Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí jàndúkú olóṣèlú tó yìnbọn pa Ezekiel, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá l'Osun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

‎Ọjọ gbogbo ni tole ọjọ kan ni toloun, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu Saheed Kareem, afurasi to yinbọn pa ọmọ ọdun mẹrinla ni Ilu Ilobu nipinlẹ Osun, ẹni to ti bọ sọwọ ọlọpaa bayii.

Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ọsun, Ibrahim Gotan, ti fi oju Kareem ẹni tí gbogbo eeyan mọ si Tanfẹani han fun gbogbo eeyan lati ri i

Ni ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa ọdun yii ni a gbọ pe afurasi naa ṣe iku pa oloogbe Ezekiel Ọlapade ọmọ ọdun mẹrinla.

‎Ninu ọrọ rẹ, Kareem to jẹ afurasi naa sọ pe oun kọ loun pa Ezekiel ati pe, oun ko si nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa to kọja.

Fidio to ṣafihan pe Kareem lọwọ ninu iku ọmọ ọdun mẹrinla naa ni awọn ọlọpaa lawọn fi ṣe awari afurasi naa.

Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Ọsun wa rọ gbogbo awọn oloselu to n n lo awọn janduku ti ko jẹ ki alaafia jọba ni ipinlẹ Ọsun pe ki wọn jáwọ, bi bẹẹ kọọ wọn o foju wina ofin.

‎Kọmisọna tun fi da gbogbo olugbe Ipinlẹ Ọsun loju pe ki wọn lo fi ọkan balẹ, o ni gbogbo awọn janduku naa ni ọwọ ṣinkun ọlọpaa yoo tẹ patapata.

‎Apapọ gbogbo awọn janduku ti Kọmisọna Ọlọpaa Ibrahim Gotan fi lede ni wọn jẹ mẹrinlelogun.