Abula: Eré ìdárayá tiwantiwa tí wọ́n fi orúkọ àmàlà, gbẹ̀gìrì àti ewédú sọ tó ti wá ń di gbajúmọ̀ káàkiri

Àkọlé fídíò, Abula: Wọ́n fi orúkọ àmàlà, gbẹ̀gìrì àti ewédú sọ. Tó ń di gbajúmọ̀ káàkiri
Abula: Eré ìdárayá tiwantiwa tí wọ́n fi orúkọ àmàlà, gbẹ̀gìrì àti ewédú sọ tó ti wá ń di gbajúmọ̀ káàkiri
Published

Ni ọdun 1984 ni arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Elias Yusuf da ere idaraya kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Abula silẹ.

Ounjẹ ilẹ Yoruba kan ti wọn n pe ni 'Abula'ni wọn fi sọ̀ ọ lorukọ. Abula jẹ abupọ ọbẹ Gbẹgiri, ewedu ati ata.

Abula gẹgẹbi ere idaraya jẹ adapọ ere idara bii Volleyball ati Tennis nibi ti awọn olukopa ti n lo patako onigun mẹrin lati maa gba bọọlu gba ori awọn to wa ni iduro.

Ni ọdun 1998 ni wọn kọkọ lo ere idaraya naa nibi idije apapọ ere idaraya lorilẹede Naijiria.