Ìgbésẹ̀ wo ló kàn lẹ́yìn tílé aṣòfin àgbà buwọ́lu ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti buwọlu atunto ofin fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ni Naijiria.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ile igbimọ aṣofin naa ka abajade esi igbimọ to n ri si atunto ofin ọhun, eyii ti alaga rẹ, Barau Jibrin, gbe wa siwaju rẹ.
Abẹnugan awọn aṣofin naa, Godswill Akpabio, lo fi ikede naa sita lẹyin ti ida meji ninu mẹta awọn aṣofn ọhun buwọlu u lẹyin eto idibo ti wọn ṣe lori rẹ ninu ile naa.
Olori ile naa, Opeyemi Bamidele lo lewaju atotonu ọrọ naa ki awọn aṣofin akẹgbẹ rẹ to jiroro le lori.
Lara awọn ohun ti awọn aṣofin jiroro le lori ni bi wọn yoo ṣe ṣe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ti awọn ọlọpaa ọhun yoo si maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ọlọpaa ijọba apapọ ti wọn ti wa nilẹ tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Ile igbimọ aṣofin
Ki lo wa ninu atunto ofin ọlọpaa ipinlẹ naa?
Lara awọn nnkan to wa ninu atunto ofin naa ni pe awọn gomina ipinlẹ yoo lagbara lati maa yan kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ wọn, iyẹn lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ba ti buwọ lu u tan.
Amọ ṣa, ọga agba ọlọpaa, iyẹn IG naa ni yoo si jẹ ọga agba yanyan fun ileeṣẹ ọlọpaa.
Abala 17(6) ofin ọhun sọ pe gomina ipinlẹ le paṣẹ fun kọmiṣọna lori ohun to jẹ mọ aabo irufẹ ipinlẹ bẹẹ.
Ẹwẹ, abala 17(7) ofin ọhun ni kọmiṣọna ọlọpaa ko lagbara lati fi ṣikun ofin mu ẹnikẹni, ti ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu tabi awọn eeyan mọle latari pe wọn sọrọ kobakungbe si ijọba, ayafi ti wọn ba ṣe labẹ ofin.
Abala ofin yii n gbiyanju lati ri daju pe ijọba ipinlẹ kankan ko lo ọlọpaa ipinlẹ naa lẹyin idasilẹ rẹ lati maa gbogun ti ẹnikẹn tabi ẹgbẹ to ba tako o.
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin agba ti buwọlu atunto ofin yii fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe yii, ko tii di ofin.
Iṣẹ ṣi pọ ti wọn yoo ṣe lori rẹ, bẹẹ ni Aarẹ Bola Tinubu si gbọdọ buwọlu u ko to di ṣiṣẹ.




























