Ọlọ́pàá "yìnbọn pa" ọkùnrin kan níta gbangba lórí fídíò tó gba orí ayélujára, aráàlú fọnmú

Oloogbe Mene Ogidi wọ aṣọ dudu, ọlọpaa to yinbọn pa Ogidi wa ninu aṣọ ọlọpaa pẹlu ankọọbu lọwọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Delta State Police Command/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti fọwọ ofin mu agbofinro to yinbọn pa afurasi kan niluu Effurun nipinlẹ Delta.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, SP Bright Edafe, fi sita wi pe bi agbofinro Nuhu Usman ṣe yinbọn fun afurasi naa tako ofin ileeṣẹ ọlọpaa.

Fidio kan to wa lori ayelujara eyi ti BBC Yoruba ri to ṣafihan bi afurasi naa, Mene Ogidi, ṣe jokoo niwaju agọ ọlọpaa, ti wọn si de e ọwọ ati ẹsẹ.

Afurasi ọlọpaa to pa eeyan wa ninu asọ ọlọpaa, ẹni ti wọn pa joko silẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

"Oloogbe naa lọ gba ẹru kan ti wọn fi ranṣẹ si i ni ibudokọ, amọ, ti nnkan to wa ninu ẹru naa jẹ ibọn"

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Aiku to kọja tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin yii ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Ohun ti a gbọ ni pe, oloogbe naa lọ gba ẹru kan ti wọn fi ranṣẹ si i ni ibudokọ, amọ, ti nnkan to wa ninu ẹru naa jẹ ibọn.

Awọn eeyan to wa lagbegbe naa sọ pe awọn awakọ lo rii wi pe, ibọn lo wa ninu ẹru ti wọn fi ranṣẹ si ọdọkunrin naa.

Fidio to wa lori ayelujara ṣafihan pe awọn ọlọpaa ko fun Ogidi lanfaani lati sọ tẹnu rẹ.

Fidio naa tun ṣafihan bi ọlọpaa meji ṣe n fi ọta sinu ibọn wọn.

Nibi ti wọn ti n ki ibọn wọn ni ọkan lara awọn ọlọpaa naa ti yinbọn fun afurasi ọhun, ti o si ṣubu lẹsẹ kẹsẹ.

Nigba ti ọdọkunrin naa ti wa gba ẹru rẹ lawọn eeyan mu un ti wọn si fọrọ naa to ọlọpaa leti.

Amọ, kete tawọn ọlọpaa de ni ọkan lara wọn yinbọn fun ọkunrin naa, dipo ki wọn ṣe iwadii nipa ẹni ti o fi ibọn ranṣẹ si afurasi ọhun.

Ọpọ eeyan lori itakun ayelujara lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa.

Iṣẹlẹ ipaniyan wọpọ laarin ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, eyi gan an lo ṣokunfa ifẹhonuhan awọn ọdọ tako iwa ipa ọlọpaa si araalu eyi ti wọn pe ni EndSARS lọdun 2020.

Lẹyin naa ni ijọba pada tu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa kogberegbe SARS ka lorilẹede Naijiria.

Ọkunrin ti ọlọpaa fẹsun kan joko silẹ, ki ọta ibọn to pa a

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ ọlọpaa kẹdun pẹlu ẹbi ọdọkunrin ti agbofinro pa, ṣeleri idajọ ododo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Delta, CP Yemi Oyeniyi, ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Mene Ogidi, ọdọkunrin ti ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Nuhu Usman ṣekupa niluu Effurun nipinlẹ naa lọjọ Aiku to kọja.

Iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin tawọn eeyan kan fi ọrọ Ogidi to ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Effurun leti wi pe ibọn ati ọta ibọn lo wa ninu ẹru ti ọdọkunrin naa lọ gba ni ibudokọ.

Bayii lawọn ọlọpaa lọ sibẹ lati fọwọ ofin mu ọmọkunrin naa, ki wọn si ju u satimọle.

Amọ, adari awọn ọlọpaa to lọ sibẹ, ASP Nuhu Usman, yinbọn fun afurasi naa o si gba ibẹ ku.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ohun ti ASP Usman ṣe tako ofin ileeṣẹ ọlọpaa abala 237 ati ilana bawọn ọlọpaa ṣe maa n ṣiṣẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Delta, SP Edafe, sọ pe kete ti iroyin naa tẹ komiṣọna ọlọpaa lọwọ ni o paṣẹ wi pe ki wọn mu ASP Usman lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Asaba lati le da ṣeria fun un.

Ni bayii, wọn ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ọlọpaa naa, wọn si ti gbe e lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa Naijira l'Abuja nibi ti wọn yoo ti ṣedajọ fun un.

SP Edafe ni ileeṣẹ ọlọpaa maa n bọwọ fun ofin, kii si tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Bakan naa ni o ṣalaye ninu atẹjade to fi sita naa wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni foju ire wo ẹnikẹni to ba fọwọ pa ida ofin loju.

Kọmiṣọna ọlọpaa CP Oyeniyi wa ṣeleri pe oun yoo ri pe idajọ ododo waye lori ọrọ naa.

CP Oyeniyi tun rọ araalu wi pe ki wọn ni suuru, ki wọn si ma ṣe fọwọ pa ida ofin loju.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post