Lẹ́yìn iná tó ṣẹ́yọ ni pápákọ òfurufú Murtala Muhammed l'Eko, iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ padà

Papakọ ofurufu Murtala Muhammed niluu Eko

Oríṣun àwòrán, FAAN

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn alakooso papakọ ofurufu ni Naijiria, Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), ti kede pe iṣẹ ti bẹrẹ pada ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa nipinlẹ Eko, lẹyin ina to ṣẹyọ ni apa kan ibẹ lọjọ Aiku.

Ṣaaju ni FAAN ti fi atẹjade to kede iṣẹlẹ ina naa lede laaarọ ọjọ Aiku naa ti I ṣe ọjọ keji oṣu Kẹjọ ọdun 2026.

Ninu atẹjade keji ti wọn fi sita ni FAAN ti ṣalaye pe ohun gbogbo ti pada sipo ni papakọ naa.

"Iṣẹ ti bẹrẹ pada ni abala Terminal 2, ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport, l'Eko. A ti n da awọn ero lohun, bẹẹ ni awọn irinajo ti a la kalẹ n lọ bi a ṣe to wọn."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, FAAN ko ti i sọ ohun to fa ina to ṣẹyọ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ni awọn yoo maa fi ikede sita bo ba ṣe n lọ.

Papakọ ofurufu Murtala Muhammed ilu Eko yii jẹ eyi ti ero ti maa n pọju ninu awọn ibudo itẹkọleti ni Naijiria.

Bi wọn ṣe n mojuto irinajo laaarin orilẹede yii ni wọn ri si ti oke okun.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ina kan ṣẹyọ ni apa ibi ti a mọ si Terminal 2, ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, nipinlẹ Eko.

Ajọ Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN) lo kede iṣẹlẹ naa loju opo X rẹ.

FAAN ṣalaye ninu atẹjade akọkọ pe oun ti dari ẹka to n ri si iṣẹlẹ ina sibẹ lati pa ina ọhun.

Ninu atẹjade FAAN naa ni wọn ti sọ pe ẹnikẹni ko ṣofo ẹmi ninu ijamba ina naa, bẹẹ ni ko sẹni to farapa.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti ina yoo ṣẹyọ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed ilu Eko yii.

Ina ṣẹyọ loṣu Keji ọdun 2026 yii ni papakọ ofurufu naa, ni abala ti a mọ si Terminal 1.