Ọmọ Nàìjíríà míràn tún kú sọ́wọ́ ọlọ́pàá ní South Africa; Ìjọba Nàìjíríà fárígá, pè fún ìwádìí kíkún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olu ileeṣẹ orilẹede Naijiria to n ri si irinajo ni South Africa ti bu ẹnu atẹ lu bi ọmọ Naijiria kan, Ibeh Chika Simon, ṣe padanu ẹmi rẹ sinu ikọlu awọn ọlọpaa lorilẹede naa, lojuna ati le awọn ajeji kuro ni South Africa ti wọn gbe dani.
Bakan naa ni Naijiria n pe fun iwadii iku to pa Ibeh Chika Simon lọsẹ to kọja yii, to si tun gbe ọmọ Naijiria mi-in ti wọn pe orukọ tiẹ ni Egwabor Patrick Chuks, de ile iwosan.
Egwabor farapa gidi bi iroyin ṣe wi, latari ibọn to ba a nibi iṣẹ lile ajeji jade tawọn ọlọpaa South Africa n ṣe.
Tẹ o ba gbagbe, South Africa ti n le awọn ajeji rẹpẹtẹ kuro nilẹ naa o ti pẹ, paapaa awọn alawọ dudu ti wọn jẹ ọmọ Africa bii tiwọn, lori ẹsun pe wọn ko je kawọn riṣẹ ṣe niluu abinibi awọn.
Ọgbọnjọ oṣu Kẹfa to kọja yii ni wọn fi gbedeke si fawọn ajeji lati filuu awọn silẹ, ọpọ orilẹede lo si ti ko awọn eeyan rẹ wale lati ibẹ.
Ṣaaju igba naa ni South Africa ti n fun ogun mọ wọn lati le wọn jade, tawọn ọmọ Naijiria kan si ti padanu ẹmi wọn ninu igbesẹ naa.
Bawo ni ikọlu to pa Simon, sọ Egwabor di ero ileewosan ṣe waye?
Lile awọn ajeji kuro ni South Africa naa lo n tẹsiwaju lọjọ kẹtalogun oṣu Keje ọdun 2026 yii, eyi ti i ṣe ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.
Atẹjade ti ileeṣẹ Naijiria to n ri si irinajo ni South Africa fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe Ibeh Chika Simon ku ninu ikọlu naa lọna to ruju, iku rẹ si nilo ẹkunrẹrẹ alaye.
O ni lasiko ti awọn ọlọpaa South Africa, "South African Police Service" (SAPS) n dọdẹ awọn ajeji kiri niluu Bellville, Cape Town, lọjọ naa ni Simon ko agbako iku.
Bakan naa ni atẹjade naa sọ pe ninu iṣẹ awọn ọlọpaa ọhun ni wọn ti yinbọn fun Egwabor Patrick Chuks, ọmọ Naijiria miran to di ero ileewosan.
Ẹhonu ijọba Naijiria
Lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keje yii, Agbẹnusọ Naijiria nilẹ okeere, Kimiebi Imomotimi Ebienfa, ba BBC sọrọ lori iha ti ijọba Naijiria kọ si iṣẹlẹ yii.
Kimiebi ṣapejuwe iku Simon ati ifarapa Egwabor bii ohun to bani lọkanjẹ pupọ.
"Ibanujẹ ọkan gbaa ni iku Simon. Iroyin iwa ika to wa latọdọ awọn ọlọpaa to fa iku rẹ ba wa lọkan jẹ."
O ṣapejuwe iṣelẹ yii bii ọkan lara awọn ipaniyan to ti waye ni South Africa sawọn ọmọ ilẹ okeere, eyi to wa bẹẹ lai ni ojutuu.
Bakan naa ni ajọ yii loun ka iwa naa si ikorira awọn ajeji, eyi to n peleke si i.
O ni iwan aa ko bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lati gbele aye, ati pe South Africa ko tẹle ofin rẹ to ṣeleri lati ṣe daadaa si gbogbo eeyan.
O wa pe fun iwadii to ko akoyawọ, ti yoo waye lẹsẹkẹsẹ, ti ko si ni I fi sibi kan lati tete waye lori iku Ibeh ati ibọn to ba Egwabor to fi dero ileewosan.
Alaye South Africa
Ṣaaju ni igbimọ to n ri si iwọle jade ni South Africa ti sọrọ lọjọ Aiku lori iṣẹlẹ yii, pe iwadii ti n lọ lọwọ lori rẹ.
Minisita eto idajọ wọn, Mmamoloko Kubayi, to jẹ alaga igbimọ naa, ṣalaye pe awọn ẹgbẹ kan di awọn agbofinro lọwọ lasiko ti wọn n ṣiṣẹ wọn ni Bellville, bẹẹ ni awọn ajeji kan ko gba ki wọn ṣiṣe wọn.
"A fẹ kilọ gidi fawọn to n di iṣẹ awọn agbofinro wa lọwọ, bi bẹẹ kọ, wọn yoo foju wina ofin."
Nigba to n dahun si bawọn eeyan ṣe ti padanu ẹmi sinu iṣẹ awọn agbofinro naa, Kubayi sọ pe:
"Nipa awọn to ku lasiko ti iṣẹ naa n lọ lọwọ, yoo wu wa lati fidi ẹ mulẹ pe ohun to nilo iwadii ni.
"A maa fi abọ iwadii naa lede bo ṣe yẹ."
Bakan naa lo ni awọn alaṣẹ South Africa ti gbọ nipa awọn ikọ fijilante kan ti ijọba ko fọwọ si, eyi to da oju sọ awọn ajeji.
Kubayi rọ awọn to n ṣe iru ẹ lati dẹkun ẹ.
O ni eeyan meje ni ọwọ ofin ti ba ninu awọn to n ṣiṣẹ to lodi sofin yii.





























