ti o bimọ karun un tan lo sọ pe ki n wa gba ọmọ ọhun, amọ, mo kọ mi o lọ.
O pada gbe ọmọ naa wa bami pẹlu ọkunrin to ni ajọṣepọ pẹlu rẹ, eyi to mu mi pe ọlọpaa lati mu wọn.
Ọlọpaa beere bi mo ṣe jẹ si i, o si sọ fun wọn pe baba ọmọ oun ni mo jẹ nigba ti ọkunrin naa jẹ ọkọ oun.
Bayii ni ọkunrin naa bẹrẹ sii bẹ mi wi pe ki n gbe ẹjọ naa kuro lọdọ ọlọpaa tori oun ko fẹ ki iyawo ile oun to ti bimọ mẹrin foun mọ.
A ṣa pada kuro ni agọ ọlọpaa, ṣugbọn mi o gba ọmọ naa,'' Tioruju lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Salami sọ pe ko to oṣu kan ti oun fi ọlọpaa mu awọn mejeeji ni iyawo oun jawe ikọsilẹ foun.
O ni obinrin naa si sọ nile ẹjọ wi pe mẹta ninu ọmọ marun un toun bi lo jẹ toun.
Iyawo mi sọ pe ọkunrin keji yẹn lo lawọn meji yoku.
''Iyawo mi sọ fun ile ẹjọ wi pe akọbi mi, ẹkeji ati ẹkẹrin nikan lọmọ toun bi fun mi.
Eyi tumọ si pe emi kọ ni baba ọmọ kẹta ati ikarun un to bi nile mi.
Ṣugbọn emi ni mo ṣe suna gbogbo awọn ọmọ marun un yii, ti mo si ṣe itọju wọn.
Iyawo mi ṣalaisi lọdun to kọja, ni gbogbo igba ti mo ba ranti ọrọ naa lo maa n dun mi,'' Tioroju ṣalaye.