Àwọn ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa St.Janet, akọrin Jùjú tó jáde láyé

Oloogbe Iyun Janet Oluwatoyosi Ajilore (St. Janet)

Oríṣun àwòrán, St. Janet/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Iyun Janet Oluwatoyosi Ajilore (St. Janet)
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Agbọsọgbanu ni iroyin iku gbajumọ olorin Juju to tun maa n kọrin aṣa nni, St. Janet, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ, lati wakati ti iroyin iku naa ti bọ sori ayelujara.

St. Janet ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Iyun Janet Oluwatoyosi Ajilore ni awọn eeyan tun mọ si Mama Yabis lode ariya, amọ eeyan pupọ ni ko mọ pe akọrin tun ni Oloogbe Iyun ni ṣọọṣi Kerubu ati Serafu nigba kan.

Wọnyi lawọn nnkan ti ọpọ eeyan ko mọ nipa olorin to maa n fi ibalopọ kọrin, ṣẹfẹ, St. Janet

Ọmọ ilu Ile Ife, nipinlẹ Osun ni Oloogbe Iyun Omotoyosi Ajilore tawọn eeyan mọ si St. Janet.

Ile ẹkọ girama Ooni Girl's High School, niluu Ile-Ife ni Oloogbe St.Janet lọ, o si tun kawe ni Yunifasiti ilu Eko ti a mọ si Lagos State University (LASU).

Ko too di olorin aye to n kọ Juju ati orin aṣa papọ, akọrin ni Oloogbe Iyun ninu ijọ Kerubu ati Serafu.

Bawọn kan ṣe waa mọ ọn si olorin Juju ni awọn kan gbadun orin ibalopọ to maa n kọ lai da ọrọ kankan pe, eyi to mu okiki rẹ kan.

Nibi orin aṣa naa ni wọn ti fun St .Janet ni inagijẹ Mama Yabis.

St Janet funra rẹ a maa pe ara rẹ ni General Overseer, iyẹn adari ijọ Saint Bottles Cathedral.

Awọn mi-in a si maa pe ijọ naa ni ijọ awọn ẹlẹṣẹ (Sinners' Chapel).

St. Janet koju iṣoro pẹlu orin aṣa to n kọ, wọn figba kan yọ ọ lẹgbẹ

Nitori iru orin ti Oloogbe St.Janet maa n kọ, eyi ti awujọ ka si ohun ti ọmọde ko gbọdọ tẹti si, awọn asiko kan wa ti ẹgbẹ olorin PMAN fofin de orin rẹ.

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko koro oju si awọn orin rẹ.

Amọ pẹlu awọn ipenija yii, awọn aye ṣi n tẹti si orin obinrin naa bo ṣe jẹ orin ibalopọ ati aṣa to.

Bi a ba wa yọwọ orin kikọ to n gbe Oloogbe Iyun de ita gbangba, to si n jẹ kawọn eeyan maa fi oju onikọkukọ wo o, eeyan jẹjẹ ti ki i sọrọ ni awọn to sunmọ St.Janet pe e nigba aye rẹ.

Bẹẹ lo si ṣe n ṣe aye rẹ lọ, to n kọrin lawọn ile ijo, ode ariya ati ile ijọsin ti wọn ba pe e si.

Asiko ti ẹnikẹni ko si ronu iku kan an ni akọrin naa jade laye wẹrẹ lọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.

Ikú dóró! Gbajúmọ̀ olórin Juju St. Janet jáde láyé

Akọrin Juju St. Janet wọ aṣọ funfun pẹlu awo loju

Oríṣun àwòrán, St Janet/Instagram

Iroyin ibanujẹ lo tun suyọ lagboole olorin nilẹ Naijiria, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ọkan lara awọn gbajugbaja olorin nni, Iyun Janet Ajilore tọpọ awọn eeyan mọ si St Janet ti jade laye.

Saint Janet, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n pe e, lo ki aye pe o digboṣe lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo da a dubulẹ lati bi oṣu diẹ sẹyin.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ilu-mọ-ọn-ka olorin naa fi aye silẹ, gẹgẹ bi awọn to sunmọ ọn ṣe gbe e sita.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ awọn akẹgbẹ olorin naa lo ti gbe iroyin iku rẹ sori ikanni ayelujara wọn, nibi ti ọpọ ti n barajẹ pupọ lori ipapoda rẹ lai ro tẹlẹ.

"Pẹlu ibanujẹ, a n kede ipapoda St. Janet (Iyun Janet Ajilore), ẹni to fi aye yii silẹ lẹyin aisan rampẹ," ọkan lara awọn atẹjade ori ayelujara sọ bẹẹ.

Atẹjade ọhun fi kun un pe, "Orin rẹ, ẹbun rẹ, ohun ara ọtọ rẹ fọwọ kan aye ọpọ eeyan, to si fi ipa manigbagbe silẹ lagboole amuludun. Ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rẹrẹ. Titi ayeraye la o maa ranti rẹ."

Lara awọn to fi iroyin iku St Janet sita, pẹlu ọrọ ibanikẹdun ni Ayoola Akinola Michael tọpọ mọ si Alayo Melody Singer.

"A n gbe ile aye lonii, a maa ku to ba di ọla! St Janet, ki Ọlọrun tẹ ẹmi rẹ si afẹfẹ rere," Alayọ Singer banujẹ.

Bakan naa ni gbajugbaja oniroyin nni, Otunba Femi Davies naa fidi iroyin ọhun mulẹ loju opo ayelujara rẹ laarọ ọjọ Aiku, to si lo dun oun d'ọkan.

Davies lo jẹ ko di mimọ pe olorin naa ku lẹyin aisan rampẹ to ti n ba a finra.

"St Janet (Iyun Janet Ajilore), gbajugbaja olorin Juju ilẹ Naijiria, ẹni ti awọn eeyan mọ gẹgẹ bii pe o fi ara jin, to si tẹpa mọ iṣẹ rẹ, pẹlu ọkan akikanju ati itara, to fi mọ awọn orin amaraya ti ku.

"Ọjọ Abamẹta to kọja yii lo dakẹ lẹyin aisan rampẹ," Femi Davies ṣalaye.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn mọlẹbi oloogbe naa ko tii sọ ohunkohun lori iku rẹ.

Ki lo ṣokunfa iku Saint Janet?

Bo tilẹ jẹ pe BBC News Yoruba ko tii le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn lara ohun ti a gbọ ni pe aisan to nii ṣe pẹlu itọ ṣuga lo ṣokunfa iku rẹ.

Taani Saint Janet

Odu ni Janeth Omotoyosi Janet Ajilore Iyun, ẹni ti wọn tun n pe ni Mama Yabis, kii ṣaimọ foloko lagboole olorin Juju nilẹ Naijiria, ti ọpọ awọn to gbafẹ si gbadun ori rẹ nigba to wa laye.

Ko fẹẹ si agbo ariya tabi ibi ti awọn eeyan ti ma lọ n jaye, ti wọn kii tii gbọ orin rẹ lagbaye. Bo ṣe n ṣere orin nilẹ Naijiria, lo tun ti lọ soke okun lati lọ kọrin fawọn ololufẹ rẹ.

Inu ẹgbẹ akọrin ti ijọ Kerubu ati Serafu ni St Janat, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun naa ti bẹrẹ iṣẹ orin rẹ, nibẹ lo si ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ orin kikọ.

Nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun, St Janet bẹrẹ sii tẹle gbajumọ olorin nni, Segun Lawaye jade orin kikọ, to si n ṣe elegbe lẹyin rẹ.

Igba to ya loun naa pinnu lati ṣe awo orin tiẹ sita, bo tilẹ jẹ pe ko tii gbajumọ nigba naa.

Diẹdiẹ ni Mama Yabis tun bẹrẹ sii mu idagbasoke ba orin rẹ, leyi to jẹ ko bẹrẹ sii di gbajugbaja laarin awọn olorin.

Ohun pataki tubọ jẹ ki Mama Yabis di ilu mọ-ọn-ka ni ti bo ṣe bẹrẹ sii yi awọn orin ti wọn n kọ lawọn ile ijọsin si ikọkukọ, eyi gan-an lo jẹ ki awọn to gbafẹ fẹran orin ọhun.

Nigba naa lo bẹrẹ sii pe ara rẹ ni oludasilẹ ile ijọsin Saint Bottles, eyi ti oloyinbo n pe ni "General Overseer of Saint Bottles Cathedral (Sinners' Chapel),".

Apejẹ yii lo ṣafihan iru awọn orin to n kọ fun awọn olulufẹ rẹ kaakiri agbaye

Pẹlu bo ṣe n kọ irufẹ orin yii to, awọn eeyan tun ṣi n gba tiẹ siwaju si i, to jẹ ki wọn maa pe e si oniruuru ode ariya nilẹ Naijiria ati loke okun.

Awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus' gan-an lo tubọ gbe e ja sita gbangba, to di pe ko si ibi naa ti wọn kii tii kọ ọ.

Ọpọ igba ni ẹgbẹ olorin bii PMAN ti fi ofin de Saint Janet nitori irufẹ orin to n kọ, leyi ti wọn sọ pe ko ṣagbelarugẹ fun iwa ọmọluabi.

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekoo tun gbe igbesẹ lori awo orin rẹ to pe ni 'Faaji Plus', ti wọn si fagile e lawọn ode to ba nii ṣe pẹlu ijọba ipinlẹ naa.