Aráàlú dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá n'Ibadan bí ọlọ́kadà kan ṣe kú lójú pópó lásìkò táwọn ọlọ́pàá dá a dúró

Agọ ọlọpaa na lẹyin iṣẹlẹ ọhun

Oríṣun àwòrán, Oyo state Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn araalu kan ti fi ibinu sọ ina si agọ ọlọpaa Kara, to wa lagbagbe Moniya, niluu Ibadan lẹyin iku ọkunrin ọlọkada kan nibẹ.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn ọlọpaa meji kan n yẹ awọn eeyan wo nibẹ, eyii ti ofin ko gba wọn laaye lati ṣe lagbegbe ọhun.

Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, DSP Olayinka Ayanlade fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọlọpaa da ọlọkada ọhun, Sanni Salisu, to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn duro loju popo.

Ayanlade sọ pe ọlọpaa meji to n ṣiṣẹ ni Kara n yẹ ara awọn eeyan to n kọja nibẹ wo lai kọkọ gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ.

Agọ ọlọpaa ti ọpọ ọkada wa niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Oyo state Police

"Aisan to fara jọ warapa lo sadede kọlu Ọlọkada niwaju awọn ọlọpaa to da duro, lo ba ku"

O ni "Lasiko itakurọsọ wọn ni nnkan to farajọ warapa ṣadede kọlu u, to si ṣubu lulẹ lati ori alupupu rẹ.

"Ninu igbiyanju lati doola ẹmi rẹ, awọn ọlọpaa ọhun gbe digba-digba lọ sile iwosan Modupe to wa ni Akinyele, ibẹ ni awọn oṣiṣẹ eto ilera ti kede pe o ti jade laye.

"Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣadede waye mu ki inu bi awọn eeyan to wa lagbegbe naa."

A gbọ pe awọn eeyan kan lagbegbe ọhun ti inu bi latari iku ojiji ọkunrin naa lai ya bo agọ ọlọpaa ọhun ti wọn si sọ ina si apakan rẹ.

Iroyin ni lara awọn dukia to jona nibẹ ni ọkọ akero Mazda kan ti awọn ọlọpaa n lo ati alupupu mẹta, nigba ti ina jo ọlọpaa kan pẹlu.

Ayanlade ṣalaye pe lẹyin ikọlu naa ni wọn fi awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa ṣọwọ sibẹ lati da alaafia pada sagbegbe ọhun.

O fi kun pe awọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ sile igbokupamọsi to wa nile iwosan Adeoye to wa lagbegbe Ring Road fun iwadii ohun pato to ṣokunfa iku rẹ.

Ọkada ti wọn sun nina

Oríṣun àwòrán, Oyo state Police

"Ẹ dẹkun sisọ iroyin ẹlẹjẹ pe awọn ọlọpaa lo pa ọlọkada naa"

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Abimbola Ayodeji Olugbenga ti paṣẹ ki wọn ti awọn ọlọpaa mejeji ti ọrọ naa kan mọle fun iwadii.

Olugbenga tun paṣẹ fun ẹka CID ileeṣẹ ọhun ko ma fi iwadii naa falẹ ki gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ le foju wina ofin.

Amọ ṣa, ọlọpaa ni iroyin to n lọ ni igboro ori ayelujara nipa ohun to ṣẹlẹ nibẹ yatọ si ohun pato to waye.

Wọn ni ki araalu masẹ naani iroyin ẹlẹjẹ to n lọ ni igboro pe ọlọpaa lo gbẹmi ọkuunrin naa.

Lẹyin naa lo ni ileeṣẹ ọhun ko ni faye gba iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ.

O tun rọ awọn araalu ki wọn dẹkun ati maa ṣe idajọ lọwọ ara wọn lai kọkọ ṣe iwadii lati kọkọ mọ kulẹkulẹ ohun to ba ṣẹlẹ.