Àlàyé rèé lórí ìdí tí ọkọ̀ òfurufú tó ń bọ̀ láti Amẹ́ríkà, tó yẹ kó balẹ̀ l‘Eko padà láì já èrò inú rẹ̀, lẹ́yín tó dúró fún wákàtí mẹ́jọ lójú òfurufú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkọ ofurufu Delta Air Line DL54 to gbera lati papakọ ofurufu Hartsfield Jackson Atlanta wa si ipinlẹ Eko ni ko ri bi de ipinlẹ Eko to pada si ibi to ti gbera.

Igbesẹ yii mu ki awọn ero inu ọkọ ofurufu naa lo wakati mẹjọ loju ofurufu to si ni lati pada si Atlanta to ti gbera.

Awọn oṣiṣẹ inu ọkọ ofurufu naa sọ fun awọn ero pe awọn maa ni lati pada si ibi ti awon ti n bọ nitori ipenija imọ ẹrọ ti awon ni.

Iroyin ni awọn ero inu ọkọ ofurufu naa lo ọpọ wakati loju ofurufu ni ọjọ Abamẹta naa to si jẹ pe wọn ni lati pada si ibi ti wọn ti n bọ bii ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa ṣe ṣadede wọgile irinajo ọhun lai sọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.

"A da ọkọ ofurufu naa pada tori ipenija imọ ẹrọ kan to waye"

Airlive.com ninu iroyin ti wọn gbe jade sọ pe bi ọkọ ofurufu naa ṣe gbera ni irọlẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹsan-an, oṣu Karun-un, to si wọ ti inu ofurufu ni iwọn ẹsẹ bata 33,000 nigba to maa fi to wakati mẹta.

Amọ bi ọkọ ofurufu naa ṣe n de bii idaji ọna lati kọja si odi keji ni awọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu naa kede pe awọn ko ni le tẹsiwaju pẹlu irinajo naa nitori ipenija kan to waye pẹlu ọkọ naa.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ Delta Air Lines fi lede sọ pe awon da ọkọ ofurufu naa pada tori ipenija imọ ẹrọ kan to waye amọ wọn o sọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ ni pato.

Lẹyin ti wọn pada si Atlanta ni owurọ ọjọ Aiku ni ileeṣẹ naa wọgile irinajo naa patapata, ti wọn si fi ọkọ ofurufu naa kalẹ si papakọ ofurufu fun ayẹwo ati atunṣe ohun to ba ṣẹlẹ sii.

Bakan naa ni wọn tun wọgile irinajo lati Eko si Atlanta to yẹ ko waye lojọ Aiku.

Awọn ero to fẹ wọkọ naa lọ si orilẹ ede Amẹrika ni wọn nilo lati ṣẹṣẹ maa wa ọkọ ofurufu mii ti wọn maa ba rinrinajo tabi ki wọn duro de ọkọ ofurufu mii ti Delta Air Line maa pese fun wọn amọ ti wọn sọ pe wọn ko mọ igba ti iyẹn maa waye.