Ìdí tí a kò fi sin Olóye Lekan Alabi, Abese Olubadan sílùú Ibadan-Tunji Alabi, ọmọ Olóògbé

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/ Facebook/ BBC
Nigba ti ikede iku Oloye Oloogbe Lekan Alabi, Abese Olubadan jade lọjọ Abamẹta, ti wọn si kede pe wọn yoo sinku lọjọ Aiku, ko sẹni to ro o pe ilẹ Ibadan kọ ni Baba naa yoo sun.
Ṣaaju lọjọ Aiku naa ni wọn ti kirun si oku lara nile rẹ to wa ni Akobo, niluu Ibadan.
Imam agba ilu Ibadan, Alhaji Agbọtọmọkekere lo ṣe waasi to si sọrọ lori bi Oloye Lekan Alabi ṣe lo igbe-aye rẹ.
Amọ nigba ti akoko to lati sinku, itẹ oku aladani kan niluu Fiditi, nipinlẹ Oyo ni awọn ẹbi Oloogbe gbe baba naa lọ ti wọn si sinku naa sibẹ.
Eyi mu ọpọ eeyan maa beere pe ki lo le ṣẹlẹ ti agba oye ilẹ Ibadan yoo lọ sun oorun ayeraye rẹ niluu Fiditi, dipo ilẹ Ibadan ti wọn ti bi i.
BBC News Yoruba wa nibi isinku naa, ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe to ba wa sọrọ lori eyi, Tunji Alabi si ṣalaye pe:
"A fẹ ibi ti abojuto yoo ti wa fun wọn, a fẹ aabo,ati pe baba funra rẹ ko fẹran ibi idọti lati sun"
Ninu alaye Tunji Alabi to jẹ abigbẹyin Oloogbe Lekan Alabi lo ti sọ pe awọn fẹ ibi ti abojuto to peye yoo ti wa fun baba.
O fi kun un pe Oloye Lekan Alabi ko fẹran idọti rara nigba aye rẹ, eyi si tun jẹ idi kan tawọn fi gbe e wa si aaye naa ni Fiditi.
Bakan naa lo ni awọn fẹ ki aabo to peye wa fun oku baba.
Tunji tun sọ pe awọn itẹkuu ilu Ibadan ti kun, bẹẹ ni igbo ti pọju nibẹ.
O ṣalaye pe ẹnikan to fẹran aṣa ni Oloogbe Lekan Alabi, ko si fẹ irẹjẹ.
Iyawo oloogbe naa sọrọ pẹlu, o ni alabaaro toun maa n fi ọrọ lọ lo ti jade laye yẹn.
Lara awọn eeyan to wa nibi eto isinku naa ni:
Sẹnetọ Sarafadeen Ali, Kọmisanna fun iroyin nipinlẹ Ọyọ; Ọmọọba Dọtun Oyelade, Kọmiṣanna to n ri ṣi eto Aṣa ati Igbafẹ nipinlẹ Ọyọ; Ọmọwe Wasiu Olatunbosun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Olóyè Lekan Alabi, Abese Olubadan ilẹ̀ Ibadan tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/ Facebook.
Agba oye ilẹ Ibadan to tun jẹ agba ninu iṣẹ iroyin, Oloye Lekan Alabi, ti jade laye.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Akọwe iroyin fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, iyẹn Adeola Oloko fi sita, owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni Oloye Alabi papoda.
Oloogbe Alabi ni Abese Olubadan nigba aye rẹ.
Ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ni nigba to jade laye.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ọla ọjọ Aiku ni wọn yoo sinku Oloogbe Lekan Alabi nilana ẹsin Islam.
Ta a ni Oloogbe Oloye Lekan Alabi?

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/Facebook
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 1950 ni wọn bi Oloogbe Oloye Lekan Alabi, ọmọ ilu Ibadan nipinlẹ Oyo ni.
O lọ sile ẹkọ 7th-Day Adventist Primary School, Oke-Foko, Ibadan ati African Church Grammar School, Apata Ganga, Ibadan.
Oloogbe ṣiṣẹ tiṣa nile ẹkọ alakọọbẹrẹ St John's Anglican Primary School, Ibadan.
Ni 1973, wọn gba a sileeṣe iwe iroyin Sketch gẹgẹ bii akọroyin.
O lọ sile ẹkọ College of Journalism, 'Fleet Street', London to gbajumọ pupọ ni 1976, o si yege nibẹ ni 1978.
Lekan Alabi fiṣẹ silẹ ni Sketch, o dara pọ mọ ileeṣẹ tẹlifiṣan apapọ NTA, Ibadan.
Ọdun1983 lo ṣiṣẹ bii Akọwe iroyin fun Oloogbe Bola Ige to jẹ gomina Oyo nigba naa.
O di ipo naa mu lati 1983 de 1989.
Bakan naa lo ṣe fun Major-General Oladayo Popoola, Ọgagun Adetunji Olurin ati Ọgagun Sasaenia Oresanya.
Oloye Alabi ni Alaga ẹgbẹ Adegoke Adelabu (Penkelemesi) ati the Yusufu Olatunji (Baba l'Egba).
Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ Olufọkantan ẹgbẹ Adekunle Fajuyi Foundation, D.O.Fagunwa Foundation, Duro Ladipo Foundation ati bẹẹ bẹẹ lọ ni.
Oloye Ibadan to n reti ati depo Olubadan lọjọ kan ni Oloogbe Lekan Alabi, ki ọlọjọ too de sipo Abese Olubadan to wa.




























