Olórí àwọn tó ń pèsè owó fún ẹgbẹ agbésùnmọ̀mí ISWAP ní Naijiria jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ọmọ ogun

Asiko ti agbesunmọni naa ati awọn ọmọ rẹ jọwọ ara wọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti ṣe aseyọri mii ninu igbiyanju rẹ lati koju igbesunmọmi ni Naijiria.

Eyii ko ṣẹyin bi ọkan gboogi lara awọn to n ṣeranwọ owo fun ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP ṣe jọwọ ara rẹ fun awọn ọmọ ogun Operation Hadin Kai.

Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe igbesẹ afurasi naa lo n waye lasiko ti pupọ awọn agbesunmọmi bi tirẹ bẹrẹ si n jọwọ ara wọn fun ileeṣẹ ọmọ ogun.

Agbẹnusọ fun ẹka Theatre Command, ọgagun Mohammed Goni sọ pe lẹnu lọlọ yii, nnkan bii agbesunmọmi mẹridinlaadọta ati mọlẹbi wọn ni wọn ti jọwọ ara wọn fun awọn ologun.

O ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Abamẹta, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni ọkunrin naa jọwọ ara rẹ loju ọna Ladari–Jegarawa–Tunokalia.

Goni tẹsiwaju pe "Igbesẹ rẹ lati jọwọ ara rẹ ko ṣẹyin bi awọn oṣiṣẹ Operation HADIN KAI ṣe n kọlu ibuba agbesunmọmi ti wọn si n ju ado oloro si ọdọ wọn loorekoore."

Ọgagun naa fi kun pe iwadii awọn fi han pe ọkunrin ọhun ni olori awọn to n pese owo fun ikọ agbesunmọmi ISWAP lagbegbe Jubillaram.

Afurasi naa pẹlu awọn ọmọ rẹ ọkunri meji ni wọn jọwọ ara wọn fun awọn ologun.

Lara awọn ohun ija ti ologun gba lọwọ wọn ni ibọn AK-47 kan, ile ọta ibọn mẹrin, ọta ibọn ọgọrun ati ẹyọkan, ati alupupu kan.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ni awọn ti n fi ọrọ wa afurasi naa lẹnuwo ko le ran awọn lọwọ lori igbogun ti igbesunmi ni Naijiria ati ki ọwọ tun le tẹ awọn agbesunmọmi akẹgbẹ rẹ ninu igbo.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori igbesẹ ọkunrin naa lati jọwọ ara rẹ fun awọn ologun.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ni oun ko ni sinmi ninu afojusun oun lai rẹyin igbesunmọmi ni Naijiiria.